Amos Dauda, Iphone: Ilé ẹjọ́ dájọ́ ẹgba mẹ́ẹ̀dóògún fún ọ̀daràn tó jí Iphone ní Kaduna

Ilé ẹjọ́ dájọ́ ẹgba mẹ́ẹ̀dóògún fún ọdànran tó jí Iphone

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdọ́mọkunrin ẹni ogún ọdun kan, Amos Dauda ni ilé ẹjọ́ Májísíréétì ni ìlú Kaduna ṣe dájọ́ pe kí wọ́n fún ni kòbókò ẹgba mẹ́ẹ̀dógún nítorí o jí Iphone.

Fóònù náà tí owó rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdájọ Naira.

Ọ̀daràn náà tó n gbé agbègbè Barnawa ní ìpińlẹ̀ Kaduna ní wọ́n fi ẹsùn onípele méjì kàn fún olè jíjà , ti òun pẹ̀lú sí gbà pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn.

Adájọ́ Ibrahim Emmanuel dájọ́ pé ki wọ́n fún ni ẹgba mẹ́ẹ̀ddógún ki ó sì tóju àyíka ilé ẹjọ́.

Bákan náà ni Adájọ́ rọ olùjẹ́jọ́ náà láti máa hùwà rere kí ó sì jìnà réré sí ìwà ọ̀dáràn, nítorí tí ẹjọ́ rẹ̀ bá tun padà sí ilé ẹjọ́, ilé ẹjọ́ le máa ṣíjú àaǹú wòó mọ́.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí

Sáájú ní ọlọ́pàá Chidi ni Stephen Fracis kan mu ẹjọ́ wá si aga ọlọ́pàá Gabasawa ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún, oṣù kọkànlá ọdún yìí.

Gẹ́gẹ́ bi ọlọ́pàá náà ṣe sọ, Dauda jí fóònù nínú ilé òun lásìkò tí òun sùn lọ́wọ́ to sì jí fóònù tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ náírà.

Ọlọ́pàá ni wọ́n mú ọdaran náà lásìkò tó n gbìyànjú láti sálọ, ti wan sì gbà fóònù náà lọ́wọ́ rẹ̀

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́