UK Covid Vaccine: Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 yóò dé sí Nàìjíríà nínú oṣù kíní ọdún 2021

Mínísítà tó n rí sí ètò ìlera, Osagie Ehanire lo fìdí ìròyìn náà múll lajọ́rún lẹ́yìn ìpàdé ìgbìmọ̀ aláṣẹ́ ìjọba tó wáye.

Oríṣun àwòrán, WHO

Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí kéde pé abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 yóò dé sí Nàìjíríà ni inú oṣù kíní ọdún 2021.

Mínísítà tó n rí sí ètò ìlera, Osagie Ehanire lo fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ l'Ọjọ́rú lẹ́yìn ìpàdé ìgbìmọ̀ aláṣẹ́ ìjọba tó wáye.

Ó ní àwọn onímọ̀ nípa ìṣègún ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti le sọ pàtó irú àbẹ́rẹ́ ti yóò dára fún àwọn ọmọ Nàìjíríà, pàápàá jùlọ nítorí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò ni amú omítutu tó tuntùn tó ìwọ̀n ọgọ́rin.

Ìjọba àpapọ̀ ti kéde ṣáájú pé àwọn ń retí abẹ́rẹ́ tí yóò tó ogún mílíọ̀nù ni ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2021.

Arábìnrin ẹni àádọ̀rún ọdún ló kọ́kọ́ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tí Pfizer ṣe síta

Aworan ẹni to gba abẹrẹ ajẹsara

Arabinrin ẹni aadọrun ọdun kan ti di ẹni akọkọ ti yoo gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 tuntun ni ilẹ Gẹẹsi.

Eyi wa lara eto fifun ọpọ eeyan labẹrẹ yi kaakiri ilẹ naa.

Margaret Keenan ti yoo pe ọdun mọkanlelaadọrun lọsẹ to n bọ sọ pe ẹbun ọjọ ibi to dunmọ oun ju ni wọn fun oun yi.

Ni nkan bi ago mẹfa abọ kọja iṣẹju kan ni o gba abẹrẹ yi, akọkọ abẹrẹ ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin ti ile iṣẹ Pfizer/BioNTech gbe jade.

Ireti wa pe miliọnu mẹrin eeyan ni yoo ri abẹrẹ yi gba nigba toṣu yoo ba fi pari.

Awọn agbalagba tọjọ ori wọn kọja aadọrun ọdun ati awọn oṣiṣẹ ilera ni yoo kọkọ jẹ anfaani abẹrẹ yi lọna ati daabo bo awọn to wa ninu ewu julọ.

Nọọsi agba nileewosan University Hospital Coventry lo fun ni abẹrẹ naa.

Obinrin kan duro sẹgbẹ ami idamọ ileesẹ Pfizer

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilẹ Gẹẹsi ni orileede akọkọ lagbaye to ti bẹrẹ si ni lo abẹrẹ ajẹsara ti Pifizer pọn lẹyin ti ijọba fontẹ lu lilo rẹ lọsẹ to kọja.

Abẹrẹ naa kii ṣe dandan.Ẹni to ba wu lati gba a ni wọn yoo fun.

Abẹrẹ ajẹsara fun idena arun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Abẹ́rẹ́ àjẹsára tó dájú fún ìdènà àrùn Coronavirus ti jáde

Awọn onimọ sayẹnsi ti gbe abẹrẹ ajẹsara ti yoo koju arun Coronavirus jade.

Ileeṣẹ apoogun Pfizer ati BioNTech lo se abẹrẹ ajẹsara naa jade.

Wọn wa sapejuwe ọjọ ti wọn gbe abẹrẹ naa, ti yoo koju arun Coronavirus jade, gẹgẹ bi ọjọ to lamilaaka ni igbe aye awọn onimọ sayẹnsi ati gbogbo ẹda alaaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn apoogun naa ni awọn ti lo abẹrẹ ajẹsara naa ni ara eniyan bii ẹgbẹrun lọna mẹtalelogoji ni orilẹede mẹfa, ti ko si ni ipalara kankan fun wọn.

Ileeṣẹ apoogun naa ni awọn yoo bẹrẹ si ni pese abẹrẹ ajẹsara naa fun iṣẹlẹ pajawiri lati opin osu yii.

Abẹrẹ ajẹsara fun idena arun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Reuters

Bawo ni abẹrẹ ajẹsara yii yoo ṣe ṣiṣẹ si ni agọ ara?

Awọn onimọ sayẹnsi ti sọ wi pe, abẹrẹ ajẹsara tabi oogun oyinbo to lagbara ni awọn lero wi pe o le koju arun Coronavirus lagbaye.

Iwadii abẹrẹ ajẹsara tuntun yii fihan wi pe, awọn eniyan yoo nilo ati ma a gba ni ẹẹmeji laarin ọsẹ mẹta, ki o le ṣiṣẹ daradara lara.

Iwadii ti wọn ṣe ni orilẹede Amerika, Germany, Brazil, Argentina, South Africa ati Turkey fihan pe, laarin ọjọ meje ti wọn ba ti gba abẹrẹ ajẹsara keji naa ni arun naa yoo dopin lagọ ara ẹni to ba lo.

Abẹrẹ ajẹsara fun idena arun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igba wo ni abẹrẹ ajẹsara yii yoo bẹrẹ si ni wa fun awọn eniyan lati gba si ara wọn?

O ṣeeṣe ko jẹ pe eniyan perete ni yoo le ri abẹrẹ ajẹsara yii gba ninu ọdun yii.

