Àjọ NRC gbẹ́sẹ̀lé ìrìnnà reluwé lójú òpó Eko, Abuja, Kano àti Ajaokuta

Oríṣun àwòrán, Nigeria railway corporation
Ajọ irinna reluwe lorilẹede Naijiria, NRC ti bẹgile iriina reluwe loju opo rẹ gbogbo ni Eko, Abuja ati Ajaokuta nitori ipaya lori abo.
Oludari agba ajọ naa, Fidet Okhiria fidi eyi mulẹ fun awọn akọroyin lọjọru.
Oludari ajọ reluwe ni Naijiria Fidet Okhiria ṣalaye pe igbesẹ naa waye nitori ibẹru gulegule ikọlu awọn agbebọn.
O sọ ọ yanya pe iroyin igbiyanju awọn agbebọn lati ji awọn arinrinajo kan to n gbera lati Ajaokuta lọ silu Abuja lọjọ Aje.
O ni awọn agbebọn naa yinbọn lu awọn arinrinajo naa bi o tilẹ jẹ wi pe wọn moribọ.
Adari agba ajọ irinna reluwe Naijiria naa wa gba awọn arinrinajo to ba fẹ ba reluwe rin loju opo naa lati lo awọn ibudokọ reluwe to wa ni Itakpe tabi Itogbo titi di igba ti ti ọr abo lagbegbe naa yoo ṣe gbojule.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Railway Corporation
“Ni ibamu pẹlu aṣẹ ti minisita sọ, irinna reluwe loju opo Abuja si Kaduna ṣi wa ni idaduro naa titi di igba ti awọn arinrinajo tawọn agbebọn ji gbe lasiko ikọlu to waye nibẹ ba ti gba itusilẹ ti wọn si gbe ohun elo abo si oju opo naa”
Bakan naa lo ni oju opo Eko si Kano naa yoo ṣi dawọduro naa nitori gulegule awọn agbebọn lagbegbe Minna si Kaduna.
Ki ni ijọba apapọ n ṣe lori ọrọ abo fun irinna reluwe ni Naijiria?
Atẹjade yii n waye lẹyin wakati diẹ ti minisita tuntun ti aarẹ Buhari ṣẹṣẹ yan fun igbokegbodo ọkọ, Onimọẹrọ Mu’azu Jaji Sambo kede pe ijọba apapọ yoo bẹrẹ si ni lo awọn ohun elo ẹṣọ igbalode laori awọn oju opo reluwe gbogbo lorilẹede Naijiria lati dena atunṣẹ ikọlu ati ijinigbe to waye loju opo reluwe Abuja si Kaduna.

Oríṣun àwòrán, Ministry of transportation Nigeria
Minisita tuntun naa, Onimọẹrọ Jaji Sambo ṣalaye pe irinna reluwe lojuna Abuja si Kaduna ko lee bẹrẹ pada ayafi ti gbogbo awọn arinrinajo to ku ni ikawọ awọn agbebọn naa ba gba itusilẹ.
Bakan naa lo fi kun un ninu atẹjade kan ti Eric Ojiewe, adari ọrọ iroyin ni ileeṣẹ eto igbokegbodo ọkọ nijọba apapọ Naijiria fi sita pe eyi yoo mu karaalu tubọ ni igbẹkẹle ninu lilo eto irinna reluwe naa.












