Ekiti rape: Ẹni ọdún 51 fipá bá ọmọ ọdún 12 lòpọ̀, ìjọba ìpínlẹ Ekiti lẹ awòrán rẹ̀ gbangba sí àárín ìlú

Afipabanilopo

Oríṣun àwòrán, Google

Ara aato ti wọn la kalẹ lati fopin si iwa ifipabanilopọ lawujọ, ijọba ipinlẹ Ekiti ti ti lẹ orukọ arakunrin kan si oju gbangba ti wọn gbamu pe o fipa ba eeyan lopọ.

Arakunrin naa, Ajayi Peter ẹni ọdun mọkanlelaadọta to jẹ ọmọ ilu Itapa Ekiti ti gba idajọ ẹwọn gbere ni ile ẹjọ giga ilu Ado Ekiti fun pe o fipa ba ọmọbinrin ọmọ ọdun mejila lo pọ.

Ajayi Peter

Oríṣun àwòrán, Google

Gẹgẹ bi ọrọ tó jade lati ọfiisi agbẹjọro agba ipinlẹ EKiti, bi wọn ṣe fi orukọ ati didoju ti ni ni gbangba wa ni itẹsiwaju ipinu ijọba lati ma faye gba iwa ifipabanilopọ mọ ni ipinlẹ naa.

Bakan naa, atẹjade ọhun fihan pe labẹ akoso afikun igbesẹ ti agbẹjọro agba naa tun gbe jade, wọn yoo tun lẹ orukọ ati aworan awọn afipabanilopọ ti ofin ba gbamu si adirẹsi ile ti wọn ba mọ wọn mọ ati ni ibi to ba gbajumọ daadaa ladugbo ibi ti ẹni to ṣe aṣemaṣe yii n gbe.