Ṣé lóòtọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́jáde fásitì Ibadan gbé $1m fún UCH?

Oríṣun àwòrán, @Igbopeople
Akẹkọọ imọ iṣegun nigba kan ri ni nile ẹkọ ẹkọṣẹ iṣegun fasiti ijọba apapọ to wa niluu Ibadan, College of Medicine, dokita Philip O. Ozuah, ti gbe miliọnu kan dọla kalẹ fun ile ẹkọ naa.
Tako iroyin to n lọ kaakiri ori ayelujara, ile ẹkọ College of Medicine, ti fasiti ilu Ibadan, UI, ni wọn gbe owo yii kalẹ fun, kii ṣe ile iwosan nla UCH ilu Ibadan.
Ọkan lara awọn ẹka ẹkọ iṣegun fasiti Ibadan, UI, ni College of Medicine jẹ, kii ṣe ara UCH bo tilẹ jẹ pe ileewosan naa ni wọn n lo.
Ozuah gbe owo tabua yii kale nibi ipade awọn ọmọ ẹgbẹ akẹkọọjade ile ẹkọ naa kan to wa lori ikanni Zoom, lori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, College of Medicine
Nibi ipade naa, ti ọga agba fidihẹ ile ẹkọ naa, Ọjọgbọn Olayinka Omigbodun pe awọn eeyan ọhun si lo ti bere fun iranlọwọ wọn.
Ọjọgbọn Olayinka Omigbodun ni ipo ti ile ẹkọ naa wa ko tẹ awọn lọrun, awọn si nilo owo lati ṣe awọn atunṣe kan si ile ẹkọ ọhun.
Lara awọn atunṣe naa ni kikọ ileegbe tuntun fun awọn akẹkọọ, atunsẹ awọn kilaasi wọn atawọn nnkan mii.
O ni ojuṣe ijọba n lati ṣe awọn nnkan wọnyii amọ ijọba ko lowo lọwọ, eredi ree to fi ke si awọn akẹkọọjade naa lati dide iranlọwọ fun ile ẹkọ ọhun to jẹ orisun wọn.

Oríṣun àwòrán, College of Medicine
Ko pẹ ti ikede naa jade ti awọn akẹkọọjade ọhun, ti gbogbo wọn ti di dokita bayii, bẹrẹ si n ṣeleri iye owo ti awọn yoo fi ran ile ẹkọ naa lọwọ.
Bi awọn kan ṣe n ṣeleri ẹgbẹrun lọna igba naira, miliọnu kan naira ati bẹẹ lọ, ni dokita Ozuah, si iyalẹnu gbogbo awọn akẹgbẹ rẹ ṣeleri miliọnu kan dọla.
Ozuah ni oun gbe owo naa kalẹ fun kikọ ilegbe fun awọn akẹkọọ ile ẹkọ ọhun.
Ta ni dokita Philip O. Ozuah?
Dokita Philip O. Ozuah jẹ ọkan lara awọn to kẹkọọ gboye nipa imọ iṣegun ni ile ẹkọ ẹkọṣẹ iṣegun, College of Medicine, to wa ni fasiti ilu Ibadan, UI.
Ọdun 1985 ni Ozuah jade nile ẹkọ naa ko to lọ kawe siwaju si niluu Carlifornia, nilẹ Amẹrika, lẹyin naa lo tun gboye ọmọwe nipa imọ iṣegun ni fasiti University of Nebraska-Lincoln, nilẹ Amẹrika.Oun ni alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Montefiore Medicine, to ni ajọṣepọ pẹlu ile ẹkọ Albert Einstein College of Medicine, nilẹ Amẹrika yii kan naa.Ṣáájú ni ìròyìn to ń jáde lórí ayélujára nípa ìròyìn ẹ̀bùn owó yìí sọ pé ojogbon Ogunbiyi ni adari koleeji tó ń kọ́ni ni imọ nípa ètò ìlera lọ tẹ́wọ́ gbà owó náà.
Ṣáájú ni ìròyìn to ń jáde lórí ayélujára nípa ìròyìn ẹ̀bùn owó yìí sọ pé ojogbon Ogunbiyi ni adari koleeji tó ń kọ́ni ni imọ nípa ètò ìlera lọ tẹ́wọ́ gbà owó náà .
Àti pé ojogbon Olayinka Olusola omigbodun ni adari eka eto eko náà lásìkò yii, Òun sì ni obìnrin àkókò tí yóò jẹ adari eka eko eto ìlera college of medicine ni Fáṣítì ibadan. O je akosemose imọ nipa itọju ọpọlọ, (Psychiatry) psychatry

Oríṣun àwòrán, other
Ṣùgbọ́n nígbà tí bbc yoruba kan sì àwọn aláṣẹ eka eto eko náà ni Fáṣítì Ibadan ni wọn ṣàlàyé lórí àṣìṣe náà pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹẹ.
Ṣùgbọ́n nígbà tí bbc yoruba kan sì àwọn aláṣẹ eka eto eko náà ni Fáṣítì Ibadan ni wọn ṣàlàyé lórí àṣìṣe náà pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.ọÀti pé ojogbon Olayinka Olusola omigbodun ni adari eka eto eko náà lásìkò yii, Òun sì ni obìnrin àkókò tí yóò jẹ adari eka eko eto ìlera college of medicine ni Fáṣítì ibadan.
O je akosemose imọ nipa itọju ọpọlọ, (Psychiatry)












