Nigeria government - Lekki Toll Gate - Kí ló wà ninú lẹ́tà tí ìjọba Naijiria kọ sí CNN

Oríṣun àwòrán, Twitter/cnn/bashirahmad
Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti kọ lẹta si ileeṣẹ iroyin CNN, lati tun iwadii ṣe lori iṣẹlẹ ipaniyan to waye ni Lekki toll gate, nipinlẹ Eko.
Ninu lẹta naa ti wọn kọ si Igbakeji Aarẹ ẹka ibanisọrọ ni CNN, Ọgbẹni Jonathan Hawkins lo sọ pe:
"A kọ lẹta yii lati fihan pe ẹbu ni iwadii ti ileeṣẹ amohunmaworan CNN sọ pe oun ṣe, to si fi sita fun aye ri lọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2020.
Iwadii naa to ni oun ṣe lori lori bi awọn eleto aabo Naijiria ṣe dana ibọn mọ awọn oluwọde ti ko dihamọra ogun ni Lekki Toll Gate nipinlẹ Eko, lasiko iwọde #ENDSARS, ko ba igbelewọn iṣẹ iroyin mu.
- A dúro bí iké lẹ́yìn ìròyìn táa gbé jáde nípa Lekki Tollgate; CNN tako Lai Mohammed
- Báyìí ni olùwọ́de EndSARS, Eremosele Adene ṣe gba òmìnira lọ́wọ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà
- Ṣé Sanwo-Olu, gómìnà Eko yóò farahàn níwájí ìgbìmọ̀ olùwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate?
- Òtítọ́ làwọn sọ́jà gbé ìbọn tó lọ́ta gidi nínú lọ sí Lekki Toll Gate lásìkò ìwọ́de EndSARS- Ọ̀gágun Taiwo
O si tun satilẹhin fun ayederu iroyin to ti n lọ tẹlẹ nipa iṣẹlẹ naa.
Ati pe iṣẹ iroyin jati-jati ni ileeṣẹ iroyin agbaye yii ṣe."
Bakan naa ni lẹta naa tun kilọ fun CNN pe Naijiria ni ẹtọ lati gbe igbesẹ labẹ ofin, lati di ileeṣẹ iroyin lọwọ ko ma ba a dakun wahala END SARS.
Kilo tun wa ninu lẹta naa?
- Ijọba sọ pe iroyin naa ko tẹle ilana to gbe iṣẹ iroyin duro - aiṣegbe ati fifun igun kọọkan ni anfaani kan naa lati sọrọ
- Ijọba tun fi ẹsun kan CNN pe o sare gbe iru iroyin bẹ ẹ jade, lai gbọ ọrọ lẹnu ijsba nipa rẹ.
- Yatọ si eyi, ijọba Naijiria tun sọ pe awọn fidio to wa lori ayelujara idọrẹpọ 'social media', ni CNN ṣa jọ, eyi to lewu.
- Wọn tun ni ọrọ ẹnu DJ Switch ni CNN n gbagbọ, eyi to jẹ pe o ti yipada lọpọ igba.
- Ijọba fikun pe CNN ko sọ nkankan nipa rogbodiyan to tẹle iwọde END SARS, ti awọn ọlọpaa kan ti padanu ẹmi wọn.















