EndSARS Protest Update: Seun Kuti dá ẹgbẹ́ tí baba rẹ̀, Fela Kuti dá silẹ̀ ní ọdún 1979 padà

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ṣeun Kuti to jẹ ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja olorin, Fela Kuti ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko lati tako ifilọlẹ ẹgbẹ tuntun, Movement of the People ti wọn ṣe agbekalẹ rẹ.
Seun Kuti lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni Kalakuta Museun ni Ikẹja, nipinlẹ Eko sọ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni aṣẹ lati tako ifilọlẹ ẹgbẹ naa eyi to jẹ agbende ẹgbẹ yii kan naa ti baba rẹ gbe kalẹ nigba aye rẹ.
Seun ni ''oyinbo buruku ni wọn kọ sibẹ, ti kọmisọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko si buwọlu''.
Saaju asiko yii ni ikọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi atẹjade ranṣẹ si ẹgbọn Seun Kuti, Yeni wipe wọn yoo foju wina ofin ti wọn ba ṣe ipade kankan bii ti ifẹhọnuhan EndSars ni ile igbafẹ ''Fela Shrine'' naa.
- Ìjọba kò nì í fi àyè gba irú rògbòdìyàn #ENDSARS mọ́ - Mínísítà Ọlọ́pàá
- Ayọ̀ abara tíntín! Olorì Naomi àti Ooni Adimula Ile Ife kí Arẹmọ tuntun kúàbọ̀
- Ilé-ẹjọ́ yí ẹjọ́ DPO ọlọ́pàá tó ju télọ̀ sátìmọ́lé torí ó ba aṣọ rẹ̀ jẹ́ dànù
- Makinde loun ní ìbéèrè láti bi Ajimobi lórí aṣemáṣe iṣẹ́ àgbàṣe, ni kọmíṣọ́nà Ajimobi kan bá gbarata
Bakan naa ni aworan jade lori ayelujara nibi ti awọn ọlọpaa ti duro wamuwamu niwaju ile igbafẹ naa, ti wọn ko si gba ki ẹnikẹni wọle tabi jade.
Amọ, Seun Kuti ati ikọ rẹ lo agbegbe miran lati ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ, Movement of the People naa eleyii ti baba rẹ Fela Kuti gbe kalẹ ni ọdun 1979.

Fela Kuti gbe ẹgbẹ naa kalẹ lati dije dupo aarẹ orilẹede Naijiria, eleyii ti ijọba Naijiria nigba naa fofin de lati dije dupo ninu idibo to waye nigba naa.
Seun Kuti ninu ọrọ rẹ ni ẹgbẹ naa wa fun ominira awọn eniyan lorilẹede Naijiria.
''Mo fẹ fi daa yin loju pe ẹgbẹ Movement of the People ko ni doju ti awọn ọmọ Naijiria nitori yoo wa fun awọn araalu ni.
Afojusun wa ni ki awọn owọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria gbaruku ti ẹgbẹ naa, ki wọn si ja fun ominira orilẹede Naijiria.
''A gbọdọ ṣiṣẹ papo pẹlu awọn araalu lati rii wi pe ko si ẹnikẹni to gbẹyin ninu ijijagbara naa''
Seun Kuti ni gbogbo ẹgbẹ to n ja fun ominira orilẹede Naijiria lo gbọdọ parapọ bii ti igba ti Naijiria gba ominira ni ọdun 1960 lati tun ṣiṣẹ pọ fun ominira orilẹede Naijiria.
Òkò gbọnin lórí ìjọba àpápọ̀ tórí pé ó pe àwọn olùwọ́de EndSARS ní agbésùnmọ̀mí
Awọn agbaagba ogbontagi agbẹjọro ni Naijiria, awọn ẹgbẹ, at'awọn eekan ilu, ti bẹnu atẹ lu bi ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria ti pe awọn oluwọde EndSARS ni agbesunmọmi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn sọ oko ọrọ si ijọba lori bi banki apapọ orilẹ-ede Naijiria, CBN ti gbe gbe apo ikowosi awọn oluwọde EndSARS ti pa.
