Aregbesola ń gbẹ̀yìn bẹbọjẹ́ fún Tinubu l'Osun- APC

Oríṣun àwòrán, others
Rogbodiyan to n sele ninu egbe oselu All Progressive Congress nipinle Osun ti tun gba ona miran pẹlu bi awọn ẹgbẹ kan ti won n pe ara wọn ní The osun progressive (TOP) ati APC Youth wing ṣe ya si igboro ilu Osogbo lati fi ehonu han lori iha ti Gomina tẹlẹ rí ipilẹ Osun ko si ẹgbẹ oselu APC.
Awọn igun ọdọ ninu ẹgbẹ oselu All Progressive Congress fẹsun kan gomina ana ni Ipinlẹ Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola pe o ṣíṣe tako erongba olujide sipo aarẹ Orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ni Ipinlẹ Osun Alaga fun awọn ọdọ, Goke Akinwemimo lo sọrọ síta fun awọn akoroyin niluu Osogbo lọjọbọ, tí ó sì pe akiyesi sì Ọga agba fun ẹgbẹ oselu APC pe minisita ko si ninu ẹgbẹ oselu naa mọ. Akinwemimo ni o da oun loju pe erongba minisita naa ati awọn alátilẹyin rẹ ni ko ni wa si ìmuṣẹ lori bi wọn ṣe n gbero lati mu ijakunlẹ ba ẹgbẹ oselu APC siwaju eto ìdibo lọdun 2023.
O ni, "A sọ gbogbo eleyi lati pe akiyesi awọn adari ẹgbẹ oselu pe Aregbesola ko si ninu ẹgbẹ oselu APC mu. "Aregbesola ati awọn alátilẹyin ni a ri gbogbo ete ti wọn gbero lati ri pe ẹgbẹ oselu APC ko mu orí yọ ninu eto ìdibo. "Wọn ti bẹrẹ ọtẹ lati ri pe ẹgbẹ oselu APC fidi remi ninu eto ìdibo lọjọwaju."
Irọ ní o, Ọmọ Ẹgbẹ Oṣelu APC tọkàntọkàn ni Rauf Aregbesola ni ipinle Osun- Igun Aregbesola fèsì

Oríṣun àwòrán, others
Ṣugbọn ọrọ ba ibo miiran lọ lọdọ awọn The osun progressive (TOP), ti ya si igboro ilu Osogbo lati fi ehonu han pe ki won yo alaga egbe oselu ipinle naa kuro ọgbẹni Gboyega famoodun gẹgẹ bí oludari.
Awọn olufẹhonuhanti ni wọn jẹ alatilẹyin oloootọ si gomina tẹlẹ ti ipinlẹ Ọsun ati minisita fun eto abẹle lọwọlọwọ Rauf Aregbesola bẹrẹ iwode ìfẹ̀hónúhàn wọn lati abẹ afárá gbajugbaja olaiya ni ilu Osogbo ki wọn to fopin si ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun.
Lara awon olufẹ̀hónúhàn naa to ba awon oniroyin soro, Abosede oluwaseun ati Sodiq olajide pé fún yiyọ alága ẹgbẹ́ Gboyega Famodu gẹgẹ bí Olùdarí, àtúntò ẹgbẹ APC l'osun ati pe ki awọn alasẹ òke pe Ọgbẹni Rauf Aragbesola pada.
Oluwaseun ati olajide tun fi ẹsun kan Famoodun pe o ṣe agbekalẹ iselu ipinya eyiti o jẹ ọkan ninu awọn okunfa eyi ti o fa ijakule egbe naa ninu idibo gomina lojo kerindinlogun osu keje ni ipinle Ọsun.
Lakoko ti awọn olufẹ̀hónúhàn se iwode lo ile igbimọ aṣòfin ipinlẹ Ọsun ni onarebu Timothy Owoeye rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati fara balẹ, o si ṣeleri pe ẹgbẹ APC yoo yanju awọn rogbodiyan ti naa laipẹ.
Awọn olufẹ̀hónúhàn naa fi lẹta fun olori ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọsun onarebu Timothy owoeye lati fijiṣẹ fun igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ APC ni Abuja.












