Àwọn dókítà ṣe ìpínyà ìbejì tí orí wọn lẹ̀pọ̀ láti orílẹ̀-èdè méjì ọ̀tọ̀tọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rọ Virtual Reality

Oríṣun àwòrán, PA Media
Awọn dokita lorilẹ-ede Brazil to ṣe ipinya awọn ibeji ti wọn lẹpọ lati ori pẹlu imọ ẹrọ Virtual Reality, VR.
Wọn ṣe iṣẹ abẹ naa fun awọn ọmọde ọhun ti wọn jẹ ọmọ ọdun mẹta, Bernardo ati Arthur Lima nile iwosan kan niluu Rio de Janeiro pẹlu itọsọna lati ile iwosan miran, Great Ormond Street Hospital, to wa niluu London.
Ikọ to ṣiṣẹ abẹ naa lo ọpọlọpọ oṣu lati kẹkọọ nipa bi wọn yoo ṣe ṣiṣẹ abẹ ọhun lẹyin ti wọn ti kọkọ ya aworan awọn ọmọ naa pẹlu ẹrọ CT ati MRI.
Ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba ti wọn ṣe onigbọwọ bi wọn ṣe pin awọn ọmọ ọhun, Gemini Untwined, ni ipinya naa jẹ eyii to lagbara ju ti awọn tii ṣe.
Adari ajọ naa, ọgbẹni Jeelani sọ pe o jẹ igba akọkọ ti awọn dokita yoo wa ni orilẹ-ede ọtọtọ ti wọn yoo si ṣiṣẹ abẹ ninu yara kan naa lori ẹrọ Virtual Reality.
Igba meje ọtọtọ lawọn ibeji naa ṣiṣẹ abẹ eyii ti ko din ni wakati mẹtadinlọgbọn, nnkan bii ọgọrun oṣiṣẹ lo si wa nibẹ nigba ti wọn n ṣẹ eyii to kẹyin.

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ara meeriri ni iṣẹ abẹ naa
Nigba ti yoo sọrọ lori bi iṣẹ abẹ naa ṣe waye lori ẹrọ VR, ọgbẹni Jeelani sọ fun ileeṣẹ iroyin PA pe “Ohun iyalẹnu ni iṣẹ abẹ naa jẹ, ara meeriri ni pe a le maa wo ohun ti yoo ṣẹlẹ ki a si le ṣiṣẹ abẹ naa lori kọmputa ko to di pe a fi awọn ọmọ naa sinu ewu kankan.”
“Awọn eeyan kan gbabọ pe irufẹ iṣẹ abẹ bayii lo lewu julọ ninu iran tiwa yii amọ bi a ṣe ṣiṣe abẹ naa lori Virtual Relaity dabi igba ti eeyan ba lọ sinu aye miran lori Mars ni.”
Ni bayii, awọn ibeji naa ti wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju lẹyin iṣẹ abẹ ọhun.
Awọn dokita sọ pe oṣu mẹfa gbako ni wọn yoo lo nile iwasan naa lẹyin iṣẹ abẹn ọhun ki ara wọn le mokun daadaa.
Ẹwẹ, ajọ Gemini Untwined sọ pe ẹyọkan ninu ẹgbẹrun lọna ọgọta ibeji lagbaye ni wọn maa n lẹpọ lati ori.












