US presidential election 2020: Esther Agbaje, Oye Owolewa àti Nnamdi Chukwuocha jáwé olúborí nínú ìdìbò Amẹrika

Oríṣun àwòrán, owolewa/Chukwuocha/Agbaje
Awọn ọmọ Naijiria mẹta, to tun jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika ti jaweolubori ninu idibo to n lọ lọwọ lorilẹ-ede ọhun.
Awọn ọmọ Naijiria naa ni; Esther Agbaje, Oye Owolewa ati Nnamdi Chukwuocha.
Esther Agbaje lo dije lati ṣoju ẹkun 59B ni Minnesota, iyẹn nile igbimọ aṣoju-ṣofin labẹ asia ẹgbẹ Democratic, to si ni ibo 17,396.
Ẹni ọdun marundinlogoji na fi ẹyin Alan Shilepsky gbolẹ, eyii to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican, ati Lisa-Delgado ti Green Party.

Oríṣun àwòrán, @go4esther
Agbaje to kawe gbowe ninu ẹkọ imọ ofin lati fasiti Harvad jẹ ọkan pataki lara awọn ọmọ Naijiria mẹsan an to n kopa ninu eto idibo ọhun.
Ṣaaju akoko yii, Agbaje ti kọkọ ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ijọba ilẹ Amẹrika, US State Department, bẹẹ lo tun ṣiṣẹ nileesẹ awọn amofin kan lẹyin to kọkọ kẹkọọ gboye ni Fasiti Pennsylvania.
Esther Agbaje ni ọmọ Naijiria akọkọ tii yo jẹ ọmọ ile aṣoju-ṣofin ni Minnesota.
Ọmọ Naijiria miran to bori nin ninu idibo ọdun 2020 ni Nnamdi Chukwuocha ti wọn dibo yan lati ṣoju ẹkun kinni ti ipinlẹ Deleware nile igbimọ aṣoju.
Gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ Democrat ti ko ni alatako kankan, Chukwuocha bori ninu idibo ọhun pẹlu ibo 7,640.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ yan Chukwuocha lati ṣoju ẹkun kinni ni ile igbimọ aṣoju Deleware lọdun 2018.
Chukwuocha kẹkọọ nipa itan ni fasiti ipinlẹ Deleware, o si ni iriri nipa eto oṣe abẹle ipinlẹ ọhun.
Ọmọ naijiria kẹta ti yoo di ipo oṣelu mu l'Amẹrika bayii ni Oye Owolewa.
Owolewa gbegba oroke ninu odibo naa lẹyin to fi ẹyin awọn alatako rẹ, Joyce Robinson-Paul ati Sohaer Syed gbolẹ.
Owolewa ni ibo 164,026, nigba ti Robinson-Paul ni ibo 18,600, ti Syed si ni 15,372.
Ọmọ Naijiria ọhun kẹkọọ gboye Ọmọwe ni Northeastern University, iyẹn ni ilu Boston.
Oun ni ọmọ Naijiria akọkọ ninu iwe itan ti yoo di ipo yii mu ni agbegbe Colombia.
- Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin he lẹ́yìn tó jí ẹ̀rọ ìléwọ́ iPhone ní ìpínlẹ̀ Ogun
- Ẹ fún wa lówó oṣù wa tàbí kí a gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ- Àwọn dokita ìpínlẹ̀ Ondo
- Coronavirus gbẹ̀mí èèyàn mẹ́rin lánàá Ọjọ́rú ní Nàìjíríà, èèyàn márùndínlọ́gọ́jọ 155 míì tún kóo
- Wo àfipábánilòpọ̀ ẹni ọdún 51 tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti tú làṣirí ní gbangba

Oríṣun àwòrán, Instagram/oye4dc
Owolewa jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bìi ọmọ Naijiria àkọ́kọ́ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin Amẹrika
Ọmọ Naijiria to n dije lati ṣoju ẹkun Colombia nilẹ Amẹrika, Oye Owolewa, ti jawe olubori ninu idibo to n lọ lọwọ.
