Christian Obodo, agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tẹ́lẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé lẹ́ẹ̀kan síi

Oríṣun àwòrán, @ajayi_bamidele
Iroyin taa gbọ ni wipe awọn ajinigbe ti tu agbabọọlu Naijiria tẹlẹ, Christian Obodo ti wọn jigbe silẹ.
Iroyin sọ pe ọrẹ timọ timọ rẹ lọjọ pipẹ sẹyin, Big Sam lo fi aridaju didoola rẹ han fun awọn oniroyin ni ilu Warri pe wọn tu u silẹ lalẹ ọjọ Aiku.
Agbabọọlu tẹlẹri to n gba ọwọ aarin fun ikọ agbabọlu Naijiria Super Eagles, Christian Obodo yii ko sọwọ ajinigbe agbebọn lẹẹkeji ni ọna Refinery Road ni Warri, ipinlẹ Delta.
Obodo to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlogoji ni awọn agbebọn kan jigbe nigba ti o duro lati ra ọgẹdẹ lọna lọjọ Aiku gẹgẹ ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ṣe sọ fun awọn oniroyin.
Ni nkan bii ago marun irọlẹ ni iroyin sọ pe wọn ji i gbe lagbegbe ile itura Ishaka, Refinery Road. Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Delta, Onome Onovawakpoyeya lo sọ bẹẹ.
"Oun ati ọrẹbinrin rẹ ni wọn jọ wa pọ ti wọn duro lati ra ọgẹdẹ loju na".
Agbẹnusọ ọlọpaa naa fi kun un pe ko sẹni to tii bere owo itọnran fun itusilẹ rẹ.
Eyi ni igba ikeji ti awọn agbebọn yoo ji agbabọọlu Naijiria tẹlẹri yii. Igba akọkọ to bọ sọwọ awọn ajinigbe ni ọjọ kẹsan oṣu kẹfa ọdun 2012 nigba to n lọ sile ijọsin ni ilu Warri.
Ṣugbọn ọjọ keji ọjọ ti wọn ji i gbe naa ni awọn ọlọpaa tọ ipasẹ awọn ajinigbe naa lẹyin odi ilu Warri nibi ti wọn ti ri Obodo ti wn si gba awọn afurasi kan mu.
Agbabọlu to ti gba ami ẹyẹ bonze ri ni idije AFCON ti ọdun 2006 ṣalaye oun toju rẹ ri lọdun mẹjọ sẹyin nigba ti wọn kọkọ ji i gbe ati bo ṣe moribọ lọna ara tawọn araalu ẹgbẹ wọn atawọn fijilante doola rẹ fifi to awọn ọlọpaa leti ti wọn fi tọ ipasẹ awọn ajinigbe ọhun lọ si ilu Isoko.
Ni nkan bii ọdun melo sẹyin lawọn ajinigbe ti n ṣọ awọn agbabọọlu ọmọ Naijiria to n gbe loke okun ati mọlẹbi lọwọ lẹsẹ.
Bi ko ba gbagbe, wọn ji agbabọọlu super Eagles tẹlẹri mii naa, Onyekachi Apam gbe lọdun 2007. Bakan naa ẹgbọn ọkunrin fun Balogun ikọ yii kan naa tẹlẹri, Joseph yobo ko sọwọ awọn ajinigbe ni ili PortHarcourt ti wọn si tu u silẹ lẹyin ọjọ mẹwaa lọdun 2008.
Lọdun 2019, wọn tun ji baba Balogun ikọ Super Eagles tẹlẹ, Mikel Obi gbe ni Jos ṣugbọn awọn ọlọpaa tu u silẹ nigba to ya.
Iya agbabọọlu mii, Samuel Kalu naa tun ko sọwọ awọn agbebọn ni Aba, ipinlẹ Abia lọdun to kọja. Lẹyin ọjọ mẹfa to lo lakata awọn ajinigbe ni wọn to da a silẹ.
Ko tun pẹ rara ti wọn ji iya akọnimọọgba ikọ Super Eagles tẹlẹri, Samson Siasia gbe lọjọ kẹẹdogun oṣu keje ọdun 2019. Lẹyin bi oṣu meji ati aabọ ni awọn ajinigbe ti fi iya rẹ silẹ.















