Big breast: Oluwaremilekun Fatolu: Mo máa ń wọ kọ́mú “size 50H", ẹyọkan leè tó N15,000, Okrika N9,000

Àkọlé fídíò, Kété tí wọ́n bá ti báa yín sùn tàn torí pé ẹ tóbi, ẹ gbà pé ìfẹ́ yẹn ti parí - Auntie Remi Ọlọ́yàn ńlá

"Ti wọn ba ti debẹ tan. a wa di pe ẹyin lẹ ma maa wa wọn kiri to dẹ jẹ pe awọn lo n lee yin kiri nigba ti wọn o tii debẹ".

Auntie Remmie Ọlọyan nla sọ iriri rẹ gẹgẹ bi ẹni ti ọyan tobi gan ati ohun toju rẹ maa n ri pẹlu awọn ọkunrin.

Remilekun

Oṣere ni Oluwaremilekun Faith Fatolu ṣugbọn ti awọn ololufẹ rẹ maa n pe ni Auntie Remi.

Gbogbo ile itaja kọmu lorilẹede Naijiria lo ti kan si ti wọn o ni iwọn ọmu rẹ lori igba ti wọn a si ṣeleri fun un pe awn a kan si ti awọn ba ti ni.

Ṣugbọn Remilekun ni ko si eyi to kan pada si oun ri. Tori naa afi ko ra a lati ilu Oyinbo nipasẹ awọn ọrẹ rẹ.

Remilekun

Oríṣun àwòrán, Remi Fatolu

Remi Fatolu

Oríṣun àwòrán, Remi Fatolu

Produced By Yemisi Oyedepo & Damilola Oduolowu