Rahama Sadau blasphemy: Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn rèé nípa bóyá wọ́n dájọ́ ikú fún òṣeré Kannywood

Oríṣun àwòrán, George Okoro
Osere tiata Kannywood kan, Rahama Sadau ti figbe ta pe ko si ẹnikẹni to mu oun ati pe, ofege ni iroyin to gbode pe wọn ti dajọ iku fun un.
Sadau fi ikede yii sita loju opo rẹ ni Twitter rẹ nirọlẹ ọjọ iṣẹgun.
Ikede rẹ naa ko ṣẹyin bi iroyin ṣe gba ori ayelujara kan pe wọn ti gbe osere tiata naa lọ si ileẹjọ Sharia, ti wọn si dajọ iku fun tori pe o ṣatọna bi awọn kan ṣe sọrọ abuku si Anọbi Muhammad.
O ni ''Mi o mọ ibi ti iroyin yi ti wa. Mo si rọ awọn eeyan lati sinmi ahesọ ọrọ ti ko nidi."

Oríṣun àwòrán, Rahama Sadau
Lọsẹ to kọja ni Rahama ṣe alabapin awọn aworan rẹ kan to fara rẹ silẹ loju opo ayelujara.
Bi awọn eeyan kan si ṣe n gbosuba kare fun lori aworan yii, ni awọn miran n bẹnu atẹ lu.
Aworan naa da awuyewuye silẹ, tawọn eeyan kan si n sọrọ abuku si Anọbi Muhammad ninu ọrọ ti wọn kọ sabẹ aworan naa loju opo Twitter Rahama.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àgbààgbà Yorùbá kò fara mọ́ àbá gbígbógun ti ojú òpó ayélujára - Seyi Makinde
- Aṣaájú olùwọ́de EndSARS 50 dèrò iléẹ́jọ́ lórí ìfẹ̀hónúhàn àti ìdàlúrú
- Ìpínlẹ̀ mọ́kànla ni kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣàmúlò òfin tó dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé - Ìjọba àpapọ̀
- Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn ún he lórí ẹ̀sùn jìbìtì 668,000 náírà
- Ẹ̀yin obìnrin, ẹ jáde du ipò ààrẹ láti gbàjọba lẹ́yìn Buhari - Amina Muhammed
- Sina Jesu ní orúkọ́ mi báyìí, ń kò jẹ́ Shina Rambo mọ́ - Adigunjalè tẹ́lẹ̀ kìlọ̀
- Agbẹjọ́rò wọ́ ìjọba lọ sílé ẹjọ́ pé kó yọ kéú kúrò lára owó Náírà
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
Ko si ẹnikankan to mu mi:
Amọ bi awọn eeyan kan ṣe n pe Rahama Sadau lori ago nipa idajọ iku ti wọn gbọ pe wọn se fun, lo mu ko bọ si oju opo Twitter rẹ lati salaye pe wọn ko mu oun.
''Awọn ọlọpaa ko fiwe pe mi, bẹẹ si ni mi o gba iwe ipẹjọ kankan. Mo fẹ fi da awọn ololufẹ mi loju pe alaafia ni mo wa, ko si si ẹjọ kankan ti wọn fi kan mi''
''Fawọn to fẹ sọ ọrọ yii di bamii, ti o le mu wahala wa, mo bẹ yin, ẹ tọwọ ọmọ yin ba sọ''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O fi kun ọrọ rẹ pe ''asiko yi jẹ akoko inira fun mi. Kii ṣe igba yii lo yẹ ka tun maa tan iroyin ofege ka. Mo dupẹ lọwọ awọn to kan si mi''












