Benue Penis Disapearance: Àwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de torí nǹkan ọkùnrin tó ń pòórá

Alaga ijọba ibilẹ Guma, nipinlẹ Benue, Caleb Aba, ti kede isede oni wakati mejila nilu Dauda, nitori awuyewuye to n waye pe nkan ọmọkunrin n poora nibẹ.
Laipẹ yii ni rogbodiyan waye nilu naa, nitori iwọde awọn ọdọ to n fi ẹsun kan pe nkan ọmọkunrin awọn n poora.
Koda, iroyin sọ pe awọn ọdọ naa pa pasitọ kan ti wọn fi ẹsun kan pe oun lo n mu awọn nkan ọmọkunrin naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Òkò gbọnin lórí ìjọba àpápọ̀ tórí pé ó pe àwọn olùwọ́de EndSARS ní agbésùnmọ̀mí
- Ẹ gbà mí o! Ìjọba Buhari ní kí Ológun pa mí láàrin ọjọ́ kan péré - Omoyele Sowore
- Bí nǹkan bá ṣe mí àtàwọn ọmọ mi, Aláàfin ni kẹ mú o - Olorì Anu figbe ta
- Ọ̀pọ̀ òkú fọ́nkálẹ̀ nílé ìwòsàn ìjọba ní Ore, ìpayà àjàkálẹ̀ àrùn gbàlú kan
- Ìpinu Gómínà láti dẹ́kun owó ìfẹ̀yìntì fáwọ̀n Gọ́mìnà àná dùn mọ́mi- Bola Ahmed Tinubu
- Ọkùnrin tó ṣe òfegè fọ́nran àwòrán ìgbéyàwó Buhari pẹ̀lú Mínísítà d'èrò ilé ẹjọ́
- Ṣé lóòtọ́ ni olorì méjì míì tún ti kúrò láàfin Oyo?
- Sọ́jà nà mí, tí mí mọ́lé bí wọn ti ṣe fún bàbá mi láyé ìjọba ológun Buhari - Ọmọ́ Busari Adelakun
Ọgbẹni Aba sọ pe isede yoo ma a wa laarin aago mẹjọ alẹ si mẹfa owurọ, titi nkan yoo fi pada bọsipo lori eto aabo.
O ni igbesẹ naa waye nitori bi awọn ọdọ naa ko ṣe sinmi ogun, bo tilẹ jẹ pe Gomina Samuel Ortom ati awọn olori ilu ti da si ọrọ naa.
O ṣalaye pe rogbodiyan naa kọja bo ṣe yẹ, nigba ti awọn ọdọ naa tun yabo agọ ọlọpaa kan lọjọ Aje, lati kọluu.
"Wọn dana sun dukia awọn ti wọn ba ti fi ẹsun kan, koda wọn pa pasitọ kan."
"Yatọ si eyi, wọn lu ọkunrin kan titi to fi daku, nitori wọn fura si pe o ti mu nkan ọmọkunrin eeyan kan."
Àwọn ọ̀dọ́ Benue pa pásítọ̀ ti wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó ń mú ǹkan ọmọkunrin

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Benue ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú pásítọ̀ kan tó n jẹ́ Uhembe Jacob ti àwọn ọ̀dọ́ Daudu pa lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó jí ǹkan ọmọkùnrin àwọn ènìyàn
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ náà, Anene Suewese Catherine fí ìdí ikú pásítọ̀ náà múlẹ̀, ó ni ọkùnrin náà kú, lẹ́yìn tó sá kúrò nínú ilú Daudu lọ sí abúlé míràn.
Wòlí Uhembe Jacob ló ni ìjọ Divine Shadow ni ìlú Daudu, ní ìjọba ìbílẹ̀ Guma, ìpińlẹ̀ Benue.
