Kí ló dé tí àwọn ọ̀dọ́ ìlú fárígá lọ dáná sun "mortuary" ọlọ́dani kan?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Kaakiri oju opo ayelujara nisè láwọn eeyan n salabapin aworan ati fidio tó ṣafihan b'awọn ọdọ kan ṣe fi ibinu dana sun ile igbokupamosi kan ni ilẹ Igbo. Ibeere ti ọpọ sí n beere ni pé kí ló ṣẹlẹ ati pe nibo ni iṣẹlẹ yi ti waye. BBC ṣe iwadii ọfintoto lórí ọrọ naa. Ababọ wa ree.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ni ọjọru ni iṣẹlẹ yi waye ni ilu kan torukọ rẹ n jẹ Ndiolumbe to sì wá ni ijọba ibilẹ siala Ngwa South nipinlẹ Abia. Awọn ọdọ kan lo dana sun ile igbokupamosi lori ẹsun pe àwọn tó ní ààyè naa n tà ẹya ara èèyàn lọnà tí kò tọ.
Ki lawọn ọlọpaa Ipinlẹ Abia naa sọ?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
BBC ba alukoro ileesẹ ọlọpaa Abia, Geoffrey Ogbonna sọrọ to si ni èèyàn kankan ko tii mu ẹjọ wá sí ọdọ àwọn lori iṣẹlẹ naa. O ni awọn n reti ẹni tó ní ilé igbokupamosi ko wa fejosun ṣugbọn o ni iwa ti ko bojumu ni k'awọn eeyan maa dá idajọ ṣe lọwọ ara wọn. O fikun un pe tohun ti bẹẹ awọn ọlọpaa ti lọ sí ibi iṣẹlẹ naa ti iwadii sí ti bẹrẹ. O ni nigba tawon dé ibẹ nkan tàwọn ba yatọ sí iroyin tó gbòde. O ni laipẹ awọn yóò fi atẹjade ṣọwọ́ sí BBC lori abajade awọn.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Akoroyin BBC to kàn sí àdúgbò náà jabọ pe awọn ri ọkọ kan ti wọn láwọn to n se owo ẹyà ara eeyan gbe kalẹ sibẹ lalae fi to ẹni tó ní ilé igbokupamosi naa leti. Titi di akoko yi ko sí ẹni tó lè sọ pàtó ibi ti eni to ni ile igbokupamosi naa wa. Onitọun naa ko sí ti bá àwọn akọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa.