Owolewa gbegba oroke ninu odibo naa lẹyin to fi ẹyin awọn alatako rẹ, Joyce Robinson-Paul ati Sohaer Syed gbolẹ.
Owolewa ni ibo 164,026, nigba ti Robinson-Paul ni ibo 18,600, ti Syed si ni 15,372.
- A ti gbé ìwádìí dìde lórí ìpànìyàn tó wáyé lásìkò ìwọ́de EndSARS- Ilé ẹjọ́ àgbáyé, ICC
- A kó ní sanwó oṣú ASUU láìjẹ́ pé wọ́n gba IPPIS- Ìjọba Àpapọ̀
- Oṣú mẹ́fà ni òṣìṣẹ́ ìjọba tó bá bímọ yóò máa lò nílé kó tó wọṣẹ́ padà- Seyi Makinde
- DPO ọlọ́pàá ju télọ̀ sátìmọ́lé, gbé e lọ sílé ẹjọ́ n'Ibadan torí ''ó ba aṣọ rẹ̀ jẹ́''

Oríṣun àwòrán, Instagram/oye4dc
Ninu atẹjade to fi soju opo Instagram rẹ, Owolewa sọ pe "mo fẹ fi akoko yii dupẹ lọwọ gbogbo awọn ẹbi ati ọre mi lagbegbe Colombia."
"Nitori akitiyan ati ifarajin yin ni mo ṣe di ọmọ Naijiria akọkọ ti yoo di asojuṣofin nilẹ Amẹrika."

Oríṣun àwòrán, Instagram/oye4dc
Ipinlẹ Kwara ni baba Owolewa ti wa, ti iya rẹ si jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Oyo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Lẹyin ti iroyin jade pe Owolewa ti bori ninu idibo ọhun, ọpọ awọn ololufẹ rẹ kaakiri Naijiria ati loke okun lo ti bẹrẹ si n kii ku ori ire lori itakun agbaye.
Lara awọn to ti bẹrẹ si n kii ni ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ naijiria nilẹ okeere, NIDCOM.

Oríṣun àwòrán, @Nations
Wo awọn ọmọ Yorùbá méje, tó ń dupò nínú ìdìbò ilẹ̀ America
Mọ̀ sí i nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́sàn-án tó ń díje nínú ìdìbò ilẹ America lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Ko din ni ọmọ orilẹ-ede Naijiria mẹsan an to n dije ninu idibo gbogboogbo ti yoo waye nilẹ America lọjọ Iṣẹgun.
Pupọ ninu wọn lo n dije lati inu ẹgbẹ oṣelu Democrat, wọn si n du ipo ninu ijọba apapọ, ipinlẹ, ati ni agbegbe.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Yatọ si idibo aarẹ, idibo gomina yoo waye nipinlẹ mọkanla, ati ẹkùn meji.
Bakan naa ni idibo sile aṣofin yoo waye, fun gbogbo ijoko ile 435 nile igbimọ asoju-sofin, marundinlogoji ninu ọgọrun un yoo si waye nile aṣofin agba.
Awọn ọmọ Naijiria to n dije:
Ni ipele ijọba apapọ,
1) Ọgbẹni Oye Owolewa:
Ẹni yii ti baba rẹ jẹ ọmọ ipinlẹ Kwara, ati ti iya rẹ wa lati ipinlẹ Oyo, n du ipo (ti ko nilo ibo) sile igbimọ asoju-sofin
Onimọ nipa oogun oyinbo ṣíṣe ni Owolewa, o si ni iwe ẹri Ph.D lati Fasiti Northeastern, ni Boston.
O n dije lati ṣoju Ẹkùn Colombia, labẹ ẹgbẹ oṣelu Democrat.
Jija fun owo oṣu to dọ́gba fun gbogbo oṣiṣẹ nilẹ America, ni afojusun rẹ.