- Ọmọ Nàìjíríà mẹ́fa tó n fi owó ránṣẹ́ sí Boko Haram rẹ́wọ̀n he ní Dubai
- Ìjọba Eko fẹ́ tú olùwọ́de EndSARs 253 sílẹ̀ lọ́jọ́ Ajé nínú 361 tó wà láhàámọ́
- Ojúlówó Shina Rambo yọjú sígboro lọ́jọ́ Àìkú, ó fi ìka hánu lórí ìpànìyàn tó ti ṣe
- Wo àwọn ọmọ Naijiria mẹ́ta tó jáwé olúborí nínú ìdìbò sílé aṣòfin ilẹ̀ Amẹrika
Ìròyìn sọ pé, láti ǹkan bi ọsẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn báyìí ni àwọn ọkùnrin ní agbègbè náà ti ń sọ pé ǹkan ọmọkùrin àwọn kò ṣiṣẹ́ mọ́
Kí a tó wí kí a tó fọ̀, ènìyàn bí méjìlá tí n jáde lkáti sọ pé ǹkan náà ló n ṣẹlẹ̀ sí wọ́n
Sáájú ni wọn ti kọ́kọ́ nàka sí ọkùnrin kan ti wọ́n ń pe ni Ernest Tsuwe, tí ọkùnrin náà sì lọ pokuso nígbà ti gbogbo ènìyàn ni kí ó dá ǹkan ọmọkùnrin àwọn padà.
Sùgbọ́n ẹ̀yìn o rẹyìn ní àwọn ọdọ́ ya sí ìgbòrò tí wọ́n sì n pe ìjọba ìbílẹ̀ láti gbé ìgbésl láti wá ẹni tó n mú ǹkan ọmọkunrin awọn lọ
Lẹ́yìn ìfẹ̀hónú hàn ni àwọn àgbààgbà ìlú pe ìpàdé ní ọjọ́ kẹta oṣù kọkanlá níbi ti wọ́n ti kéde pé Ernest jẹ́ ọ̀rẹ́ ọkùnrin kan tó n jẹ́ Saka Noah àti Wòlí Uhembe to jẹ́ agbódegbà àwọn tó n jí ǹkan ọmọkùnrin.
Wọ́n ni, wọ́n ń fi òògùn gba ǹkan ọmọkpunrin àwọn ènìyàn, lẹ́yìn náà ni wọ́n yóò ni kí wọ́n san owó láti gba ìwòsàn lọ́dọ̀ wọn.
Ọ̀rọ̀ yìí ló dá rògbòdìyàn sílẹ̀, tí ọ̀dọ́ sì rọ́ bò àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí láti lù wọ́n pa.
Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ọlọ́pàá lára Saka, nígbà ti Woli sáré wọ inú mótò rẹ̀ tó sì mórí lé Yelwata ní ìpińlẹ̀ Nasarawa
Àwọn ọ̀dọ́ náà kọ́kọ́ dáná sun ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, nígbà tí ó yá ni ìròyìn ikú rẹ̀ tàn ká.
Kódà, ọ̀rọ̀ náà kò yọ àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ sílẹ̀ bí àwọn náà ṣe ya sí ìgboro láti bèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú pásítọ̀ wọ́n, àwọn ọlọ́pàá pẹ̀lú ti fi wọ́n lọ́kan bálẹ̀ àwọn yóò wádìí ǹkan tó ṣeku pa ọkùnrin náà.
Ṣe lóòtọ́ ni pé, ǹkan ọmọkùnrin ń sọnu ní Daudu?
Agbẹnusọ ọlọ́pàá sọ fún BBC pé kò sí ǹkan ọmọkunrin tí wọ́n jí mú àti pé gbogbo àwọn tí wọ́nn kó lọ si ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò, sáká ni ara wọ́n dá, kò sí ǹkan tó sọnù níbẹ̀.
Ó tún sàlàyé pé, lásìkò yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn agbègbè náà ló n jáde pé àwọn ò rí ǹkan ọmọkùnrin àwọn mọ́.
Ọlọ́pàá ńi ó ṣeẹṣe ko ni ǹkan ti ó n mú ǹkan ọmọkunrin wọn ṣe ṣégeṣège oo, sùgban kò sí ẹni tó mú ǹkankan lára wọn.
Ó fi kun pé, ènìyàn mẹ́jọ ni wan ti mú báyìí lórí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì ti gbé wọn lọ sí ilé ẹjọ́.
Wọ́n fi kún pé bí wọ́n ṣe kọlu àwọn ènìyàn náà kò bójúmu rára, gbogbo ẹni tó bá sì lọ́wọ́ níní ọ̀rọ̀ náà ni yóò foju ba ilé ẹjọ́















