UK Parliament on Nigeria: Geoffrey Onyeama ni aṣofin UK kò lágbára láti sọ̀rọ̀ lórúkọ ìjọba UK

Oríṣun àwòrán, @Geoffrey
Minista fun ọrọ ilẹ okeere ni Naijiria, Geoffrey Onyeama ti fesi pada fun awọn aṣofin United Kingdom pada lori ọrọ idajọ ifiyajẹni lasiko iwọde EndSars ni Naijiria.
Geoffrey Onyeama dahun si ibeere lori ọrọ idajọ awọn aṣofin UK lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Abuja to jẹ olu ilu Naijiria ni ọjọru.
O ni: " A ti kàn si awọn ijọba UK lori ọrọ yii, ohun ti mo ro ni pe ipade naa jẹ ti awọn aṣofin UK ni kii ṣe agbẹnusọ ti ijọba.
Awa naa si ti n ba wọn fikunlukun, a ti ṣalaye ipa ti ijọba Naijiria ko lori iwọde #EndSars naa fun awọn to yẹ ninu ijọba UK pẹlu ohun to ṣẹlẹ ni pato".
Onyeama ni ohunkohun to ba wu aṣofin kọọkan lo le fi ẹnu ara rẹ sọ nigba to ba wu u ṣugbọn kii ṣe lati sọ ero ara rẹ lorukọ ijọba UK.
O ni ohun to ṣe pataki ni lati rii pe idajọ ti ijọba ba fẹ ṣe ko ṣegbe fẹnikan tabi fi sibi ti ko yẹ ko fi si.
Ati pe, o di dandan fun ijọba Naijiria lati pese awọn ohun eelo iwadii lori bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ gangan fun awọn to yẹ ninu ijọba ki wọn to gbe igbesẹ kankan.
Ọrọ yii n waye lẹyin ti awọn Asofin UK jiroro lori ijiya to yẹ fun ẹnikẹni ni ijọba tabi ninu awọn agbofinro ti ade iwa ibajẹ ohun ti iwadii ba fihan pe o ṣẹlẹ ninu iwọde #EndSars loṣu kẹwaa, ọdun yii ba ṣi mọ lori ni Naijiria.
Theresa Villers, okan ninu awọn aṣofin ni UK lo fi to awọn to ku rẹ leti pe awọn eeyan 220, 330 lo ti buwọlu iwe ẹsun naa ni eyi to fun wọn ni aṣẹ lati gbe e yẹwo.
Wọn ni ki ijọba UK ronu igbesẹ to yẹ ni gbigbe lati fiya jẹ awọn alaṣẹ Naijiria to ba tapa si ẹtọ ọmọniyan lasiko iwọde naa ni Naijiria.
- Àwọn olóṣèlú, àti àwọn Ọba n gbàbọ̀dè fún ìpínlẹ̀ Ekiti lórí ọ̀rọ̀ àwọn tó n fi ipá bánilòpọ̀- Kọmísọ́nnà ètò ìdájọ́
- Ọmọbìnrin tó tayọ nínú ìdànwó WAEC ọdún 2019 pẹ̀lú A1 méje ti kú
- Ohun mẹ́wàá pàtàkì nípa Maradona àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ẹlẹ́sẹ̀ ayò Diego Costa rèé
- Ganiyat tó fi irin gbígbóná àti àdá ya ara ọmọ àbúrò ọkọ rẹ ti dèrò àgọ́ ọlọ́pàá l' Ogun
- Wo dókítà ọmọ Nàìjíríà tí àgbáyé ń wárí fún nítorí abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19
Ilé aṣòfin orílẹ̀-èdè UK n gbèrò fífí ìyà jẹ àwọn adarí Naijiria tó lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn ENDSARS
Àwọn aṣòfin UK ṣetán láti fìyà jẹ àwọn adarí Naijiria tó lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn ENDSARS
Ile aṣofin ilẹ Gẹẹsi, ti n jiroro lori iwe ipẹjọ kan ti wọn si n gbero lati fiya jẹ awọn alaṣẹ Naijiria to ba lọwọ ninu ipaniyan ENDSARS.
Ọjọ Aje ni ile aṣofin naa fẹnuko ninu idibo pe ijiya yoo wa fun awọn olori ijọba to lọwọ ninu lilo ipa lori awọn oluwọde alaafia naa, ni ogunjọ, oṣu Kẹwaa.

Wọn ni fifi iya jẹ orilẹ-ede Naijiria lapapọ yoo pa awọn ọmọ Naijiria lara. Nitori naa ni wọn ṣe fẹ ki ijọba wadii awọn to lọwọ si iṣẹlẹ naa.
Awọn ọmọ ile aṣofin naa tun koro oju si iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari, fun bo ṣe n kọlu awọn to kopa ninu iwọde ENDSARS, to tun n dẹruba wọn.
Idibo naa waye, nitori iwe ẹsun kan ti awọn ọmọ Naijiria to le ni ẹgbẹrun lọna igba (220,000) fi ọwọ si
Awọn aṣofin naa n fẹ ki ijọba United Kingdom ṣe iwadii awọn ẹsun aṣilo agbara, ati awọn olori ijọba ni Naijiria to lọwọ si ipaniyan to waye ni Lekki nipinlẹ Eko.
Bakan naa ni wọn koro oju si ijọba ṣe gbẹsẹ le apo asunwọn awọn oluwọde naa.
Wọn tun jiroro lori ipa ti UK n ko ninu eto ẹkọṣẹ ati tita nakn ijagun fun ileeṣẹ alaabo Naijiria.
Ijiya to ṣe e ṣe ko waye fun awọn alakoso ijọba ati eleto aabo, ni fifi ofin de irinajo wọn silẹ okeere, ati gbigbẹsẹ le dukia wọn.
- A dúro bí iké lẹ́yìn ìròyìn táa gbé jáde nípa Lekki Tollgate; CNN tako Lai Mohammed
- Ìjọba Naijiria faraya nínú lẹ́tà tó kọ sí CNN lórí ìwádìí rẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Toll Gate
- Wo àwọn ayédèrú ìròyìn tó gbà'gboro kan lásìkò ìwọ́de #EndSARS
- Báyìí ni olùwọ́de EndSARS, Eremosele Adene ṣe gba òmìnira lọ́wọ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà
- Pásítọ̀ Sam Adeyemi, Taaooma, Falz àti gbogbo àwọn tí ilé ẹjọ́ fẹ́ rí nìyìí

Oríṣun àwòrán, @Falz
Ijọba Naijiria ko ti i fi igba kan sọ pe lootọ ni awọn eleto aabo yinbọn mọ awọn oluwọde naa.
Ọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ọdun 2020, ni ijọba orilẹ-ede United Kingdom, ti fesi si iwe ẹsun ti awọn ọmọ Naijiria kọ si.
Awọn eeyan naa n fẹ́ ki ajọ commonwealth fiya to tọ si ẹni to ba tapa si ẹtọ ọmọniyan, jẹ awọn adari Naijiria.
Ile aṣofin United Kingdom si fesi pe rogbodiyan to waye lasiko iwọde ENDSARS kọ oun lomiinu.
Ati pe oun n duro de abajade iwadii ijọba Naijiria lori ẹsun ifiyajẹni ti wọn fi kan awọn ọlọpaa.



















