Nigeria road accident record in 2020: Èèyàn 1,076ni ìjàmbá mọ́tò ti sọ di olóògbé láti oṣù mẹ́ta sẹ́yìn ní Nàìjíríà- FRSC

Nigeria road accident record in 2020: Èèyàn 1,076ni ìjàmbá mọ́tò ti sọ di olóògbé láti oṣù mẹ́ta sẹ́yìn ní Nàìjíríà- FRSC

Oríṣun àwòrán, FRSC

Ajọ ẹṣọ oju popo ni Naijiria, The Federal Road Safety Corps, FRSC ti kede pe ijamba ọkọ 2,656 lo ti ṣẹlẹ loju popo Naijiria ni eyi to si ti fa iku awọn eeyan 1,076 laarin oṣu kẹta sẹyin.

Alanilọyẹ fun ajọ naa, ẹsọ CPEO Bisi Kazeem lo sọ eyi di mimọ ni ilu Abuja.

O ni ere asapjude lo ṣokunfa eyi to pọju ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ naa.

O tun ṣalaye pe awọn mọto 4, 494.

Bisi ni eeyan to le ni ẹgbẹrun mẹfa ati ẹẹdẹgbẹta ni wọn farapa ninu awọn ijamba ọkọ to waye naa.

Bisi Kazeem salaye pe awọn eeyan to din diẹ ni ẹgbẹrun meje ni ajọ ẹṣọ oju popo FRSC doola ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ kaakiri Naijiria

O parọwa fun awọn awakọ lati ṣọra nipa sisare asapajude loju popo nitori pe ẹmi ko ni aarọ rara.

O tun ni ki wọn maa gbera irinajo lasiko ki wọn ma baa maa fi oru rin lopopona

Bakan naa lo ni ki koowa maa ṣayẹwo ọkọ rẹ bi o ti yẹ ki o to gbera irinajo lasiko yii, ki wọn si maa tẹle ofin irnna loju popo lai sare ju bo ti yẹ lọ tabi lai ya ọkọ miran silẹ lọna aitọ.

Ni ipari o ni ki awọn awakọ maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ẹṣṣo aabo oju popo FRSC ki alaafia le jọba loju popo Naijiria.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà