Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà

Ninu eto ẹkọ wa lori eto Akomolede ati Asa lori BBC lọsẹ yii, ohun ta a maa gbe yẹwo ni oniruuru asa igbeyawo meje to wa nilẹ Yoruba.

Gẹgẹ bi Olukọ wa lọsẹ yii, Arabinrin Adetunji lati ileẹkọ girama Isabatudeen nilu Ibadan ti salaye, lara awọn igbeyawo ilẹ Yoruba la ti ri iyawo Ọsingin, nibi ti wọn yoo ti fẹ iyawo nisu lọka.

Awọn yoku ni igbeyawo Asante, nibi ti wọn yoo ti ji iyawo gbe lọ sile ọkọ rẹ, igbeyawo ọkọ kaalẹ ninu eyi ti obinrin yoo ti salọ sile ọkọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ẹ fara balẹ gbọ eto yii lẹkunrẹrẹ lati mọ nipa awọn igbeyawo to ku ati ojuse awọn alarina ninu igbeyawo.