Áyédèrú ni ọ̀pọ̀ ìwé ẹ̀rí tí Adeleke gbé fún INEC - Gómìnà Oyetola

Aworan Ademola adeleke ati Gomina Oyetola

Oríṣun àwòrán, others

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ati Gomina Adegboyega Oyetola ti ipinlẹ Osun ti kọ iwe si ile ẹjọ lati yi esi idibo to gbe Ademola Adeleke, ti ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party wọle gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa losu to kọja danu.

Ẹgbẹ APC sọ eyi nitori wọn ni iwe eri ti Adeleke gbe kalẹ jẹ ayederu.

Sẹnetọ Ademola Adeleke, ẹni to bori eto idibo naa labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP ni apapọ ibo 403,371 eyi to mu ko fi ẹyin gomina to wa lori aleefa janlẹ, eyiun Adegboyega Oyetola.

Iwe ẹjọọ titako eto idibo naa waye ni ile-ẹjọ giga ni Osogbo, olu-ilu ipinle Ọsun.

Oju ewe ẹgbẹrun niye iwe ti Gomina Gboyega Oyetola fowo si pẹlu Alaga ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ọsun, Gboyega Famodun, ti wọn si fi sọwọ si ile ẹjọ lori erongba wọn lati gba ipo naa pada.

aworan gomina Gboyega Oyetola

Agbẹjọro agba fun Gomina Oyetola, Kunle Adegoke, nigba ti o ba awọn akọroyin sọrọ nipe, Gomina ti ṣeto awọn agbejọro to to aadọta niye lati lọ fi idi otitọ mulẹ ni ile ẹjọ pe Sẹnetọ Ademola Adeleke ko yẹ ni gomina latari bi o ṣe lo ayederu iwe ẹri fun eto idibo gomina ni ipinlẹ Osun.

Adegoke ni iwadi awọn ti kẹfin gbogbo kọlọfin ohun ti ẹgbẹ oṣelu PDP ati Sẹnetọ Ademola Adeleke gbe ṣe nigbati eto idibo waye.

“O da wa lọju pe Alhaji Isiaka Gboyega Oyetola lo jawe olubori ninu eto idibo gomina to waye ni ipinlẹ Osun.

Ki a kọkọ bẹrẹ pe iwe ẹri ti Sẹnetọ Adeleke gbe fun ajọ INEC ni iwadi wa ti fihan pe ayederu ni, ti kọ si yẹ ni gomina ipinlẹ naa.

“Ikeji ni pe, a kẹfin kọlọfin ni awọn ijọba ibile kan ni ipinlẹ Osun, eyi ti wọn ti gbe ru gomina Oyetola lẹyin, ti a si ti sẹtan lati gbe lọ si ile ẹjọ bayi.”