Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n yọ ìtàn ẹ̀yà Igbo kúrò nínú ìwé tí àwọn ọmọ ilẹ ẹ̀kọ́ ń lò ní Naijiria?

Awọn eeyan to n wo Egungun kan to n jo nipinlẹ Ebonyi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Egungun kan to n jo nipinlẹ Ebonyi
    • Author, Chiamaka Enendu
    • Role, BBC Global Disinformation Unit
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin ọdun marundinlogun, ijọba Naijiria ti da ẹkọ nipa itan orilẹede pada si awọn ẹka eto ẹkọ ni Naijiria.

Loṣu to kọja, Umwelo Victor, to maa n sọrọ lori ayelujara nipa ọrọ awujọ ati oṣelu ṣe fidio kan nibi to ti bu ẹnu atẹ lu iwe kan ti ọmọ rẹ n lo nilẹ ẹkọ.

Victor sọ pe iwe ọhun ti orukẹ rẹ n jẹ "Living History Book 1" ko mẹnuba itan ẹya Igbo ni Naijiria, eyii to jẹ akitiyan lati pa itan ẹya naa rẹ.

Ọpọ eeyan lo ti wo fidio naa bayii ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu iwe ọhun.

Nigba to n ba BBC sọrọ, Victor iwe akọkọ loun n mẹnuba, amọ iwe keji sọrọ nipa ẹya igbo ni Naijiria daadaa.

Ileeṣẹ to tẹ iwe naa jade ti sọ pe gbogbo ohun to wa ninu rẹ lo wa ni ibamu pẹlu alakalẹ eto ẹkọ ijọba Naijiria.

Iwe Living History to da awuyewuye silẹ lori ayelujara
Àkọlé àwòrán, Iwe Living History to da awuyewuye silẹ lori ayelujara

Ki lo wa ninu iwe naa?

Ẹya mẹta gboogi lawọn eeyan da mọ ni Naijiria, awọn ẹya naa si ni Hausa, Yoruba ati Igbo, ti wọn jẹ nnkan bii ida 70% ọmọ Naijiria.

Oniruru ẹya mii lo tun wa ni Naijiria yatọ si awọn wọnyii.

Awọn to tako iwe naa sọ pe iwe ọhun ko mẹnuba awọn itan to ṣe pataki nipa ẹya Igbo Naijiria.

Ileeṣẹ to tẹ iwe naa, Accessible Publishers sọ fun BBC pe iwe akọkọ sọ itan nipa awọn igbo nigba ti apa keji ṣalaye nipa aṣa ati ọlaju wọn.

Accessible Publishers fi kun pe oun tẹ iwe naa pẹlu ajọṣẹpọ awọn onkọwe lati inu ẹya igbo ki iwe naa le pe.

BBC ra iwa naa lati apa kinni titi de apa kẹta.

Apa kinni iwe naa darukọ igbo gẹgẹ bii ọkan lara awọn ẹya to ṣe pataki julọ ni Naijiria loju ewe karundinlogun, awọn oju ewe mii ṣalaye ni kikun nipa awọn ẹya miran ni Naijiria yatọ si ẹya Igbo.

Ere yii jẹ lara awọn ohun aṣa Igbo ti iwe naa mẹnuba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ere yii jẹ lara awọn ohun aṣa Igbo ti iwe naa mẹnuba

Iwe naa ṣalaye nipa ibẹrẹ ọlaju Igbo ninu abala to n sọrọ nipa Nok, Ife, Benin ati Igbo Ukwu lai fi odidi oju ewe kankan silẹ fun ẹkunrẹrẹ itan wọn.

Gẹgẹ nii alakalẹ ijọba apapọ, ẹkọ ile ẹkọ girama akọkọ, JSS1 yoo dojukọ itumọ ati ipinlẹ itan atawọn ibi to ṣe pataki ninu itan ẹya kọọkan ni Naijiria ṣaaju ijọba amunisin. Lara awọn ohun ti wọn mẹnuba nibẹ ni Hausa-Fulani, Oyo ati Benin.

Ọjọgbọn Olutayo Adesina ni fasiti ilu Ibadan sọ pe ko ya oun lẹnu pe awọn kan koro oju si iwe naa latari pe ko ṣalaye nipa ẹya wọn daadaa.

Ọjọgbọn naa ni ibere to yẹ ki awọn eeyan maa bere ni pe ṣe wọn mọọmọ yọ itan ẹya naa ni tabi aṣiṣe ni.

O tun bere pe ṣe gbogbo ẹya to wa ni Naijiria ni wọn fun iye oju ewe kan naa lati ṣalaye itan wọn.

Awọn wo lo n ka iwe naa?

Ife ti wọn fi n mu omi ni ẹya Igbo Ukwu laye atijọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ ni Naijiria sọ pe awọn ko tii buwọlu iwe naa fun lilo lawọn ile ẹkọ.

Ti ijọba ko ba tii buwọlu iwe naa fun kika, bawọ wa lawọn akẹkọọ kan ṣe n ka a?

Ọgbẹni Victor nigba to n ba BBC sọrọ sọ pe iwe ọhun lọmọ oun to wa nile ẹkọ giga kan niluu Port Harcourt n ka.

O tẹnumọ pe ti wọn ko ba buwọlu u fun lilo, yoo ṣoro ki awọn akẹkọọ to maa lo o.

Nigba ti a kan sile ẹkọ naa, awọn alaṣẹ rẹ fidi rẹ mulẹ pe o wa lara iwe ti wọn buwọlu fun wọn fun lilo.

Ile ẹkọ ọhun sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn maa n duro de ontẹ ijọba fun iwe lilo, awọn naa maa n gbe igbesẹ lati lo awọn iwe kan lẹyin ti wọn ba ṣe iwadii to yẹ nipa iwe naa tan.

Wọn fi kun pe obi kankan ko tii sọrọ tako iwe ọhun leti awọn lati igba ti wọn ti n lo o.

Itan ẹkọ itan lawọn ile ẹkọ ni Naijiria

Fun ọpọ igba lawon alaṣẹ ti ṣatunṣe si ilana ẹkọ ni Naijiria lẹyin ominira.

Ni ibẹrẹ ọdun 1980, wọn yọ ekọ itan kuro lara ohun ti awọn akẹkọọ yoo maa kọ fun awọn to ṣẹṣẹ wọ ile ẹkọ girama.

Lasiko naa, awọn to wa ni ipele SS1 si SS3 lo n kọ ẹkọ naa, kii sii ṣe dandan.

Nigba to di ọdun 2009 ni wọn fa ẹkọ itan yọ patapata nile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ipele JSS1 si JSS3.

Ṣugbọn ọpọ araalu lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba ọhun.

Lẹyin ti ijọba da imọ ẹkọ naa pada lọdun 2025, ọpọ ọmọ Naijiria lo faramọ amọ wọn n ṣọ ohun ti wọn n kọ awọn naa akẹkọọ lojulẹsẹ.