Arabic on Naira: CBN ní owó gọbọi ní yóò ná Nàíjíríà láti tẹ owó tuntun jáde

Aworan owo Naijiria

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nairametrics

Ileẹjọ giga apapọ nilu Eko ti ṣetan lati gbẹjọ lori ẹsun t'agbẹjọro kan gbe wa siwaju rẹ pe, ki ile ifowopamọ apapọ Naijira, CBN, yọ Keu ti wọn kọ si ara Naira kuro.

Lọjọ iṣẹgun yi ni igbẹjọ yii yoo waye.

Agbẹjọro taa n wi yii, Malcolm Omirhobo tun fẹ ki ile ẹjọ paṣẹ fun ileeṣẹ ologun Naijiria lati yọ alifabẹti ati ọrọ keu to wa lara ami idanimọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ipe yii di dandan nitori Naijiria kii ṣe ilẹ ta ti n tẹle ofin ẹsin tabi ilẹ to n tẹle ofin ẹsin Islam.

Agbẹjọro yii tun fẹ ki wọn fi ede abinibi Yoruba, Igbo, tabi Hausa parọ ọrọ kewu tabi ede gẹẹsi to ba wa lara owo Naijiria.

Godwin Emefiele

Oríṣun àwòrán, @Emefiele

Ṣugbọn Banki apapọ Naijiria, CBN, ti sọ fun ile ẹjọ giga ijọba apapọ nipinlẹ Eko pe, owo gọbọi ni yoo na orilẹ-ede Naijiria lati tẹ owo tuntun jade.

Ile ifowopamọ agba Naijiria naa ni kikọ nnkan lede larubawa kii ṣe ami idanimọ ẹsin Islam.

O ni ọpọ awọn eeyan to n gbe lagbegbe ariwa Naijiria ni wọn n sọ ede larubawa bo tilẹ jẹ pe ede Gẹẹsi ni ede tofin Naijiria fontẹ lu gẹgẹ bi ede ajumọsọ.