Ajimobi School: Makinde ní Ajimobi, àwọn tó ṣàkóso iṣẹ́ àgbàṣe iléèwé Oba Akinbiyi lẹ́jọ́ láti jẹ́; Olowofela, kọmíṣọ́nà Ajimobi ní kí Makinde ó tẹlẹ̀ jẹ́jẹ́

Oloogbe Abiọla Ajimọbi pẹlu Ṣeyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Ajimobi/twitter

Laipẹ yii ni gomina ipinlẹ Ọyọ paṣẹ iwadii lori bi wọn ṣe fa iwe iṣẹ agbaṣe oni irinwo miliọnu naira fun kikọ ileewe girama igbalode Oba Akinbiyi to wa lagbegbe Ọrẹmeji ni ilu Ibadan ya.

Ni ọjọ Aje ni gomina Makinde pa aṣẹ yin lẹyin abẹwo rẹ si ileewe naa nibi ti iroyin sọ pe o ti ri awọn ariwisi ti ko ṣe fi oju fo da.

Àkọlé fídíò, Bí o bá bá ààrùn ìpẹ́pẹ́ gbígbẹ lára arẹwà obìnrin rẹ̀, kí loó ṣe?

Gomina Makinde ṣalaye pe lai ti ju ọdun kan lọ, ogiri, atawọn ohun ẹṣọ iwọlẹ taili ti wọn lo ti n dibajẹ pẹlu afikun pe ko daju pe wọn kọ ile naa bi o ti ṣe yẹ ni ibamu pẹlu ilana to tọna fun kikọ ile.

O ni orukọ ileewe naa gan ti wọn kọ sori patako ti n ṣi danu.

O ni awọn eeyan to wa nidi ikọle naa nigba naa yoo dahun ibeere lori idi ti wọn fi kọkọ fa iwe iṣẹ naa ya lọwọ kọngila ti wọn gbe fun, bakan naa lo ni wọn yoo tun dahun ibeere loribi wọn ṣe gbe iṣẹ naa fun eto oju awo lawo fi ngbọbẹ, direct labour pẹlu irinwo miliọnu naira ti o si tun jẹ pe iṣẹkiṣẹ ni wọn ṣe.

Àkọlé fídíò, 'Mo ní àṣírí ìyá tó fẹ́ ọmọ rẹ̀ láya fún Boko Haram torí ẹbí rẹ̀'

Amọṣa ọkan lara awọn kọmiṣọna ni iṣejọba gomina Ajimọbi nigba naa, Ọjọgbọn Olowofẹla ti ke si Makinde pe ko fi oloogbe Ajimọbi lọrun silẹ ko si lalafia.

Olowofẹla to jẹ kọmiṣọna feto ẹkọ nigba naa ṣalaye pe igba ti iṣẹ naa n falẹ lọwọ agbaṣẹṣe ti wọn gbe e fun to si han gbangba pe agbaṣẹṣe naa ko lagbara iṣẹ ti wọn gbe fun un naa ni gomina paṣẹ ki wọn gba iṣẹ agbaṣe naa kuro lọwọ rẹ ki wọn gbee fun ileeṣẹ ijọba to n mojuto iṣẹ ode lati pari.

O ni o yẹ ki Makinde o yẹ gbogbo iwe akọsilẹ nipa iṣẹ naa wo ko to bẹrẹ si ni sọ ọrọ alufansa si oloogbe Ajimọbi to jẹ gomina nigba ti wọn ṣe iṣẹ akanṣe naa.