Lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ Pfizer kéde abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ni epo bẹntiróò gbówó lórí - Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, @NewsDigestNG
Minisita to n ri si ọrọ epo bẹntiro, Timipre Sylva, ti sọ pe aṣeyọri ileeṣẹ to n po oogun, Pfizer, lati pese abẹrẹ ajẹsara Covid-19 lo fa ọwọngogo epo ni Naijiria.
Sylva lo sọ ọrọ naa nigba to n ṣe ipade idakọnkọ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari niluu Abuja.
O ni kete ti ileeṣẹ Pfizer kede pe oun ti ṣe abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni owo epo bẹntiro gbowolori kaakiri agbaye.
- Iléejọ́ ti gba béèlì olùwọ́de EndSARS Eremosele Adene àmọ́...
- Àwọn agbébọn tí jí àwọn ọmọ fásitì Zaria mẹ́jọ ní òpópónà Abuja sí Kaduna - Gomina El- Rufai
- Àwọn ọmọ Naijiria kó owó wọn kúrò ní Access Bank lẹ́yìn tó gbẹ́sẹ̀lé àpò owó àwọn olùwọ́de EndSARS
- Wo ìdí tí wọ́n fi ta ẹyẹlé kan ṣoṣo ní ₦893,000,000
- Èèyàn 157 míràn ló tún lùgbàdì Coronavirus ní Nàìjíríà
Minisita ọhun ni "ohun to ṣẹlẹ laipẹ yii ni ikede abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ti ileeṣẹ to n po oogun, Pfizer ṣe, lẹyin naa ni owo epo lọ soke."
Sylva ṣalaye pe "ti ẹ ba mọ bo ṣe n lọ nipa ti iye owo ti wọn n ta epo rọbi, ẹ o rii pe lẹyin ti Pfizer ṣe ikede rẹ ni owo eopo ọhun gbera."

Oríṣun àwòrán, @247NNU
"Nitori naa, ti owo opo rọbi ba lọ soke, o di dandan ki owo epo bẹntiro naa lọ soke."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni iye owo epo rọbi ni yoo sọ iye owo ti wọn yoo maa ta epo bẹntiro.
Minisita naa ṣalaye pe kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba yoo tupẹrẹpẹrẹ iru nnkan bayii ti owo epo ba ti gbowolori.
O ni owo epo rọbi lo maa n fa ọwọngogo ọpọ nnkan niroti kii duro soju kan.
Sylva pari ọrọ rẹ pe idi ree ti ijọba apapọ kii ṣe fi owo epo bẹntiro sojukan nitori iye owo ti wọn ta epo rọbi ni yoo sọ iye ti wọn yoo maa ta epo bẹntiro.
















