Australia: Igbe ayekòótọ́ sàànfàní, ó kó olówó rẹ̀ yọ lọ́wọ́ ikú gbígbóná

Oríṣun àwòrán, NATIONAL GEOGRAPHIC SOCIETY
Arakunrin ọmọ Australia kan ti f'orin ọpẹ bẹnu lẹyin ti ayekootọ rẹ ko yọ lọwọ ina to sadede ṣeyọ nile rẹ laarin oru.
Bi kii ba ṣe ti ariwo ẹiyẹ rẹ yi to ta ji loju orun,o ṣeeṣe ki o jona mọ ile ti eeyan kankan ko si ni mọ.
Asunfọnfọn ni Anton Nguyen n sun lọwọ nile alaja-meji rẹ ni Brisbane, Queensland lasiko ti ina sadede ṣeyọ loru Ọjọru.

Oríṣun àwòrán, Google
O sọ fun ileesẹ iroyin ABC pe " sadede ni mo gbọ ariwo kan ti ayekootọ mi, Eric, si bẹrẹ si ni pariwo. Bi mo ṣe ji ni yẹn ti mo ṣi n gbọ oorun eefin to pọ"
O ni "kia ni mo gbe Eric,ti mo fẹ gba ọna eyinkule sa jade ṣugbọn mo ri ti ina n jọ nibe ti mo ṣi gba isalẹ ile mi sa jade"
Nigba t'awọn panapana yoo fi de ni nkan bi ago kan oru, ina ti gba gbogbo ile kan.
Wakati kan gbako ni ikọ panapana mẹrin fi wọ'ya ija pelu ina ọhun ki wọn to rẹyin rẹ ni agbegbe Kangaroo Point.
Arakunrin Nguyen, to n da gbele sọ pe lẹyin apamọwọ kekere kan ati ẹiyẹ oun ti ori ko yọ, awọn ko farapa botilewu ko kere mọ.
Ọga ileesẹ panapana Queensland Cameron Thomas ni niṣe ni ayekootọ naa n lọgun "Anton" titi ti olowo rẹ fi taji loju oorun.
"Ilẹ naa ni awọn ẹrọ to n tani lolobo ti eefin ba ṣeyọ nile ṣugbọn ayekootọ naa lo kọkọ figbe ta"
Iwadii n lọ lọwọ lati mọ ohun to fa ina yi titi di bi a se n ko iroyin yi jọ.
Kàyééfì! Tọkọ taya kú lọ́jọ́ kan náà l'Abeokuta lẹ́yìn ìgbéyàwó ọdún méjìléláàdọ́rin 72
Kayeefi nla ṣẹlẹ niluu Abeokuta tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ogun ni ọgbọnjọ oṣu kẹwaa ọdun 2020.
Kayeefi ọhun ni pe ọkọ ati aya rẹ, Pa Israel Akojede ati Mama Esther jẹ Ọlọrun nipe lọjọ kan naa laarin wakati diẹ si ara wọn lẹyin ti wọn ti jọ gbe gẹgẹ bi lọkọlaya fun ọdun mejilelaadọrin.

Oríṣun àwòrán, Pinterest
Pa Akojede ku ni bi ago mẹta oru ọjọ Ẹti, lẹyin naa ni aya rẹ papoda nigba to gbọ iku ọkọ rẹ lẹyin wakati diẹ.
- Remilekun Fatolu bú sẹ́kún fún ohun tó ti pàdánù láyé torí ọyàn ńla rẹ̀.
- Èèyàn mọ́kànléláádọta ló wá láti ìpínlẹ̀ Eko nínú èèyàn 72 tó kó ààrùn covid-19 lọ́jọ́ Ajé
- 'Ṣọ́ọ́ṣì ni mọ ti ń bọ̀ kí n tó pàdé àwọn sójà tó fi abẹ gẹ irun fún mi'
- EndSARS, EndSWAT Protests: Òbí agbábọ́ọ̀lù Kazim Tiamiyu Kaka àtàwọn míì tí ọlọ́pàá pa sọ̀rọ̀, omijé bọ́ lójú
- ''Àjọ NERC ti fún Disco láṣẹ láti padà sí owó tàríìfù tuntun iná mọ̀nàmọ́ná''
- Ẹ dẹ̀kun lílo Sniper àti Dichlorvos fún ìtọ́jú oúnjẹ- NAFDAC kìlọ̀
Ẹni ọdun mẹtalelọgọrun un ni Pa Akojede ti o gbe ni agbegbe Gbonagun Obantoko ṣe nigba ti aya rẹ jẹ ẹni ọdun mejidinlọgọrun un ki ọlọjọ to de.
Ọgbẹni Joseph Akojede to jẹ akọbi wọn lọkunrin ṣalaye pe iyalẹnu ni iṣẹlẹ naa jẹ fun gbogbo ẹbi.
Ọgbẹni Akojede ohun ti awọn n ro tẹlẹ nipe iku awọn mejeeji ko le jina sira wọn nitori bi ṣe fi ifẹ ba ara wọn lo.
''Lati igba ti mo ti wa ni kekere ni mo ti maa n ṣe akiyesi baba ati mama mi, ifẹ to wa laarin wọn pọju, ko si ẹni to le ya wọn,'' Ọgbẹni Akojede lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Akojede ni ''aṣọ kan naa ni wọn jọ maa n wọ, ohun kan naa ni wọn jọ gbagbọ, bakan naa ni wọn maa n gbamọran lọwọ ara wọn.''
O ni oun ko ri ibi ti wọn maa n jara wọn niyan ri, ''mama mi maa sọ pe ohun ti ọkọ oun ba ti sọ ni abẹ ge.''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olanrewaju Akojede to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ọmọ oloogbe sọ pe iku awọn mejeeji dabi ere ori itage awọn gbajugbaja ololufẹ meji, ''Romeo and Juliet'' ti wọn fẹ ara wọn bi oju.
Olanrewaju ni o jẹ iyalẹnu fun oun pe ẹrọ ibaraẹnisọrọ kan naa lawọn mejeeji jọ lo pọ.
- Ǹkan tí a mọ̀ nípa kọ́lẹ̀jì olùdìbò tó ń fìdì ẹni ti yóò jẹ ààrẹ ilẹ̀ Amérika múlẹ̀
- Wo iye owó tí ìjọba Amẹrika ń na sí ìdìbò Ààrẹ àti ibi tí owó náà ti ń wá
- Mọ̀ sí i nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́sàn-án tó ń díje nínú ìdìbò ilẹ America lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun
- US Election 2020: Ṣé èsì ìdìbò Ààrẹ Amẹrika yóò jáde lálẹ́ ọjọ́ ìdìbò?

