Ti wọn ba fi le yan-an, ẹni ọgbọn ọdun ọhun ni yoo jẹ ọmọ Naijiria akọkọ nile aṣofin ilẹ America.
- England kéde ìséde ọ̀sẹ́ mẹ́rin míràn láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ Covid 19
- Ènìyàn méjì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Abúlé Ẹ̀gbá, ní ìpínlẹ̀ Eko
- Ta ni Wolii Olapade Agoro tó re ibi àgbà ń rè tí ayé ń pariwo rẹ̀ yìí?
- Ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu Adelé Ọba Alade Idanre ló rí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín òun àti Ọba Aroloye
2) Ọgbẹni Yomi Faparusi:
Ẹlomiran to tun n dije fun ipo ninu ijọba apapọ ni Ọgbẹni Yomi Faparusi.
Ọmọ ipinlẹ Ekiti ni, sugbọn ilu Ibadan ni wọn bi i si.Oludije to da duro ni lai si ẹgbẹ oṣelu kankan.
O si fẹ ẹ ṣoju ipinlẹ Tennessee nile aṣofin agba lorilẹ-ede America.
Faparusi kekọọ gboye ninu iṣẹ iṣegun oyinbo, ni Fasiti ilu Ibadan nibitri sanmọnti gbe dun ile ti wọn tun ni ọgba ẹlẹranko.
Bakan naa lo gba Ph.D, lati Fasiti Johns Hopkins, ati imọ nipa ofin, Widener University, ni Delaware.
Kii ṣe igba akọkọ niyi to dije fun ipo ile aṣofin ni America.
O gbiyanju lati gba tikẹẹti ẹgbẹ oṣelu Republican fun ile igbimọ asoju-sofin, lọdun 2014 ati 2016, sugbọn o fidi rẹmi nigba mejeeji.
Ohun to jẹ Faparusi logun ni lati jẹ "ohùn rere" fun gbogbo ọmọ Naijiria ati ilẹ Africa, to ba fẹ ẹ dije fun ipo oṣelu lorilẹ-ede naa.
- Ǹkan tí a mọ̀ nípa kọ́lẹ̀jì olùdìbò tó ń fìdì ẹni ti yóò jẹ ààrẹ ilẹ̀ Amérika múlẹ̀
- Aàbò tó péye yóò wà fún àwọn tí yóò kópa nínú ìfẹsẹwọ̀nsẹ̀ Naijiria àti Sierra Leone ní Benin - Obaseki
- Wo iye owó tí ìjọba Amẹrika ń na sí ìdìbò Ààrẹ àti ibi tí owó náà ti ń wá
- Oluwo ti ìlú Iwó kìí ṣe ẹgbẹ́ Àtaọjà Osogbo - Alaafin ìlú Ọ̀yọ́
3) Yinka FaletiNi Missouri:
Ọgbẹni Yinka Faleti, to jẹ ọmọ ipinlẹ Eko, naa n dije lati inu ẹgbẹ oṣelu Democrat, bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu Republican lo n dari nibẹ.
Ipo Akọwe Ijọba Apapọ lo n dije fun.Akọsilẹ lori ayelujara Wikipedia sọ pe, Faleti, jẹ sọja nileesẹ ọmọ ogun ilẹ America, laarin ọdun 1998 si 2004.
Orilẹ-ede Kuwait lo ti sisẹ.Ẹni ọdun mẹrinlelogoji ọhun, ni iwe ẹri lati Ileewe ikọsẹ ologun ilẹ America, ni West Point.
O si tun kekọọ gboye ninu imọ ofin ni Fasiti Washington.Afojusun rẹ gẹgẹ bi oloṣelu ni lati ri i daju pe awọn ti wọn ba dibo yan n tẹti si awọn to dibo yan wọn.
4) Paul Akinjo
Ọgbẹni Paul Akinjo, lati ipinlẹ Ondo, n dije fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ California, lati ṣoju ẹkun idibo kejila.
