Latest ASUU strike update: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ASUU tí gbà láti fòpin sí ìyanṣẹ́lódí lẹ́yìn tí ìjọba gbà látí sàn N70bn

Awọn akẹkọọ fasiti

Oríṣun àwòrán, Facebook/ASUU

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ASUU ti gba lati fopin si iyanṣẹlodi ti wọn ti gunlẹ lati oṣu mẹjọ sẹyin .

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ASUU naa ṣepade pẹlu ijọba apapọ ti Minisita fun ọ̀rọ iṣẹ ati oṣiṣẹ, Chris Ngige n ṣe adari fun.

Lara awọn nkan ti ASUU ati ijọba apapọ jọ ni adehun le lori ni owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ, owo oṣu awọn oṣiṣẹ, ọrọ awọn ile iwe fasiti ni awọn ipinlẹ ati apo owo iṣuna IPPIS ti wọn kọ lati gbawọle, ti wọn si fi apo iṣuna UTAS pari rẹ.

Lẹyin ipade wakati mẹjọ, Chris Ngige ni o da oun loju wi pe ọna abayọ ti waye ninu ijiroro wọn, ti wọn yoo si fopin si iyanṣẹlodi wọn laipẹ.

Ngige ni gbogbo nkan ti ASUU bere lọwọ wọn ni awọn ti ṣe amọ ẹgbẹ naa nilo lati ba awọn ọmọ ẹgbẹ wọn sọrọ lori abajade ipade wọn.

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi

Kilo ṣẹlẹ laarin ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU ati ijọba apapọ?

Oṣu mẹjọ sẹyin ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU ati ijọba apapọ ti n fori gbari ti wọn si ti gunle iyanṣẹlodi tako igbesẹ ijọba lori asunwọn apo owo IPPIS.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU kọkọ bẹrẹ iyanṣẹlodi ni Ọjọ Kẹsan an, Oṣu Kẹta, ọdun 2020 lẹyin ti ijọba ni awọn ko ni san owo oṣu fun awọn olukọ ti ko ba darapọ mọ aṣunwọn owo Integrated Personnel and Payroll Information System (IPPIS).

Àkọlé fídíò, Àṣírí tú! Ikọ̀ ìwádìí BBC ṣí àwọn tó ń jí ìkókó gbé sí gbangba

ASUU ni asunwọn owo naa ko le ṣiṣẹ fun awọn nitori bi ileewe giga ṣe n ṣe akoso ara wọn, amọ awọn le gbẹ ajọ University Transparency Accountability Solutions (UTAS) silẹ ti yoo si rọpọ IPPIS ọhun.

Nibayii, ijọba ti gba lati san iye owo to to biliọnu aadọrin naira lati fi san owo oṣu awọn oṣiṣẹ ati owo ajẹmọnu wọn.

Amọ, ẹgbẹ ASUU ti ni awọn yoo kan si awọn ọmọ ẹgbẹ wọn yoku lati jiroro lori igbesẹ ijọba ati lati kede ọjọ ti awọn yoo pada si ẹnu iṣẹ.

Ìgbà tí ẹgbẹ́ ASUU ní òun yóò tó fi òpin sí ìyanṣẹ́lódì rèé

Alaga Ẹgbẹ olukọni Fasiti ni Naijiria, ASUU, nipinlẹ Eko, Ọmọwe Dele Ashiru sọ pe oun ko gbọ nipa ipade ti ijọba apapọ sọ pe oun yoo ṣe ni ọsẹ yii pẹlu awọn olukọ.

Ọmọwe Ashiru sọ pe iyansẹlodi si n lọ lọwọ, nitori pe awọn ko tii yanjú ọrọ pẹlu ijọba apapọ.

O sọ eyi gẹgẹ bi esi si ikede ti ijọba apapọ Naijiria fi sita pe oun yoo ṣepade pẹlu ẹgbẹ ASUU ni ọsẹ yii lati yanju nkan to mu ki ẹgbẹ naa wa ni iyansẹlodi fun ọpọlọpọ oṣu.

