Lady Peller: Ọjọ́ ni ọjọ́ tí idán yíwọ́ fún ọkọ mi lẹ́yìn tó gé mi sí méjì, mo kú tán

Alhaji Silifat Peller jẹ ọ̀kan lára àwọn ìyàwó ìlúmọọka Alhaji Moshood Abiola Peller, ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí prof Peller.
Gẹ́gẹ́ bi ìṣe ọkọ rẹ̀ tó ti di olóògbé, Lady Peller, gẹgẹ bi àwọn èniyàn ṣe máa n pé, náà gbówọ́ nínú ká pidán, pàápàá jùlọ láàrìn ọdún 1980 si 1990.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó ṣe láìpẹ́ yìí ló sàlaàyé bi ó ṣe rin ìrìnàjò ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ìyàwò Prof Peller.
Lady Peller to ti di ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin báyìí dúpẹ́ lọ́wọ́ elédùà tó fún ni okun àti àwọn ọmọ ti Ọlọrun fi jíìkí rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Lady Peller
Lásìkò tí Lady Peller ń sọ̀rọ̀ níbí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo náà ló ní òun pàdé ọkọ oun ní ǹkan bi ààdọ́ta ọdún ṣẹ́yìn.
"Láìkò tí mó wà ni Iseyin District Grammar School, Wọ́n wá ṣere nílé ìwé wa, ibẹ̀ ni a ti di ọ̀rẹ́, nígbà tí ó yá, ni a jọ ṣe ìgbéyàwó ti mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ràn lọ́wọ́ bi ìgbákejì pídánpidán."
Alhaja Silifat ni bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun àti professor jẹ́ músulumi, iṣẹ́ ajé àwọn kò dí ẹsìn lọ́wọ́ nítori ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Lady Peller
Lady Peller fi kun pé, nínú àwọn ìdá ti àwọn máa n ṣe nígbà míran tí ọkọ́ òun yóò gé òun sí méjì nínú pòsí, kò sí èyí tí òun siyè méjì níbẹ̀ rí, nítorí pé òun mọ pé kò ni ṣe aburu fún òun.
" A máa n kó ara wa ni ìjánu gidi, nítori pé ǹkan ti à n ṣe amóhùmáwòrán lásán ni."
Ọjọ tí ǹkan fẹ́ yíwọ́ lórí ìtàgé
" Sùgbọ́n ní ọjọ́ kan, ǹkan ṣẹlẹ̀ ní Cultural Centre, mo nígbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn yóò ṣì rántí."
Gígé tí a ń gé ní ọjọ́ náà kìí ṣe fún amóhùmáwòrán, o gbóná gan ni lọ́jọ́ náà, mó lọ mi o le pada lọ́jọ́ ti a ń wí yìí, títí ti ètò náà fi pari.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Lady Peller
"Àwọn kan ni àwọn ò fẹ́ rí ǹkan kan míràn mọ́, wọ́n sì bínú lọ, lọ́jọ́ kejì, àwọn ènìyàn Lady Peller sa ni àwọn fẹ́ rí.
Kódà, àwọn kan tún ń gbé ìròyìn òfégè kiri pé ọkọ̀ tó pọ̀, ti wọ́n ń gbé òkú lọ sí ìlú Iseyin.
"Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, Professor Peller ku', idán ò kú o, Prof Peller ni ọmọ kan tó ń jẹ́ Zeeto Peller, agbẹjọrò ni, sùgbọ́n òun náà gbówọ́ nínú idán pípa.
Kò sí ẹni ti wọ́n fi dandan mú láti ṣe ohunkóhun, sùgbọ́n gbogbo ọmọ ti Peller fi sílẹ̀ ló ṣe dáadáa.
Báwo ni Professor Peller se kú gan?
Àwọn oníròyìn náà ló ta professor Peller, lásìkò ìfọ̀rọ̀wánillnuwo ló ti sọ̀rọ̀ jù, tí ọ̀pọ̀ awọn aṣírí si hàn síta.
Ó ní "lásìkò tí òun bá ń kírun, kò ni sí ǹkankan lára òun bí ààbò, pé sùgbọ́n tí òun bá ti kírun tán, tí òun wọ agbáda òun padà, bí wọ́n bá kòjú òun kò sí ǹkan ti wọ́n le ṣe si, ǹkan kan ko le ràn òun.
Sùgbọ́ǹ gẹ́gẹ́ bi músùlùmí, a mọ̀ pé àmúwa Ọlọrun ni gbogbo ǹkan ti o bá ṣẹlẹ̀ si ẹdá, sùgbọ́n, ẹnìkan tàbi èsù ni yóò lò."