Akinjo ti fi igba kan jẹ igbakeji Mayor ilu Latherop, o si tun sisẹ gẹgẹ bi ọmọ ologun ilẹ America, laarin ọdun 1982 si 1989.
Ọrọ ile gbigbe, eto irinna, ati ọrọ awọn asatipo lo jẹ ẹ logun.
5) Adewumi Kuforiji:
Ni Delaware, Adewumi Kuforiji n dije fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ, lati ṣoju ẹkun idibo kẹrinlelọgbọn.
Ọmọ ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo ni Kuforiji
O gba iwe ẹri ninu imọ isiro, ati iwe ẹri imọ ijinlẹ kejì ninu imọ amojuto okoowo,lati Fasiti ipinlẹ Delaware.
O dije fun ipo yii kan naa lọdun 2018, sugbọn ẹni to wa nipo naa, Lyndon Yearick, ti ẹgbẹ oṣelu Republican, fi ẹyin rẹ janlẹ .Àwọn mejeeji lo tun jọ n dije lọjọ Iṣẹgun.
6) Esther Agbaje:
Ni ipinlẹ Minnesota, Arabinrin Esther Agbaje, naa n dije fun ile igbimọ aṣofin, lati ṣoju ẹkun idibo 59B.
Ẹgbẹ oṣelu Minnesota Democratic Farmer-Labour Party, to jẹ isọmọgbe ẹgbẹ Democrat, lo ti fẹ ẹ dupo.
Ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni awọn obi rẹ, sugbọn wọn ti di ọmọ ilẹ America.
O n dije fun ipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ, lẹyin to fi ẹyin Raymond Dehn, to ti n ṣoju ẹgbẹ naa fun ọjọ pipẹ, janlẹ l'oṣu Kẹjọ.
Agbaje ni iwe ẹri nipa imọ ofin, lati Fasiti Harvard. Iwe ẹri imọ ijinlẹ kejì lati Fasiti Pennsylvania.
Bakan naa lo sisẹ nile isẹ ijọba ọtẹlẹmuyẹ ilẹ America.
- Atiku banújẹ́ sí ìròyìn pé Amẹ́ríkà dínà mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà
- Wo ìdí tí orílẹ̀-èdè America ṣe tako ìyànsípò Okonjo-Iweala gẹ́gẹ́ bi olórí ajọ WTO
- Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America
- Ẹ wo Daniel tí wọ́n fẹ́ yẹgi fún lẹ́yìn tí US kò ṣe irú ẹ̀ fún odidi ọdún 17
7) April Ademiluyi: Ngozi Akubuike, ati Benjamin Osamenam, naa n dije.
Ẹni ọdun mọkandinlogoji ni Ademiluyi.
O si n dije fun ipo Adajọ nile ẹjọ Seventh Circuit, ni ijọba ibilẹ Prince George, ni Maryland.
Akubuike ni ti ẹ, to jẹ amofin, jẹ oludije to da duro, fun ipo adájọ nile ẹjọ Minnesota 2nd District.
Orilẹ-ede Naijiria ni Akubuike ti kekọọ imọ ofin, o si sisẹ nile ifowopamọ, ko to o ko lọ silẹ America.
Nibẹ lo si tun ti kekọọ imọ ofin ni ileewe imọ ofin, Mitchell Hamline.
O ti sisẹ gẹgẹ bi amofin fún ipinlẹ Minnesota. Ọdun 1982 ni Osamenam, de si ilẹ America.
O si n dije fun ipo aṣofin nijọba ibilẹ Brooklyn City Council ni Minnesota.
Onimọ ẹ̀rọ lo jẹ, ni ileesẹ eto irinna ipinlẹ naa.Labẹ ẹgbẹ oṣelu National Party, lo si ti n dije.
O ti fi igba kan jẹ Aarẹ ẹgbẹ awọn onimọ ẹ̀rọ, to jẹ ọmọ Naijiria, ni Minnesota.




















