Use of hijab: Ìjọba ti buwọ́lu lílo hijab láwọn iléèwé ní ìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin atotonu fun ọpọlọpọ ọdun, ijọba ipinlẹ Osun ti fọwọ si kawọn akẹkọọbinrin maa lo hijab nipinlẹ naa.
Ijọba ṣe okede ọhun ninu atẹjade kan ti arabinrin C. K. Olaniyan, to jẹ oludari agba ni ẹka eto ẹkọ ipinlẹ Osun fi sita lẹyin ti ọrọ naa ti wa nile ẹjọ fun ọjọ pipẹ.
Ijọba ṣalaye pe bi o tilẹ jẹ pe ijọba ti fọwọ lilo hijab lawọn ileewe, kii ṣe dandan fun awọn akẹkọọ maa wọ papaa julọ awọn akẹkọọ ti kii ṣe ẹlẹsin musulumi.
- A ó ṣèrànwọ́ fáwọn ẹbí ọlọ́pàá tó bá rògbòdìyàn EndSARS lọ láti inú N500m tí a yà sọ́tọ̀- Makinde
- Kàyééfì! Tọkọ taya kú lọ́jọ́ kan náà l'Abeokuta lẹ́yìn ìgbéyàwó ọdún méjìléláàdọ́rin 72
- Remilekun Fatolu bú sẹ́kún fún ohun tó ti pàdánù láyé torí ọyàn ńla rẹ̀.
- Èèyàn mọ́kànléláádọta ló wá láti ìpínlẹ̀ Eko nínú èèyàn 72 tó kó ààrùn covid-19 lọ́jọ́ Ajé
- 'Ṣọ́ọ́ṣì ni mọ ti ń bọ̀ kí n tó pàdé àwọn sójà tó fi abẹ gẹ irun fún mi'
Ti ẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrinla oṣu keji ọdun 2013 ni ẹgbẹ musulumi nipinlẹ Osun gbe ijọba ipinlẹ naa lọ si ileẹjọ pe ki ijọba faye gbawọn akẹkọọ to jẹ musulumi lati maa wọ hijab nile iwe.
Ọrọ naa si ti fẹ da aawọ silẹ lawọn ileewe to jẹ ti ijọba nipinlẹ Osun.
Ijọba rọ awọn alaṣẹ ileewe ijọba lati maa kọ eti ikun si aṣẹ ileẹjọ lori lilo hijab, bi bẹẹ kọọ, aigbọran si ileẹjọ ni irufẹ iwa bẹẹ yoo jẹ.
Atẹjade naa ṣalaye pe ijọba ko ni ṣe ohun kan to tako ipinlẹ naa gẹgẹ bi ipinlẹ to wa fun gbogbo araalu lai fi ti ẹsin kankan ṣe.
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Mọ̀ sí i nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́sàn-án tó ń díje nínú ìdìbò ilẹ America lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun
- Ẹ dẹ̀kun lílo Sniper àti Dichlorvos fún ìtọ́jú oúnjẹ- NAFDAC kìlọ̀
- Wo ọ̀nà àbáyọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àjọ WAEC gbẹ́sẹ̀ lé èsì ìdánwò wọn
- ''Àjọ NERC ti fún Disco láṣẹ láti padà sí owó tàríìfù tuntun iná mọ̀nàmọ́ná''
- EFCC bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn ìwà jẹgúdújẹrá tí wọ́n fi kan Fowler tó jẹ́ Alága iléeṣẹ́ FIRS tẹ́lẹ̀













