Agbekoya Crisis: Kunle Adelakun fi ẹ́sùn kan sọ́jà pé wọn fìyà jẹ òun n‘Ibadan

Kunle Adelakun

Oríṣun àwòrán, The Punch

Ọkan lara awọn oloye Ẹgbẹ Agbẹkọya nilẹ Yoruba, Jagunmolu Agbẹkọya, Kunle adelakun, tii tun se ọkan lara awọn ọmọ oloogbe Busari Adelakun, ti salaye ohun ti oju rẹ ri ni bareke ologun to wa ni Odogbo, nilu Ibadan.

Adelakun, ti baba rẹ ti ọpọ eeyan mọ si Ẹruobodo laye oselu alagbada keji nipinlẹ́ Oyo lo ku si ahamọ lasiko ijọba Buhari/Idiagbon lọdun 1984 nigba ti wọn sọ awọn oloselu kan si atimọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu iwe iroyin The Punch, Adelakun ni awọn ṣọja naa gbe oun lọna aitọ, ti wọn si fi iya jẹ oun ati awọn eeyan miran laipẹ yii, gẹgẹ bi wọn ti se fiya jẹ baba oun lọdun mẹrindinlogoji sẹyin.

Àkọlé fídíò, Sickle Cell In Nigeria: Makinde ní ìgbàgbọ́ ninú ìdílé òun ṣèdíwọ́ láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀

O ni "lasiko ti awọn lọ fun ipade ọrọ eto aabo nipinlẹ Oyo, nileeṣẹ ijọba, ni ede aiyede waye laarin ṣọja kan, ati ẹnikan lara awọn ọmọ ọdẹ Agbẹkọya.

Adelakun ni amọ oun ko si wahala lasiko ti oun ba wọn dasi ọrọ naa lati yanju rẹ".

"Nkan ti mo gbọ nigba ti mo de ibẹ ni pe, ṣọja kan gba ọmọ Ẹgbẹ Agbẹkọya kan l'eti, to ṣi ṣe e ṣe ko jẹ pe onitọun naa gba a l'eti pada."

Nibi ti mo ti n gbiyanju lati yanju rẹ, ni ọpọ awọn sọja ti de sibẹ, ti wọn si mu mi pe ki n tọka si ẹni to gba sọja naa l'eti."

Àkọlé fídíò, Bose Okeowo: Àárẹ̀ kékeré ló sọ mi dí aláàbọ̀ ara yìí ṣùgbọ́n...

"Lati ibẹ si ni wọn ti gbe emi ati awọn ọlọdẹ miran lọ si bareke ologun to wa ni Odogbo, Ọjọọ, Ibadan.

O ṣalaye pe, wọn fi iya jẹ awọn nibẹ, debi i pe ileewosan ni oun wa fun ọjọ meji, lẹyin ti wọn gba itusilẹ oun.

O ni ọgagun kan to ba wọn nibẹ, lo tun paṣẹ pe ki wọn tu awọn silẹ.

Amọ a tẹsiwaju lati fi idi isẹlẹ naa mulẹ pẹlu ileesẹ ologun laipẹ.