Peru President: Ààrẹ kọ̀wé fipòsílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ará ìlú fẹ̀hónúhàn lòdì sí ìjọba rẹ̀

Njẹ Aarẹ le wo sunsun ko tori iwọde ifẹhonuhan ti wọn ṣe lodi si ijọba rẹ ati awọn ẹmi to nu latari rẹ ko fipo silẹ?
Aarẹ fidihẹ orilẹ-ede Peru, Manuel Merino ti kọwe fi ipo silẹ lẹyin ti awọn akẹkọọ meji dero ọrun nigba ti wọn n ṣefẹhonuhan lodi si ijọba rẹ.
Iṣẹlẹ yii waye laarin ọsẹ kan ti Merino gori alefa.
Merino di Aarẹ Peru lẹyin ti wọn fọwọ osi juwe ile fun Aarẹ ana, Martín Vizcarra nitori ẹsun jẹgudujẹra.

Oríṣun àwòrán, @12hourNews
- Wo ọkùnrin tó dáná sun ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ torípé kó gbà látí jẹ́ aya rẹ̀
- Ìpínlẹ̀ Eko ní èèyàn 136 nínú èèyàn 152 lápapọ̀ tó lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Ọlọ́pàá fìyà jẹ mí lọ́dún 2014, mò wà lẹ́yìn àwọn ọ̀dọ́ lórí ìwọde EndSARS- Fayemi
- Awọn ọlọ́pàá gbòde kan ní Ajah, ọwọ́ tẹ àwọn afurasi tó ń jalè
Ko to fi ipo silẹ ni awọn oloṣelu kan ti kọkọ sọ pe ki Merino yọ ọwọ ara rẹ kuro lawo iṣẹjọba orilẹ-ede naa nitori bi awọn agbofinro ṣe kọlu awọn to n ṣe ifẹhonuhan lodi si i.
Ṣaaju akoko yii ni mejila lara awọn minisita to n ba a tukọ ilu ti kọkọ fi iṣẹ silẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ifẹhonuhan bẹrẹ lẹyin ti awọn ara ilu kan fẹsun kan ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede naa pe o yọ Aarẹ ana, Martín Vizcarra lori oye.
Wọn ni iwa iditẹgbajọba ni awọn aṣofin naa hu bi wọn ṣe yọ Vizcarra bi ẹni yọ jiga.
Ifẹhonuhan naa n lọ ni pẹlẹkutu nigba ti wọn kọkọ bẹrẹ ki awọn agbofinro atawọn oluwọde to kọju ija si ara wọn.
Iroyin ni awọn ọlọpaa yin gaasi tajutaju si awọn oluwọde naa lati tu wọn ka lẹyin ti awọn eeyan ọhun kọkọ bẹrẹ si n ju okuta si wọn.
Awọn akẹkọọ meji; Jack Pintado to jẹ ẹni ọdun mejilelogun ati Inti Sotelo, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun lo ba iṣẹlẹ naa lọ.















