Ore Hospital Mortuary: Ìjọba Ondo ní òun yóò gbé ibùdó ìgbókùsíí kúrò nílé ìwòsàn náà

Ile iwosan

Oríṣun àwòrán, @OndoStateHealth

Ìjọba Ondo ṣetán láti wá ojútùú sí bí mọ́súárì ilé ìwòsan Ore ko ṣe ráyè gba òkú mọ́

Ore General Hospital: Ìjọba Ondo yóò wá wọ̀rọ̀kọ̀ ṣàdá lórí bí mọ́súárì ilé ìwòsan Ore ko ṣe ráyè gba òkú mọ́

Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe, oun ṣetan lati wa ojutuu sí bi ile igbokusi, mọsuari ile iwosan ijoba to wa Ore ṣe kun fọfọ, debi pe ko raye gba oku mọ bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adele Kọmiṣọnna eto ilera ipinlẹ naa, Dokita Ajibayo Adeyeye, to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe, lootọọ ni mọsuari ile iwosan naa ti kun debi pe ita ni wọn n tẹ oku si bayii, eleyi to le fa ajakalẹ arun lagbegbe naa.

Àkọlé fídíò, Ifa Worshippers: Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ń fẹ́ kíjọba pín èrè òṣèlú alágbádá yíká gbogbo ẹ̀sìn

Dokita Adeyeye ni, oku awọn eeyan to ku ninu ijamba ọkọ lopopona mọrosẹ Ore si ilu Benin, lawọn ọlọpaa maa n ṣaaba gbe lọ si mọsuari ile iwosan naa.

Adele Kọmiṣọnna eto ilera ipinlẹ Ondo ni, ọrọ naa ti ju agbara awọn oṣiṣẹ ile iwosan ọhun lọ nitori wọn o ti yanju ọrọ awọn alaisan ti wọn n tọju tan, ka to wa sọ nípa àwọn to ti ku.

"Ọga ile iwosan naa sọ fun mi pe, awọn ọlọpaa ko dẹkun gbigbe oku awọn eeyan wa lẹyin ti ile igbokusi ile iwosan ọhun ti kun," Dokita Adeyeye lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà

Dokita Adeyeye ni oun lọ si ile iwosan naa lati ri bi nkan ṣe ri gan an níbẹ, o ni ijọba ko ba sọ mọsuari ile iwosan naa di nla amọ ko s'aye mọ níbẹ.

Kọmiṣọnna eto ilera Ondo ni, ohun ti ijọba n gbero lati ṣe bayii ni ki wọn ko mọsuari kuro nile iwosan ọhun, lati lọ kọ ọ sí ibo miran.

Dokita Adeyeye ni lai deena pẹnu, ijọba ipinlẹ Ondo n ṣiṣẹ lori ọrọ naa.

Ọ̀pọ̀ òkú fọ́nkálẹ̀ nílé ìwòsàn ìjọba ní Ore, ìpayà àjàkálẹ̀ àrùn gbàlú kan

Ibudo igbokusi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe o se e se ki ajakalẹ arun bẹ silẹ lagbegbe Ore nipinlẹ Ondo nitori iwadii ti fihan pe ọgọọrọ oku lo sun sori ara wọn nile iwosan ijọba to wa nilu naa.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ti salaye, se ni wọn gbe awọn oku silẹ kaakiri awọn ilk ile iwosan naa, ti ojo si n pa wọn mọ ibẹ.

Awọn aworan to ba ni lẹru ati fidio to ba ni ninujẹ nipa ayika ibudo igbokusi to wa nile iwosan naa, fihan pe awsn oku ti kun de ẹnu ọna, ti wsn si fi paanu bo awọ́n miran mọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, wọn tun lo biriki lati se aala laarin oku kan si ekeji, bẹẹ si ni ninu ibi kan to dabi yara, oku ọkunrin ati obinrin lọpọlọpọ lo wa nilẹ ilẹ.

Ile iwosan

Oríṣun àwòrán, @OndoStateHealth

Iyalẹnu tun lo jẹ pe oku meji mii ti wọn fẹyin ti lara ogiri ni wọn ti gbẹ di egungun, to si jẹ pe ẹrọ amunawa kekere meji pere ni ibudo igbokusi naa ni.

Awọn ara adugbo ibi ti ile iwosan ijọba naa wa ni ọrọ naa ti ka laya, to si ti ko ipaya ati irẹwẹsi ba.

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ yii, Kọmisana feto ilera, Ajibayo Adeyeye ni ibi ti wọn kọ ile iwosan naa si lo fa isoro nitori oju titi lo wa.

"Ọpọ awọn eeyan to lugbadi ijamba ọkọ ni wọn maa n gbe wa sile iwosan naa, ti wsn yoo si gbagbe wọn sibẹ.

Nigba mii, awọn ọlọpaa yoo kan gbe oku miran wa, ti wsn yoo si gbe wọn kalẹ lai boju wẹyin mọ."

Àkọlé fídíò, Grandma Maruwa: Ó yẹ kí obìnrin sisẹ́ láì wojú ọkọ kó tó jẹun

Adeyeye fikun pe pupọ ninu awọn oku naa lo ku lati ipasẹ ijamba ọkọ lai ri ẹni beere wọn, ti ẹjọ si tun n lọ lọwọ nipa iku awọn oku miran eyi ti ko jẹ ki wọn le e sin wọn.

O wa pari ọrọ rẹ pe bawọn eeyan to ni ilẹ lagbegbe naa se maa n taku lati fi ilẹ wọn silẹ pe ki wọn sin awsn oku naa si, lo mu ko nira lati sin awsn oku naa papọ.

Amọ o woye pe o seese ki wọn wa ibudo kan ti wọn yoo ti dana sun awọn oku naa, ti ko ba si ọna abayọ miran, lọna ati wa ojutu si isẹlẹ yii.