Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria pààrọ̀ àwọn lọ́gàá-lọ́gàá, ó pààrọ̀ àwọn míì káàkiri Nàìjíríà

Nigeria Army

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti paarọ awọn lọgagọga kan ni olu ileeṣẹ naa.

Igbesẹ yi lo n waye lẹyin awọn akọlu lemọ-lemọ ti awọn agbesumọmi n ṣe si awọn araalu, paapaa lẹyin ti ileeṣẹ naa ni awọn ti gbero ọna abayọ tuntun lati koju eto abo to mẹhẹ.

Ọgagun, Brigadier General Onyema Nwachukwu, To jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ naa lo fi ọrọ ọhun lede ninu atẹjade kan lọjọ Ẹti.

O ni ọga agba ileeṣẹ ọhun, Lieutenant General Faruk Yahaya ti buwọlu asẹ pe ki wọn gbe awọn ọga agba kan kuro ni ẹka ti wọn wa tẹlẹ lọ si awọn ẹka mii kaakiri ileeṣẹ ọhun.

Atẹjade naa ni “Ọga agba ologun ti paṣẹ fun awọn ọgagun ti wọn ṣẹṣẹ yan lati jawe sobi igbiyanju wọn lato koju iṣoro eto abo ni bi wọn ṣe n gba iṣẹ wọn tuntum.”

Lara awọn ti wọn ṣẹṣẹ yan si ipo General Officers Commanding, GOC, ni Major General UT Musa lati 81 Division si olu ileeṣẹ naa ni 82 Division, Major General TA Lagbaja lati olu ileeṣẹ naa ni 82 Division si olu ileeṣẹ ọhun ni 1 Division, Major General OC Ajunwa lati Section Brasilia si olu ileeṣẹ naa ni 81 Division ati bẹẹ lọ.

Yatọ si awọn wọnyii, wọn tun kede awọn ọgagun mii ti wọn gbe lati ẹka kan lọ si ọmiran.

Ileeṣẹ ọmọ ogun ni igbesẹ naa jẹ ọkan lara awọn akitiyan oun lati ri daju pe abo to peye wa fun awọn ọmọ Naijiria.

Ti ẹ ko ba gbagbe, alẹ Ọjọbo lawọn agbesumọmi kọlu ibudo awọn ologun naa kan to wa lẹba apata nla Zuma, nilu Abuja.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọmọ ogun ko tii sọ ọrọ kankan nipa ikọlu naa titi asiko ti a n ko iroyin yii jọ.