Ijọba apapọ lo banki CBN lati ti apo ikowosi ogun eeyan ninu awọn oluwọde EndSARS, lori ẹsun pe owo to wa ninu apo ikowosi naa le wa fun igbesunmọmi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ gbà mí o! Ìjọba Buhari ní kí Ológun pa mí láàrin ọjọ́ kan péré - Omoyele Sowore
- Bí nǹkan bá ṣe mí àtàwọn ọmọ mi, Aláàfin ni kẹ mú o - Olorì Anu figbe ta
- Ọ̀pọ̀ òkú fọ́nkálẹ̀ nílé ìwòsàn ìjọba ní Ore, ìpayà àjàkálẹ̀ àrùn gbàlú kan
- Ìpinu Gómínà láti dẹ́kun owó ìfẹ̀yìntì fáwọ̀n Gọ́mìnà àná dùn mọ́mi- Bola Ahmed Tinubu
- Ọkùnrin tó ṣe òfegè fọ́nran àwòrán ìgbéyàwó Buhari pẹ̀lú Mínísítà d'èrò ilé ẹjọ́
- Ṣé lóòtọ́ ni olorì méjì míì tún ti kúrò láàfin Oyo?
- Sọ́jà nà mí, tí mí mọ́lé bí wọn ti ṣe fún bàbá mi láyé ìjọba ológun Buhari - Ọmọ́ Busari Adelakun
Ẹgbẹ àwọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA ni igbesẹ fihan pe ijọba to wa lode ko lootọọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Alukoro ẹgbẹ NBA, Ọmọwe Raps Nduka sọ pe, iwọde EndSARS wa ni ibamu pẹlu ofin orile-ede Naijiria, bakan naa lo ni ohun ti wọn n beere lọwọ ijọba t'ọna.
Agbẹjọro Nduka ni gbigbẹsẹ le apo ikowosi awọn oluwọde EndSARS fihan pe, arumọjẹ lasan ni ileri ti ijọba ṣe lati wa ojutu si iwa ifiyajẹni awọn ọlọpaa tawọn oluwọde fẹ dopin.
Ninu ọrọ tiẹ, agbẹjọro agba, Mike Ozekhome(SAN) ni pipe awọn oluwọde EndSARS ni agbesunmọmi lodi sofin.
Ozekhome to bẹnu atẹ lu igbesẹ banki CBN lati ti apo ikowosi awọn oluwọde EndSARS pa ni, awọn ọmọ Naijiria ni ẹtọ labẹ ofin lati ṣe ifẹhonuhan.
Ozekhome ni gbogbo ọgbọn tí ijọba n da ni lati dunkoko mawọn igbimọ to n ṣewadi iwa ifiyajẹni awọn ọlọpaa lawọn ipinlẹ kan.
Ninu ọrọ tiẹ, agbẹjọro to tun jẹ ajafẹtọ, Jiti Ogunye ni banki apapọ Naijiria, CBN fẹ sọ ara rẹ di oniyẹyẹ, pẹlu igbesẹ lati ti apo ikowosi awọn oluwọde EndSARS pa.
Ogunye ni ile ifowopamọ ijọba ni CBN ṣe, kii ṣe ẹṣọ eto alaabo ni Naijiria."
Ẹ̀yin obìnrin, ẹ jáde du ipò ààrẹ láti gbàjọba lẹ́yìn Buhari - Amina Muhammed

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Igbakeji akọwe agba fajọ iṣọkan agbaye, UNO, Arabinrin Amina Mohammed ti sọ pe, o ṣeeṣe ki obinrin jẹ aarẹ orilẹ-ede Naijiria lẹyin Aarẹ Muhammadu Buhari ba pari ijọba rẹ.
Arabinrin Mohammed wa rọ awọn obinrin ni Naijiria lati gba ipo aṣiwaju aarẹ ilẹ Naijiria lọdun 2023.
Mohammed to ṣiwaju igbimọ awọn oṣiṣẹ agba ajọ UNO to n ṣabẹwo si Naijiria sọrọ yii niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sina Jesu ní orúkọ́ mi báyìí, ń kò jẹ́ Shina Rambo mọ́ - Adigunjalè tẹ́lẹ̀ kìlọ̀
- Agbẹjọ́rò wọ́ ìjọba lọ sílé ẹjọ́ pé kó yọ kéú kúrò lára owó Náírà
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára tó dájú fún ìdènà àrùn Coronavirus ti jáde
- Wàhálà míì dé! Nupeng àti Pengassan gùnlé ìyanṣẹ́lódì
- Ààrẹ Mali tẹ́lẹ̀, Amadou Toumani Toure jáde láyé
- Làásìgbò ọ̀tun súyọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC
- Afurasí afipábánilópọ̀ kàgbákò, obìnrin tó jà lólè fi eyín gé nǹkan ọkùnrin rẹ̀ jábọ́ lásìkò ‘Blow Job’
Arabinrin Mohammed sọ pe, awọn obinrin to le gori aleefa gẹgẹ bi aarẹ orilẹ-ede Naijiria wa daadaa.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Amina J. Mohammed
"Asiko ti to fawọn obinrin lati dide nitori wọn ko idaji ninu awọn oludibo."