Ninu ifọrọwanilẹnu kan to ṣe pẹlu ileesẹ iroyin Channels, Minisita fun eto igbani sisẹ ati ọrọ awọn oṣiṣẹ, Ọmọwe Chris Ngige fidi rẹ mulẹ pe ijiroro yoo bẹrẹ pada pẹlu awọn olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ agba ni fasiti, SSANU ati awọn alasẹ eto ẹkọ lati yanju ọrọ to wa laarin ijọba ati ẹgbẹ ASUU.

Ọmọwe Ngige ni oun ni ireti oun ni pe wọn o ri ọrọ naa yanjú ni ọsẹ yii , ti eto ẹkọ yoo si bẹrẹ pada ni awọn Fasiti.

Bakan naa lo sọ pe ijọba apapọ ń ṣe awọn ipade miran labẹnu, nibi ti wọn ti ṣe akọsilẹ awọn nkan pataki ti yoo yanju ọrọ naa.

Ilana imọ ẹ̀rọ tuntun ti ijọba fẹ ẹ ma fi san owo osu awọn olukọ naa (Integrated Payroll and Personal Information System, IPPIS) lo fa iyansẹlodi tí ASUU gunle.

Aarẹ ẹgbẹ ASUU, Biodun Ogunyemi sọ pe inira ni ilana tuntun naa yoo mu ba awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ.

O ṣalaye pe ileesẹ to n mojuto imọ ẹ̀rọ IPPIS ma n yọ lara owo oṣu awọn.

O ni ilana ti awọn Fasiti ṣe funra wọn, iyẹn 'University Transparency and Accountability Solutions', ni awọn ọmọ ẹgbẹ fẹ ẹ fi ma a gba owó oṣu wọn.

"Ti ijọba ba ti faramọ nkan ti a fẹ́, awa naa ṣetan lati pada si ẹnu isẹ wa."

Oṣu Kẹta, ọdun 2020, ni ẹgbẹ ASUU ti bẹrẹ iyansẹlodi.

Ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ fásítì, ẹ múra sílẹ̀ fún ìwọlé lẹ́yìn ìyanṣẹ́lódì oṣù méje - ASUU

Ko si ohun to ni ibẹrẹ ti ko lopin. O dabi ẹni pe iyanṣẹlodi ti ẹgbẹ olukọ fasiti, ASUU ti gunle fun oṣu meje bayii ti fẹ wa si opin.

Ajọ ASUU lo sọ fawọn akẹkọọ fasiti ijọba apapọ loju opo Twitter rẹ lati gbaradi fun iwọle pada sile iwe wọn.

Ajọ ASUU sọ pe o yẹ ki iroyin ayọ le jade ni Ọjọru ọsẹ yii nigba ti wọn ba tun ṣepade ipẹlu ijọba.

Ni ọjọ Aje, ọjọ kẹsan oṣu kọkanla ọdun 2020 ni ẹgbẹ ASUU ṣe ipade pẹlu ijọba apapọ nibi ti wọn gba lati foju diẹ lara ohun ti wọn n beere fun lọwọ ijọba han.

Nibi ipade ọhun naa ni wọn ti gbe ilana sisan owo oṣu lawọn fasiti yẹwo, iyẹn UTAS yatọ si IPPIS ti ijọba gbe kalẹ.

Minisita ọrọ iṣẹ ati igbaniṣiṣẹ, Dokita Chris Ngige sọ lọjọ Ẹti to lọ pe oun yoo tun ṣe ipade mii pẹlu ẹgbẹ ASUU lọsẹ yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ngige ni oun ni igbagbọ ipade naa yoo so eso rere nitori awọn yoo lanfani lati wa ojutuu si gbogbo ohun to ku diẹ kaato ti ASUU n fẹ atunṣe lori rẹ.

Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹta ọdun 2020 ni ASUU bẹrẹ iyanṣẹlodi lẹyin ti wọn sọ pe ijọba ko mu ileri adehun ti o ni pẹlu ẹgbẹ naa lọdun 2019 ṣẹ.

Ilana sisan owo oṣu awọn olukọ fasiti pẹlu ilana IPPIS naa jẹ ọkan lara ohun ti ẹgbẹ ASUU ko faramọ.