Ọta ìbọn tí wọ́n yìn mọ́ mi ṣi wà nínú ara mi- Arìnrìnàjò ọkọ̀ reluwe Abuja sí Kaduna tó jàjàbọ́

Oríṣun àwòrán, OTHERS
"Mo ṣẹṣẹ sun ẹkun tan ni, ẹkuna yọ pe mo maa pada ri awọn mọlẹbi mi".
Ọjọgbọ́n kan to wa lara awọn ti awọn ajinigbe ji gbe ni oju ọna irin Abuja si Kaduna kẹnu bọ ọrọ ti yoo pa eeyab to n wo fidio rẹ to jade sita gan lẹkun.
O ni oun ko le laye gbadura ki iru iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ si ọta oun leyi to jẹ pe wọn fẹrẹẹ lo odidi oṣu mẹrin ni ahamọ ajinigbe.
"Ko fi bẹẹ si ounjẹ, ebi pa wa fun oṣu mẹta atabọ, awa la tun sanwo fun ounjẹ ti wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni gbe wa ni ọsẹ bii meji sẹyin".
O ṣalaye bi ọmọ ikoko ti ko tii pe ọdun kan ati arugbo kan to ti pe aadọrun ọdun naa ṣe n jẹun ẹẹkan lojumọ.
Ọkan lara awọn ti Ọ́wọn ji gbe ni oju ọna irin Abuja si Kaduna ti sọ iriri rẹ lọwọ awọn agbebọn to ji wọn gbe.
Arakunrin Sidi Aminu Sharif wa lara awọn marun un ti wọn ṣẹṣẹ tu silẹ ni ahamọ awọn agbebọn lati Ọjọ Kejidinlọgbọn, Oṣu Kẹta ti wọn ti ji wọn gbe.
Amọ ko i tii han si gbangba boya wọn san owo idoola ẹmi fun awọn agbesunmọmi naa, ki wọn to fi wọn silẹ.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Arakunrin to n ba awọn agbesunmọmi naa duna dura, Tukur Mamu fi orukọ awọn marun un ti wọn tu silẹ gẹgẹ bi Ọjọgbọn Mustapha Umar Imam, to jẹ dokita ni fasiti ileewosan imọ ẹkọ ti Usman Dan Fodio University Teaching Hospital, Sokoto, Akibu Lawal, Abubakar Ahmed Rufai Mukthar Shu’aibu ati Sidi Aminu Sharif.
Mamu to ni oun ko ipa ribiribi lori itusilẹ awọn arinrinajo naa ni oun ko ṣe mọ nitori idunkoko mọ ẹmi oun ati aibikita ijọba apapọ.
''Dokita wa gbogbo inu mi fun ọta ibọn ni ahamọ amọ ko ri''
Sidi Aminu Sharif to sọ iriri rẹ ni o le ni oṣu mẹrin ti awọn lo ni ahamọ.
O sọ ibẹru rẹ nipa eto ilera ara rẹ nitori inu ahamọ naa ni wọn ti yin ibọn fun ni ikun.
Lasiko to n sọrọ nilu Kaduna ni gbogbo igbiyanju dokita ti wọn jọ wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa lati yọ ọta ibọn naa lo jasi pabo.
O ni ireti oun nipe oun yoo lọ si ileewosan ki wọn ya aworan ikun naa pẹlu imọ sayẹnsi lati le wo ibi ti ọta ibọn naa ha si ninu oun.
‘’Mo ranti bi iṣẹlẹ naa ṣe waye ni ọjọ naa ḷoun ti mo si gbadura lẹyin ti mo gbọ iro nla kan.’’
‘’Ninu ahamọ ni wọn ti yinbọn fun mi ni inu ti ẹjẹ si san lọ si ẹsẹ mi’’
‘’O lo ibọwọ lati wo gbogbo inu mi boya yoo ri ọta ibọn naa amọ ko ri, lẹyin naa lo tun lo scissors lati fi wa ti ko tun ri.
Mi o mọ boya ọta ibọn si wa ninu mi amọ maa lo ṣe ayẹwo lati wo inu mi finifini.’’
Ọjọgbọn to wa lara wọn n rọ ijọba pe ki wọn ṣe ohun to tọ lati doola awọn to ku to ṣi wa lahamọ ajinigbe tori ohun ti oju wọn n ri nibẹ.