Ileeṣẹ apoogun,Pfizer ati BioNTech ni awọn yoo pese abẹrẹ ajẹsara naa ni ọlọgọọrọ, ki awọn le gbe lọ si ọdọ ijọba lati fi ontẹ lu.

Lẹyin ti wọn ba ti fi ontẹ lu abẹrẹ ajẹsara naa, ni wọn ṣẹṣẹ le gbe lọ si awọn orilẹede to wa lagbaye.

Bakan naa ni wọn ni awọn yoo pese abẹrẹ ajẹsara miliọnu aadọta ki ọdun yii to pari, ti awọn yoo si pese abẹrẹ ajẹsara biliọnu kan o le ni ọdun to n bọ.

Abẹrẹ ajẹsara fun idena arun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, EPA

Awọn wo ni yoo kọkọ gba abẹrẹ ajẹsara yii?

Kii ṣe gbogbo eniyan ni yoo ni anfaani si abẹrẹ ajẹsara yii lẹẹkan naa.

O ṣeeṣe ko jẹ awọn oṣiṣẹ ni ileewosan ati awọn oṣiṣẹ eto ilera ni yoo kọkọ ni anfaani abẹrẹ ajẹsara yii.

Bakan naa ni awọn orilẹede kọọkan ni yoo sọ ẹni ti yoo kọkọ ni anfaani si awọn abẹrẹ ajẹsara yii.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Amọ, o ṣeeṣe ki Ilẹ Gẹẹsi kọkọ fun awọn agbalagba ati awọn ti wọn tete n ko arun Coronavirus yii nitori ailera ara wọn.

Wọn tun fikun wi pe, bii abẹrẹ ajẹsara naa ba ṣe ṣiṣẹ si lara awọn eniyan ni yoo sọ bi wọn yoo ṣe lo si fun awọn eniyan.

Amọ, awọn ọdọ langba ti eroja idena aisan ara wọn ji pepe lo ṣeeṣe ki wọn ma tete ri abẹrẹ ajẹsara naa gba.

Obinrin kan duro sẹgbẹ ami idamọ ileesẹ Pfizer

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Njẹ o ṣeeṣe ki isoro kan suyọ lasiko abẹrẹ ajẹsara naa?

Awọn ibeere wa lorisirisi ti ko tii si idahun si.

Amọ a ko mọ boya abẹrẹ ajẹsara naa yoo dẹna itankalẹ arun naa lati ara eniyan kan si omiran, boya yoo pa kokoro naa ni kiakia, ti ẹni to nii ko si ni lee ko ran ẹlomiran.

Ati wipe ibeere ṣi wa lori igba ati akoko ti abẹrẹ ajẹsara naa yoo ṣiṣẹ da lara eniyan, ṣe ọdun kan ni abi oṣu melo?

Bakan naa ni ipenija wa lori bi wọn yoo ṣe fun eniyan miliọnu lọna ọgọrin ni abẹrẹ ajẹsara, ti o si ṣe wi pe wọn gbọdọ gbe oogun naa ṣi ibi to ba tutu bii inu yinyin (minus 80C).

Iwadii fihan wi pe, oogun naa ko ni aleebu kankan fun ẹni to ba lo o, amọ a ko le sọ wipe otitọ ni lai wẹyin, nitori oogun paracetamol ti ko ni abawọn, naa ni ipenija tirẹ.

Abẹrẹ ajẹsara fun idena arun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bawo ni abẹrẹ ajẹsara Coronavirus yii yoo ṣe ṣiṣẹ ni agọ ara?

Ọpọlọpọ abẹrẹ ajẹsara ni o ṣi wa labẹ ayẹwo ipele kẹta lọwọ, amọ eleyii lo si mu aṣeyọri jade.

Ohun ti abẹrẹ ajẹsara naa ṣe ni lati wọ inu isan ara lọ, ti yoo si pese eroja ara 'protein' ti yoo dena arun Coronavirus to fẹ ba sẹẹli ara jẹ.

Bakan naa ni abẹrẹ ajẹsara naa yoo tun awọn sẹẹli ara ti arun Coronavirus ti bajẹ ṣe pada.

Eleyii yoo si mu ara ẹni to ba ni aarun naa ji pepe pada.

Abẹrẹ ajẹsara fun idena arun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kini awọn adari orilede lagbaye sọ nipa abẹrẹ ajẹsara naa?

Oluranlọwọ pataki fun ijọba lori eto ilera ni Ilẹ Gẹẹsi, Ọjọgbọn Chris Whitty ni, esi ayẹwo naa ṣe afihan iru agbara ti imọ sayẹnsi ni ati ifọkanbalẹ pe ọdun to n bọ yoo dara lati koju arun Coronavirus.

Aarẹ ilẹ Amẹrika ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Joe Biden ni iroyin ayọ ni abẹrẹ ajẹsara naa jẹ fun gbogbo eniyan ni agbaye.

''O di dandan ki a ni igbẹkẹle pe opin aarun Covid-19 ti n sun mọ etile, ti ko si jinna mọ."

Olootu ijọba Ilẹ Gẹẹsi sọ wi pe, abajade ayẹwo abẹrẹ ajẹsara naa fihan wi pe yoo koju arun Coronavirus, nitori naa awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati ri wi pe awọn arugbo ati awọn ti arun Conavirus n tete mu ni awọn kọkọ fun ni abẹrẹ ajẹsara naa.

Awọn onimọ sayẹnsi ni fasiti Oxford naa ni ọkan awọn balẹ nitori aṣeyọri nla lo jẹ fun awọn, ti arun Coronavirus naa ko si ni pẹ lọ si okun igbagbe.