Lekki Tollgate shooting: Fídíò táa ní lọ́wọ́ kò ṣàfihàn gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ náà - LCC
Oludari ileeṣẹ to n ṣakoso Lekki Tollgate, Lekki Concession Company ni fọnran ti awọn ni lọwọ nipa ohun gbogbo to ṣẹlẹ nigba ti wọn fẹsun kan pe awọn sọja yinbọn lu awọn afẹhonuhan to n ṣewọde EndSARS ni ogunjọ oṣu kẹwa ọdun 2020 ko ka gbogbo nkan to ṣẹlẹ nirọlẹ ọjọ naa silẹ.
Oludari ileeṣẹ naa, Abayomi Omomuwasan toun naa farahan niwaju igbimọ aṣedajọ ipinlẹ Eko lori awọn iṣẹlẹ pataki to waye lọjọ Aje fi apoti kan han igbimọ naa eyi to ni ẹrọ ayaworan CCTV wa ninu rẹ to ya fidio gbogbo nkan to ṣẹlẹ ni Lekki Tollgate lọjọ ti wọn yinbọn. Ṣugbọn o ṣalaye pe fidio naa to n wo gbogbo ohun to nṣẹlẹ dede duro ni dede ago mẹjọ alẹ eyi si ni dedee akoko ti iroyin sọ pe ibọn yinyin bẹrẹ.
O ni idi ti kamẹra naa fi dakẹ iṣẹ ni pe tori irinṣẹ ti wọn so o mọ ti ni iṣoro nibikan.
Wọn ko tilẹ fi fọnran naa han igbimọ tabi araalu loni ti wọn mu u lọ siwaju igbimọ lẹyin ọrọ ti wọn sọ.
Bakan naa, Abayomi ni fidio naa ko ni ọrọ labẹ tori awọn kan fi n wo igbokegbodo ọkọ ni...
Ọrọ ti pọ bayii lori fidio to wa lori ọrọ ẹrọ ayaworan CCTV gẹgẹ bi iroyin ṣe n fo kiri pe wọn mọọmọ yọ ẹrọ ayaworan ọhun kuro ni Tollgate ṣaaju akoko ti wọn bẹrẹ si ni yinbọn ni.
Nigba to n fesi si ibeere, oludari ileeṣẹ naa gba pe wọn yọ ẹrọ ayaworan kuro eyi ti wọn n lo lati fi mọ awọn ọkọ to kọja laarọ ọjọ iṣẹlẹ ibọn yinyin naa.
- Àwọn àkọ́lé ìròyìn mẹ́ta tó leè tẹ̀lẹ́ ìdìbò Ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika
- US Election 2020: Nígbà wo laó mọ èsì ìdìbò àti pé ṣé ó ṣeé figagbága?
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, tó ń kojú Trump nínú ìbò America
- Mọ̀ sí i nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́sàn-án tó ń díje nínú ìdìbò ilẹ America lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun
- US Election 2020: Ṣé èsì ìdìbò Ààrẹ Amẹrika yóò jáde lálẹ́ ọjọ́ ìdìbò?
Ọgbẹni Omomuwasan ba sọ fun awọn araa igbimọ ọhun pe ki ẹrọ ayaworan naa ṣi wa lọwọ ile ẹjọ.
Ẹwẹ, nipa ti ina ti wọn ni o dede ku ni Lekki Tollgate, o ni ko sẹni to pa ina. O ni ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn oṣiṣẹ awọn ni ko tan ina naa silẹ ki wọn to lọ sile nitori konileogbele to wa lode nipinlẹ Eko eyi ti ijọba Eko kede lọjọ iṣẹlẹ yii gangan.
Tani àwọn ọ̀dọ́ méjì tí yóò darapọ́ mọ́ igbimọ́ iwadii iṣẹlẹ́ Lekki ní Eko?
Lẹyin ifikunluku ati idibo lori ayelujara, agbarijọpọ ẹgbẹ ajafẹtọ ti forukọ ọdọ meji ranṣẹ ni Eko lati jẹ ọmọ igbimọ iwadii to n tọ pipin iṣẹlẹ ikọlu to waye ni Lekki.

