À ń sa ipá wa láti gbógun ti ìgbésùnmọ̀mí - Buhari

Buhari

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Ijọba apapọ ti sọ pe oun n sapa oun lati koju fopin si igbesumọ atawọn iwa ọdaran mii ni Naijiria.

Aarẹ Muhammadu Buhari lo sọ ọrọ naa lasiko to n gba lẹta kan lati ọdọ aṣoju ijọba Canada si Naijiria, James Kingston Christoff, ati aṣoju ijọba orilẹ-ede Mexico, Juan Alfred Miranda Oritz, niluu Abuja.

Lasiko to n pe fun ifọwọsowọpọ awọn orilẹ-ede mii lagbaye, Buhari ni ijọba ti ṣe awọn aṣeyọri kan lati koju igbesumọmi pẹlu iranlọwọ awọn orilẹ-ede bii Canada ati Mexico.

Buhari ni “Rogbodiyann to n waye ni Libya ti fi kun awọn eto abo to mẹhẹ lawọn erekusu Afrika atawọn orilẹ-ede mii ni aringbungbun Afrika.”

“Rogbodiyan yii ko yọ Naijiria sẹyin nitori bi a ṣe n koju awọn iwa bii iwa janduku igbesumọmi, ija laarin awọn daran-daran atawọn agbẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.”

“Amọ a ti sẹ awọn aṣeyọri kan lati koju awọn iṣoro eto abo naa pẹlu iranlọwọ awọn orilẹ-ede to jẹ ọrẹ wa bii ti yin bayii lati koju awọn iṣoro naa.”

Buhari tun sọ pe ogun to n waye laarin Russia ati Ukraine ti mu ki ọwọngogo ounjẹ wa lagbaye.

O ni oun gbagbo pe eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ lagbaye, to fi mọ ajakalẹ arun Covid-19 naa tun kun awọn iṣoro ti ọpọ orilẹ-ede n dojukọ.

Nibi eto naa, to jẹ ayẹyẹ ikinikaabọ sẹnu iṣẹ tuntun awọn aṣoju orilẹ-ede mejeji naa, Buhari ni ki wọn maṣe yẹsẹ kuro ninu ilana ti awọn aṣaaju wọn fi lelẹ.