A ó ò dasẹ́ sílẹ̀ fún ojọ́ gbọọrọ tí ìjọba bá kọ̀ láti san owó oṣù mẹ́rin tó jẹ wa- Àwọn dokita ìpínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Western Post
Ẹgbẹ awọn dokita ipinlẹ Ondo ti bu ẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ naa lori bo ṣe maa n fi iya owo oṣu jẹ wọn nigba de igba.
Abẹnugan fun awọn dokita naa ni fasiti ẹkọṣẹ iṣẹgun ipinlẹ Ondo, UNIMEDTH, Olagbe Taiwo Paul sọ fun BBC Yoruba pe, ijọba atawọn alaṣẹ fasiti ọhun kọ lati mu gbogbo ileri ti wọn ṣe fun awọn ṣẹ.
Ṣaaju ni awọn dokita ọhun ti kọkọ gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹta lati fa ijọba leti lẹyin ti wọn ni o jẹ wọn lowo oṣu mẹrin.
Awọn dokita naa korajọ, wọn si ṣe ifẹhonuhan niwaju ọọfisi adari UNIMEDTH ni ilu Akure, ti wọn si n bii eredi ti ijọba yoo ṣe jẹ wọn lowo oṣu mẹrin.
Olagbe sọ pe "Ko rọrun fun wa lati maa ṣiṣẹ ninu ebi lai si owo oṣu."
O ni wọn maa n ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ, ṣugbọn ijọba n ba ojuṣe rẹ ku to ba ti to asiko lati san owo oṣu fun wọn.
- Èmi kọ́ ló pàṣẹ fún àwọn sọ́jà láti má a pa èèyàn ní Oyigbo - Nyesom Wike
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Kàyééfì! Tọkọ taya kú lọ́jọ́ kan náà l'Abeokuta lẹ́yìn ìgbéyàwó ọdún méjìléláàdọ́rin 72
- Kíní ọ̀nà àbáyọ sí ìjàmbá ọkọ̀ tó ń wáyé lemọ́lemọ́ ní Ọjà Akungba,ní Ondo?
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "ko si owo oṣu ti a gba ri lẹnu iṣẹ yii ayafi ti ba kọkọ pariwo."
Dokita naa tẹsiwaju pe "nigba ti a ba n ṣiṣẹ wa ko si ẹni to maa n fipa mu wa, ṣugbọn ko bojumu ki a maa ba ijọba ja ki a to ri owo oṣu wa gba."
O ni lara ibere ẹgbẹ awọn dokita ọhun ni pe ijọba maa san owo oṣu wọn papọ pẹlu awọn oṣiṣẹ to ku.
Botkilẹ jẹ pe o ni ti ijọba ṣeleri fun wọn lati maa ṣe bẹẹ, ṣugbọn ko si iyatọ kankan ti wọn ri lẹyin ti wọn ti gọ ọpọlọpẹ iwe ẹdun.
O pari ọrọ rẹ pe ki ijọba san owo oṣu wọn, ko si tun ṣe eto bi owo oṣu wọn yoo fi maa lọ dede laisi idiwọ.
Ẹwẹ, nigba ti BBC Yoruba kan si kọmiṣọnna fun eto iroyin ni ipinlẹ Ondo, Donald Ojogo, o ni "a ti yanju ohun ti wọn n bere fun."
Lẹyin naa lo ni ki a kan si kọmiṣọnna fun eto ilera, iyẹn Ajibayo Adeyeye, ṣugbọn gbogbo akitiyan wa lati kan si kọmiṣonna ọhun lo ja si pabo.
















