Ìdí tó ṣe ṣòro láti gba Visa Dubai lásìkò yìí rèé àti ọ̀nà àbáyọ - Abike Dabira Erewa

Abike Dabiri-Erewa

Oríṣun àwòrán, abikedabiri

Alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, NiDCOM, Abike Dabiri-Erewa ti sọ pe ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n waye nilẹ Dubai lo jẹ ko ṣoro fun awọn ọmọ Naijiria to jẹ ọkunrin lati wọ ilẹ naa lasiko yii.

O ni awọn ọmọ Naijiria ọkunrin ti ọjọ ori wọn ko ju ọgbọn ọdun si isalẹ lọ ni igbesẹ tuntun naa pa lara.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ Arise News Channel, ni Erewa ti fi ọrọ naa lede.

O ni “Mo gbabọ pe iṣe ile ti ba wọn ọmọ Naijiria kan jade, iwa buburu naa si ti kọja oju ẹ, a si gbọdọ gba pe bi ọrọ ṣe ri niyẹn.”

“Eyii ki ṣe ọrọ idẹyẹsi rara, wọn ti ṣe aṣeju ninu iwa bururu yii.”

“Ohun ti ijọba Dubai wa ṣe ni pe wọn mu ko ṣoro lati gba iwe irinna, Visa, fun awọn ọmọ Naijiria.”

“Nitori naa, ti ọjọ ori rẹ ba jẹ ọgbọn ọdun si isalẹ ti o si jẹ ọkunrin, ko si Visa fun ọ niyẹn.”

“Wọn mọọmọ jẹ ko nira lati ni awọn amuyẹ lati gba Visa naa, ko si ni nnkan ṣe pẹlu irufẹ eeyan ti ẹni to fẹ gba Visa naa jẹ.”

Awọn amuyẹ fun Visa Dubai

Ere wa ṣalaye pe Dubai ti n bere iwe isiro iye owo to n wọle ati jade ninu banki ti eeyan n lo bayii.

Irufẹ ẹni bẹẹ si gbọdọ ti ra tikẹẹti ti yoo fi pada si Naijiria, ati pe o tun gbọdọ pese ẹri pe oun ti ni ile tabi ibi ti oun yoo maa gbe ni gbogbo akoko to yoo fi wa ni Dubai, bi bẹẹ kọ, irufẹ ẹni bẹẹ ko ni gba Visa.

O ni “O gbọdọ ra tikẹẹti ti o maa fi pada si Naijria, o gbọdọ pese iwe apo ifowopamọsi rẹ lati oṣu mẹfa sẹyin, o si gbọdọ pese ẹri nipa ile ti o maa de si... ti o ba dẹ pa irọ, wọn yoo mọ, wọn yoo si da ọ pada sile rẹ.”

Lẹyin naa lo gba awọn ọmọ Naijiria lamọran lati bọwọ fun ofin orilẹ-ede ti wọn ba rinrinajọ lọ, ki wọn si maa ṣe ohun to yẹ, ki wọn ma ba ṣe akoba fun awọn ọmọ ilu rere to n ṣiṣẹ oojọ wọn ni irufẹ orilẹ-ede bẹẹ.

Ni ti ọmọ Naijiria ti wọn lu pa lorilẹ-ede Italy, Alika Ogorchukwu, Erewa ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ ọfintoto iṣẹlẹ naa, awọn eeyan kan si ti n ṣe ikowojọ fun iyawo ati mọlẹbi to fi silẹ.