Bàbá Orlando Owoh ti lọ kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ohùn orin wọn fi ṣe oríire láyé - Orlando Ore

Àkọlé fídíò, King Atayeshe Orlando Ore: Ní ìbẹ̀rẹ̀ tí mo fẹ́ máà kọrin bíi Orlando, kò sí ẹni tó gbà mí
Bàbá Orlando Owoh ti lọ kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ohùn orin wọn fi ṣe oríire láyé - Orlando Ore

Ọmọ bibi ilu Odigbo ni Temitope Olaoye ni ipinlẹ Ondo. Ọ sọ bi o ṣe bẹrẹ iṣẹ orin ati iha ti awọn eeyan kọ sii ko to di pe o de ipo to wa bayii.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Temitope ti ọpọlọpọ ololufẹ rẹ mọ si Orlando Ore ti orukọ toun fun ara rẹ si n jẹ King Atayeshe ṣalaye pe oun ko tilẹ lanfani lati ri agbaọjẹ olorin ti Ọlọrun wa fun un ni ohun bii tirẹ soju rara nigba aye rẹ.

Orlando Ore ati Orlando Owoh
Orlando Owoh

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Mo maa pe ọdun mẹtala lori itage orin kikọ bayii amọ lati ọdun mẹẹdogun sẹyin ni Baba Orlando Owoh ti re bi agba n re.

Titi di oni lawọn eeyan ṣi kan sara si bun ti oloogbe Orlando owoh ni debi pe wọn ṣi n gbọ orin rẹ, iru ifẹ yii naa ni awọn eeyan to ti mọ King Atayeshe Orlando Ore ni sii tori pe gẹlẹ bii Baba Orlando ti wọn fẹran naa ni Orlando Ore ṣe n kọrin tirẹ.

Orlando Ore

Akẹkọgboye ninu imọ ẹkọ orin kikọ ni Temitope jẹ to si sọ ninu fidio yii nipa ifẹ alailẹgbẹ to ni fun orin kikọ.