Ondo Heardsmen vs Falae: Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Ondo ni Olóyè Falae kò tí ì mú ẹjọ́ wá si àgọ́ ọlọ́pàá kankan

Oríṣun àwòrán, Falae
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Ondo ti sàlàyé fun BBC pé títí di àsìkò yìí, àwọn kò ti i rí ìwé kankan láti ọ̀dọ Olóyè Olu Falae lórí ìṣẹ̀lẹ̀ pé àwọn darandaran.
Lásìkò tí BBC Yoruba bá agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Tee Leo Ikoro sọ̀rọ̀ lọ́san òní ló sàlàyé pé, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ láti ka a ninu iwé ìròyìn nípa ǹkan ti ó n ṣẹ̀lẹ̀ ní oko Olu Falae.
Ikoro ni gẹ́gẹ́ bi irú ènìyàn ti Olu Falae jẹ́ ni àwùjọ, kìí ṣe òun ni ǹkan yóò sẹlẹ̀ sí ti àwọn ọlọ́pàá yóò wa kọ etí ikún si.
O ní àwọn DPO méjì lágbègbè ibi ti oko Olu Falae wa ni òun ti pè láti mọ̀ bóyá wọ́n gbọ́ ohunkóhun nípa pé, àwọn darandaran wọ oko olóye Olu Falae.
Nítori náà, ọgá ọlọ́pàá ni ko tii si àkọsílẹ̀ kankan pé wọ́n mú ẹjọ́ wá

Oríṣun àwòrán, Falae Facebook
Mí o fẹ́ kí wọ́n tún jí mi gbé léèkejì- Olu Falae pariwo síta pé Amotekun
Àkọwé ìjọba àpapọ̀ nígbàkan rí, Olóyè, Olú Falae ti ke gbàjarè síta lórí bí àwọn Fulani darandaran ṣe n da oko òun láàmú.
Falae to jẹ́ ọkan lára àgbà ẹgbẹ́ afẹnifẹ́re sàlàye pé bi wọ́n ṣe n ya bo inú oko òun ni Ilado ni ìjọba ìbílẹ̀ Akure North ní ìpińlẹ̀ Ondo kò bójúmu tó.
Nínú lẹ́ta tó kọ sọwọ si àdari ẹ̀ṣọ́ ààbò tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dásílẹ̀ ní ìpińlẹ̀ Ondo, ẹ̀ṣọ́ àbò Amotekun Adeniji Adeleye ni Falae ti rọ wọ́n pé òun kò fẹ́ kí wọ́n jí òun gbe bi ti ọjọ́kọkanlélógún, oṣù kẹsan an, ọdún 2021.
- Òtítọ́ làwọn sọ́jà gbé ìbọn tó lọ́ta gidi nínú lọ sí Lekki Toll Gate lásìkò ìwọ́de EndSARS- Ọ̀gágun Taiwo
- Báyìí ni ìsìn ṣe lọ lónìí nílé ìjọsìn CCC Genesis Global
- Ọpẹ́ o! Wo bí agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tẹ́lẹ̀, Christian Obodo tí wọ́n jígbé lẹ́ẹ̀kejì ṣe móríbọ́
- Ṣé Sanwo-Olu, gómìnà Eko yóò farahàn níwájí ìgbìmọ̀ olùwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate?
Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ nínú lẹ́tà náà, òun ti fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó alága ẹgbẹ́ Meyetti Allah léti, sùgbọ́n síbẹ̀, àwọn daranran náà ba apáan oko òun jẹ́, ti wọ́n si ṣe àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́rin lése nínú oko.
Lẹ́tà náà kà báyìí pé " láàrín ọ̀ṣẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn àwọn fúlàni darandaran wá sínú oko agbado mi, wọ́n sì jẹ, wọ́n yún tẹ èyí tó kù mọ́lẹ̀.
Mó fi ọ̀rọ̀ náà lọ Alhaji Bello alága Meyetti Allah nípìínlẹ̀ Ondo, sùgbọ́n títí di àsìkò yìí kò ṣe nkankan si, láàrín ọjọ́ díẹ̀ sí àsìkò yìí, wọ́n tún lọ si oko èso ti wọ́n sì kó gbogbo àwọn osàn ti a ko silẹ sálọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá rán àwọn ènìyàn rẹ̀, lati lọ lé wọ́n kúrò, sùgbọ́n títí di àsìkò yìí, òròòru ni wọ́n n wa láti ṣe awọn òṣìṣẹ́ mi ni jàmba, já ìlẹ̀kùn wọ́n ti wọ́n sì n ko wọn ni ẹru lọ.
"Amotekun, ẹ jọ̀wọ́, ẹgbà mi àti àwọn ǹkan ìní mi, Wọ́n ji mi gbé lọ́dún 2015, mí ò fẹ́ ki wọ́n ji mi gbé lẹ́ẹ̀kan si."


