"Ohun to ku fawọn obinrin ni lati ni atilẹyin awọn ọkunrin ni Naijiria," Mohammed lo sọ bẹẹ.
Igbakeji akọwe agba ajọ UNO ni ko si idi kan to le ni ki obinrin maa jẹ aarẹ Naijiria.
Lakotan, o ni awọn ọmọ orileede Naijiria gbọdọ fọwọ s'ọwọ pọ lati tun Naijiria ṣe lai fi ti ẹya tabi ọrọ oṣelu ṣe.
"Gbogbo wa lo ni ojuṣe lati ṣe, idi niyii ti a fi gbọdọ ṣiṣẹ pọ fun igbega orileede Naijiria," Mohammed lo woye bẹẹ.
Bí ọwọ́jà ìjọba mi kò bá tíì dọ́dọ̀ yín, ẹ ṣe sùúrù pẹ̀lú wa- Ààré Buhari bẹ̀bẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahmad
Aarẹ Muhammadu Buhari ti rawọn ẹbẹ si awọn ọmọ Naijiria pe ti wọn ko ti ri ipa ijọba wi pe ki wọn ṣe suuru pẹlu oun.
Bakan naa ni Buhari bẹ awọn ti wọn gbagbọ pe ijọba to wa lode ko gbiyanju to pe ki wọn maa fi ṣe ibinu.
Minisita eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed lo gbẹnu aarẹ sọrọ yii nibi ipade to waye ni gbongan kan niluu Ilorin pẹlu awọn olori ijọba, awọn ọdọ, akẹkọọ, oṣiṣẹ, awọn iyalọja atawọn tọrọ kan lori rogbodiyan iwọde EndSARS.
Nigba ti o n jiṣẹ aarẹ Buhari nibi ipade naa, minisita eto iroyin ati aṣa sọ pe ''ijọba to wa lode mu ọrọ awọn ọdọ atawọn araalu lọkunkundun.
Ọgbẹni Mohammed ṣalaye pe ifẹ awọn ọdọ to wa lọkan ijọba Buhari lo jẹ ki o maa ṣe ọpọ eto ti yoo ṣe awọn ọdọ lanfaani.
''Ṣugbọn bi ijọba wa ko ba tii ni ipa lori gbogbo araalu, ẹ gba bẹẹ pẹlu wa,'' Mohammed lo ṣo bẹẹ,
Minisita ni ijọba Buhari ko ri owo to pọ na lati fi ṣe ijọba bii awọn ijọba to ti wa ṣaaju.
Ọgbẹni Mohammed tun sọ pe ajakalẹ arun coronavirus ṣakoba nla fun ijọba ati gbogbo eeyan, o ni Naijiria n ṣẹṣẹ n bọ lọwọ ipa to buru ti covid-19 ni lori ọrọ aje ni.
''Ẹbẹ ni a n bẹ wi pe ki ẹ ni suuru ki ẹ si ran ijọba lọwọ,'' Minisita eto iroyin lo sọrọ yii.
O ni ijọba Buhari gbe miliọnu marunlelaadọrin kalẹ lati ṣe iranwọ fawọn ọdọ lẹnu iṣẹ wọn.
Minisita eto iroyin ati aṣa ni ẹgbẹẹgberun un awọn ọdọ ni wọn ti jẹ anfaani oniruuru eto bi N-POWER, N-TECH, N-AGRO ati MSMEs labẹ ijọba Buhari.
Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrazaq Abdulrahman, Emir Ilorin, Alhaji Sulu Gambari atawọn leekan leekan mii lo wa nibi ipade ọhun.
- 'Èmi Oluwatoyin Abosede Aya Kolawole Ajeyemi ń sọ fún yín pé mo ti dé "bus stop" sinimá lọ́dún yìí'
- Remilekun Fatolu bú sẹ́kún fún ohun tó ti pàdánù láyé torí ọyàn ńla rẹ̀.
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nínú oṣù Kẹ́wàá ọdún 2020
- Wo ìgbà márùn ún tí Buhari ti rìnrin àjò lọ sókè òkun fún ìtọ́jú ara rẹ̀