Oríṣun àwòrán, Twitter/TemiOanu
Lara iṣẹ igbimọ yi ni ki wọn ṣe akojọ ẹsun, fi ọrọ wa awọn eeyan lẹnu wo ki wọn si tun fi idi ododo mulẹ lori ifiyajẹni tabi ipaniyan.
Orukọ awọn meji ti wọn yan yi ni Rinu Oduala ati Majekodunmi Oluwaseun.

Oríṣun àwòrán, falzthebahdguy
Ṣaaju ki a to bẹrẹ si ni gbe iroyin igbẹjọ igbimọ yii, a ni ki a se atupalẹ iroyin nipa awọn ti wọn yan lati ṣoju ọdọ ati iru akitiyan wọn to mu ki ipo yi tọ si wọn.
Rinu Oduala
Bi ẹ ba ti n fọkan ba iwọde ENDSARS bọ, yoo ṣoro ki ẹ to ma da arabinrin yi mọ ninu awọn oluwọde ni ipinlẹ Eko.
Oduala Olorunrinu kii ṣe ẹni to ga pupọ ṣugbọn bi eeyan ba foju di i, yoo kan idin ninu iyọ.
Ajafẹtọmọniyan yi to lewaju paapa ni ile ijọba ni Eko wa lara awọn to kọkọ gbe igba iwọde ki awọn gbajumọ mii to wa darapọ mọ wọn.

Oríṣun àwòrán, @SavvyRinu
Rinu jẹ akikanju ti ko fi igba kankan tura silẹ lori ṣiṣe deede laarin ijọba ati ara ilu.
Akọṣẹmọṣẹ ni o jẹ nipa biba eeyan polowo ọja loju ayelujara ti a si tun maa da si ọrọ to ni ṣe pẹlu mimu irọrun ba ara ilu.

Oríṣun àwòrán, Twitter/TemiOanu
Loju opo rẹ ni Twitter ati Instagram, orisirisi aworan lo wa nibẹ lawọn ibi to ti n kopa ninu iwọde.
Lasiko ti wọn bẹrẹ si ni ro wipe o yẹ ki awọn oluwọde ni aṣoju, o wa lara awọn ti wọn dibo yan lori ayelujara ki o to wa pada laanfaani ati jẹ ọmọ igbimọ iwadii.
Majekodunmi Temitope Oluwaseun
Arakunrin yi ni ẹnikeji ti wọn yan lati ṣoju awọn ọdọ ninu igbimọ iwadii nipinlẹ Eko.
Bii ti Rinuola, Temitope naa jẹ ọdọ ti o mu jijafẹtọmọniyan ni ọkunkundun.

Oríṣun àwòrán, Twitter/TemiOanu
Loju opo rẹ ni Twitter, o fi ọrọ idupẹ imoore awọn to yan sipo gẹgẹ bi aṣoju ọdọ.
O gba ladura pe ki awọn maa ṣe ja ireti awọn to yan wọn sipo kulẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Kini awọn ọdọ sọ nipa iyansipo yi?
Loju opo Twitter niṣe lawọn ọdọ n fi ọrọ iwuri ranṣẹ si awọn aṣoju wọnyi.
Ninu awọn to fi ọrọ adura ati iwuri ranṣẹ ni ilumọọka gbajumọ nii Falz ati awọn mii wa to ni ki awọn aṣoju yi ma gbabọde.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Ijoko igbimọ yi yoo maa waye ni gbogbo ọjọ Iṣẹgun,ọjọ Ẹti ati ọjọ Abamẹta ni ile ẹjọ apẹtusaawọ ipinlẹ Eko to wa ni 1A, Remi Olowude Street, Maruwa Roundabout, Lekki.
Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọrọ nipa igbimọ yi to si ni ''oun wa lẹyin igbimọ naa bi ike''
Aarẹ sọ pe oun ni gbagbọ pe igbimọ yi yoo jẹ ki awọn oluwọde ati ọlọpaa to padanu ẹmi wọn ri idajọ ododo gba.












