Super Eagles: Bi Yisa Sofoluwe ṣe di olóògbé ni Luth

Iṣẹ́ takuntakun ti Yisa Sofoluwe ti ṣe ni Dúníyàn

Oríṣun àwòrán, NAtion

A bí Yisa Sofoluwe ni ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kejílá, ọdún 1967 to si gbá bọ́ọ̀lù fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi a dile ẹyin mú.

Ẹyìn ni apá òsì ni ìròyìn sọ pé ó máa ń gbá láàrin ọdún 1983 si ọdun 1988, bákan náà ló gbá Nation's Cup ọdún 1984 àti ti 1988

Sofoluwe jẹ góòlù kan fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò náà.

Ó farahàn nínú idíje bọ́ọ̀lù Nàìjíríà fún ìgbà ogójì lásìkò tó n gbá bọ́ọ̀lù

Bákan náà ni Sofoluwe ti fi igba kan jẹ́ agbábọ́ọ̀lù Abiola Babes nílùú Abeokuta, IICC ti Ibadan àti Gatew+ay Abeokuta.

Ṣááju ni ìròyìn kàn pé, àgbà ọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù náà ṣe àìsàn to sì gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn LUTH.

Ọ̀kan ninu àwọn ọrẹ́ rẹ̀ Waidi Akanni sàlàyé pé, àwọn ń gbìyànJÚ láti wá owó tí yóò fi ṣe iṣẹ́ abẹ̀ tó nílò, ṣùgbọ́n ẹpa kò bóró mọ́.

Ìròyin sọ pé mínísítà fún eré ìdárayá àti ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ lọ́sàn ọjọ́ Iṣẹgun gbé ìgbésẹ̀ láti ran Sofoluwe lọ́wọ́ láti bá gómìnà ìpínlẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ kí wọ́n lé ràn an lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ abẹ náà.

Mínísítà fí owó ránṣẹ́ pẹ̀lú láti fi ran ìtọ́jú rẹ̀ lọ́wọ́ sùgbọ́n kò dúró ṣe iṣẹ́ abẹ náà tó fi gbekuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra.

Agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Super Eagles tẹ́lẹ̀rí Yisa Sofoluwe jáde láyé

Oloogbe Sofoluwe

Oríṣun àwòrán, Google

Agbabọọlu ikọ Super Eagles tẹlẹri, Yisa Sofoluwe ti jade laye ni ẹni ọdun mẹrinlelaadọta, lẹyin to ṣe aisan.

Opin ọsẹ yii ni iroyin jade nipa aisan rẹ lẹyin ti wọn lo ni aisan ninu agbari, cerebral atrophy to niiṣe pẹlu ọpọlọ.

Aisan yii ma n jẹ ki gbogbo sẹẹli ọpọlọ ni ifasẹyin, ti ọpọlọ ko si ni lee ṣiṣẹ mọ bi o ṣeyẹ.

Sofoluwe ni agbabọọlu ẹyin to n dile mu nigba aye rẹ, ti gbogbo aye si mọ ọ si "Dean of Defence".

Ọjọ Kejidinlọgbọn, Oṣu Kejila, ọdun 1967 ni wọn bi akọni naa to si gba bọọlu si awọn lẹẹkan fun orilẹede Naijiria.

O gba bọọlu pẹlu ikọ to de aṣekagba idije AFCON ni ọdun 1984 ati ọdun 1988.

Awọn akẹgbẹ rẹ ati awọn ololufẹ rẹ ni wọn ti n ṣe idaro rẹ lẹyin to papoda pe ki Edua de ilẹ fun ẹni ire to lọ.

Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ oríkì ìlú ara rẹ tó olùkọ́ yìí tó dántọ́ lẹ́nu rẹ̀ bíi ọmọ ìlú rẹ?