Èṣù ló sún mí débi kí n bá ọmọ mí obìnrin ní ìbálòpọ̀ - Bàbá ẹni ọdún 55

Oríṣun àwòrán, Philipine Star
Arakunrin ẹni ọdún marundinlọgọta kan ti ko sí panpẹ awọn agbofinro lẹyìn tó jẹwọ pe oun ni Ibalopọ pẹlu ọmọ bibi oun to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun.
Arowolo Ayodeji to n ṣiṣẹ ọlọdẹ ni ẹẹmeji pere loun hu iwa yii ati pe iṣẹ ọwọ èṣù ni.
Lasiko ti awọn oṣiṣẹ àjọ ẹṣọ aabo ilu, Civil Defence n ṣafihan rẹ fawọn akọroyin ni ilu Ilorin, o ni igbeyawo oun àti iya ọmọ naa ti fori sanpọn lati igba to wa lọmọ'dun meji.
Nigba ti wọn tẹ ninu lati sọrọ si, o ni èṣù lo lo oun lati hu iwa buruku yi.
"Ẹẹmeeji pere ni mo ni ibalopọ pẹlu ọmọ mi; Ṣugbọn mi o mọọmọ"
Ẹwẹ, alukoro NSCDC, Olasunkanmi Ayeni, sàlàyé fun BBC Yoruba pe Ileesẹ ijọba tó n mojuto awọn ọmọde lo ta awọn lolobo ọrọ yi.
O ni ileesẹ yii ati awọn ẹka kan lọdọ awọn Civil Defence jijọ n pawọpọ lori ọrọ yii ni.
Lati igba ti ọmọ naa ti wa ni ọdun kmeje ni baba rẹ yii ti n ba lopọ
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ilu Ijero Ekiti ni ọwọ ti ba afurasi naa ki wọn to geb lọ siluu Ilorin fun itẹsiwaju iwadii naa.
Ọgbẹni Ayeni sọ pé “Iya ọmọ yẹn ko si lọdọ baba ẹ mọ, a dẹ bere lọwọ baba-baba ọmọ naa, gẹgẹ bi agbalagba, o ni oun ko mọ pe irufẹ nnka bẹẹ n ṣẹlẹ laarin wọn.”
“Lati igba ti ọmọ náà wà lọmọ'dun meje la gbọ pé o ti n ni Ibalopọ pẹlu rẹ”
“Eyi sí tunmọ sí pé kò ṣẹṣẹ máa hu iru iwa bẹẹ.”












