Covid 19 vacine updates: America kan sárá si Dókítà Ogbuagbu, ọmọ Nàìjíríà tó ṣàwárí abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19 àkọ́kọ́

Oríṣun àwòrán, others
Wo dókítà ọmọ Nàìjíríà tí àgbáyé ń wárí fún nítorí abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19
Ọjọgbọn imọ nipa iṣegun oyinbo ati ajakalẹ arun ni Dokita Ogbuagu ni ile ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo ni Fasiti Yale.
Ileeṣẹ aṣoju ijọba Amẹrika lorilẹede Naijiria ti kan sara si Onyema Ogbuagu to jẹ dokita iṣegun oyinbo kan.
Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ ọmọ bibi orilẹede Naijiria ti o si ṣe iṣẹ takuntakun nipa awari abẹrẹ ajẹsara akọkọ to ogun rẹ ṣe e fi gbari lorilẹede Amẹrika.
- Mílíọ́nù mẹ́wàá Náírà ni ilé ẹjọ́ ni kí Kábíyèsí san gẹ́gẹ́ bí owó ìtaran ilẹ̀ tí ó gbà lọ́nà àìtọ́
- Kíni àjọ ọlọ́pàá ń ṣe lórí bí agbófinró ṣe ń ṣèèṣì pànìyan lójoojúmọ́?
- Iṣu ata yáan yàan! Iṣẹ́ fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá tó gba N100k lọ́wọ́ awakọ̀ tó gba"One way" l'Eko
- Wo ọ̀nà tí ọrọ̀ ajé Naijiria tó dẹnu kọlẹ̀ gba kàn ọ
- Jemila dáná sún ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti ọ̀rẹ́bìnrin tó bá nílé
Ileeṣẹ apogun ni Amẹrika ni, Pfizer kede ṣaaju loṣu kọkanla pe iwadii latara abẹrẹ ajẹsara rẹ fihan pe o n ni eso to dara.
Wọn fidiẹ mulẹ pe o le ni ida aadọrun awọn to n lo abẹrẹ ajẹsara naa to n ri iwosan gba lọwọ arun COVID-19 ni America.
Oniruuru ọna l'awọn ọmọ Naijiria ti gba ko ipa ninu idagbasoke agbaye.
Oṣuba nla ree fun Dokita Onyema Ogbuagbu ni fasiti Yale fun sise iranwọ lati ṣawari abẹrẹ ajẹsara fun arun COVID-19 lorilẹ-ede Amẹrika!"
Eyi ni ọrọ ti ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede Amẹrika fi sita loju opo Twitter rẹ lọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla.
Nigba to n sọrọ pẹlu awọn akọroyin leyin ti ileeṣẹ apogun Pfizer kede abajade esi ayẹwo rẹ lori abẹrẹ ajẹsara naa,
Dokita Ogbuagbu ni omi ṣi n bẹ laamu ati pe iṣẹ ṣi pọ ni ṣiṣe lati fi da awọn eeyan loju pe ko sewu pẹlu abẹrẹ ajẹsara naa.
O ni ileeṣẹ Pfizer ati BioNTech ti wọn pawọpọ gbe abẹrẹ ajẹsara naa jade ti n beere fun iwe aṣẹ latọwọ ijọba orilẹede Amẹrika eleyii ti wọn n reti pe yoo bọ sii titi ipari oṣu kọkanla.
Ireti wọn ni pe wọn yoo lee pese aadọta miliọnu abẹrẹ naa titi opin ọdun 2020 ati biliọnu kan o le ọdunrun miliọnu abẹrẹ naa nigba ti ọdun to n bọ yoo ba fi pari.
Moderna, ileeṣẹ apogun miran lorilẹ-ede Amẹrika naa ti kede pe ida mẹrinlelaadọrun atabọ (94.5%) ninu awọn ẹgbẹrun lọna ọgbọn (30,000) to lo abẹrẹ ajẹsara ti wọn lo bọ lọwọ arun COVID-19.
- Ìjọba Naijiria faraya nínú lẹ́tà tó kọ sí CNN lórí ìwádìí rẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Toll Gate
- Omotara pàdánù isẹ́ olówó ńlá nítorí ó fi ọtí ẹlẹ́rìndòdò sódà lá ọmọ alágbe lójú
- Ilé aṣòfin orílẹ̀-èdè UK n gbèrò fífí ìyà jẹ àwọn adarí Naijiria tó lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn ENDSARS
- Jemila dáná sún ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti ọ̀rẹ́bìnrin tó bá nílé
- Adájọ́ ti pàṣẹ pé kí wọ́n mú ọmọ Rasheed Maina, Faisal, tó sá mọ́ ilé ẹjọ́ lọ́wọ́
O le ni igba awọn abẹrẹ ajẹsara miran ti iwadii lori wọn n lọ kaakiri agbaye lati koju arun COVID-19.
Ko din ni miliọnu mọkandinlọgọta eeyan to ti ko ajakalẹ arun COVID-19 lagbaye lati igba ti eegun rẹ ti kọkọ ṣẹyọ.
Orilẹ-ede China lo ti jade ni osu kejila, ọdun 2019 ti o si ti ran awọn eeyan to le ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọdunrun lọ sọrun.
- Wo ọkùnrin ẹni ọdún 55 tí wọ́n ká agbárí èèyàn mẹ́rin, àti àwọn ẹ̀yà ara mìí mọ́ lọ́wọ́ ní Ogun
- Gbọ́yì-sọ̀yí àti ìròyìn èké láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ wa ló ṣáábà ma ń da ìgbéyàwó àwọn òṣèré rú- Ọpẹ Ayeola
- Ǹkan tí ó yẹ ki o mọ̀ nípa Burna Boy
- Ilé ẹjọ́ dájọ́ ẹgba mẹ́ẹ̀dóògún fún ọ̀daràn tó jí Iphone ní Kaduna
- Ọlọ́pàá tó dúró yìí gbá mi létí lẹ́ẹ̀mẹrin-Ajẹ́rìí ìwà ipá níwájú ìgbìmọ̀ SARS


















