Àwọn agbésùnmọ̀mí ti wọ Ogun, Oyo àti Osun láti ṣe ìkọlù - Gani Adams

Oríṣun àwòrán, AFP
Fi ibi to ba ti ri awọn agbesunmọmi to wa leti...
Eyi ni esi ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, fọ si ikede ti Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Gani Adams, fi sita pe awọn agbesunmọmi ti wa ni awọn aginju kan nipinlẹ Ogun, Oyo ati Osun.
Opin ọsẹ to kọja ni Gani Adams fi atẹjade naa sita.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Kehinde Aderemi, fi sita ni ọjọ Aiku, ni Adams ti sọ pe awọn araalu to ri awọn agbesunmọmi naa, ri wọn pẹlu awọn nkan ijagun oloro to pọ.
O ni “iroyin to tẹ mi lọwọ ni owurọ yii(ọjọ Aiku), ni pe awọn agbesunmọmi ti wọ aginju igbo to wa laarin ilu Osu si Ile-Ife, nipinlẹ Osun, ati eyi to wa laarin ilu Ibadan si Abeokuta.
Adams sọ pe oun rọ awọn eeyan to n gbe nilẹ Yoruba, lati ma a rin pẹlu ifura lasiko yii.
Bakan naa lo ni oun n kesi awọn gomina ni awọn ipinlẹ mẹfa to wa ni Iwọ oorun Gusu Naijiria, lati ṣe ipade pajawiri lori ọna ti wọn o gba dena ajalu nla to n bọ lọna.
Ṣugbọn agbẹnusọ ọlọpaa Ogun, Oyeyemi sọ pe awọn ko ti i gbọ iroyin iru nkan bẹẹ, ṣugbọn awọn ti n gbaradi fun ohunkohun to le ṣẹlẹ.
O ni ti Gani Adams ba sọ ibi to ti ri wọn ni pato, awọn yoo le gbe igbesẹ to yẹ,
Bakan naa lo sọ pe ki araalu fi ọkan balẹ lori eto aabo wọn.
Boko Haram ati Iswap leri lati kọlu awọn ipinlẹ kan ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọsẹ to kọja ni iroyin jade pe ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ati ISWAP, kede pe awọn yoo ṣe ikọlu ni ilu Abuja, ipinlẹ Katsina, Eko, Zamfara ati Kaduna.
Àwọn ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe aṣiri ikọlu naa tu ninu iwe akọsilẹ kan to lu jade lati ileeṣẹ alaabo NSCDC, lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2022.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Muyiwa Adejobi sọ fun iwe iroyin Punch pe, ọga agba ọlọpaa, Usman Baba, ti paṣẹ pe ki wọn o ko awọn ọlọpaa lọ si awọn ibi pataki n'ilu Abuja.
Bakan naa lo tun ṣàlàyé pe awọn ọlọpaa ọtẹlemuyẹ naa yoo ṣe iwadii bi wọn ṣe le mu ki erongba awọn agbesunmọmi naa ja si òfo.
Ṣugbọn o ṣeni laanu pe ọjọ keji, to jẹ ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keje, ni iroyin jade pe awọn agbesunmọmi Boko Haram kọlu ibudo awọn ologun kan niluu Abuja.
Ibudo naa ni eyii to wa lẹba oke nla Zuma Rock, to jẹ ala ilu Abuja si ipinlẹ Niger.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe okunkun lawọn agbesumọmi ọhun fi boju, ki wọn to si ṣina ibọn bo idubo awọn ọmọ ogun naa.
Ileeṣẹ ọmọ ogun paarọ awọn lọga-lọga

Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY
Lẹyin ikọlu to waye ọhun, ni ileeṣẹ ologun Naijiria kede pe oun ti paarọ awọn lọgagọga kan ni olu ileeṣẹ naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Ọgagun, Brigadier General Onyema Nwachukwu to fi ọrọ ọhun lede ninu atẹjade kan lọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keje, sọ pe ga agba ileeṣẹ ọhun, Lieutenant General Faruk Yahaya ti buwọlu asẹ pe ki wọn gbe awọn ọga agba kan kuro ni ẹka ti wọn wa tẹlẹ lọ si awọn ẹka mii kaakiri ileeṣẹ ọhun.
O ni eyi ko sẹyin ipinnu lati wa ọna abayọ si ipenija eto aabo.








