Àwọn ìpínlẹ̀ tó kéde ìsinmi fún àwọn òṣìṣẹ́ láti lọ gba PVC wọn rèé…

Oríṣun àwòrán, Google
Ọpọlọpọ ipinlẹ lorilẹede Naijiria lo ti kede isinmi fun awọn oṣiṣẹ wọn ki wọn le lọ gba kaadi idibo wọn ṣaaju eto idibo gbogboogbo ti yoo waye ni ọ̣dun 2023.
Eyi ko ṣẹyin bi Ajọ eleto idibo INEC ṣe kede pe awọn eniyan si le ṣe iforukọsilẹ ati gbigba PVC wọn titi di Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Oṣu Keje, ọdun 2022.
Nitori eyi ni ọpọlọpọ ijọba ipinlẹ kede isinmi fun awọn oṣiṣẹ wọn lati lọ gba PVC wọn.
Yatọ si ijọba ipinlẹ Eko ati ipinlẹ Ogun to kọkọ kede pe ki awọn eniyan wọn lọ gba PVC wọn ki wọn to pada si ibi iṣẹ, awọn ipinlẹ miran tun kede bẹẹ.
Awọn ipinlẹ mẹjọ miran to tun kede isinmi fun awọn oṣiṣẹ wọn;
Osun
Ijọba ipinlẹ Osun kede pe Ọ̣jọ Ẹti, June 24 ni wọn fun awọn araalu gẹgẹ bi ọjọ isinmi lati lọ gba PVC wọn.
Akọwe ijọba naa, Wole Oyebamiji lo fi lede ninu atẹjade ti ijọba ti fọ araalu lori.
Plateau
Gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong lo kede June 27 ati 28 fun awọn eniyan nipinlẹ naa lati jade lati lọ gba PVC.
Yobe
Gomina Mai Mala Buni ni gomina akọkọ to kọkọ kede isinmi fun awọn eniyan rẹ ki wọn le lọ gba PVC wọn.
Adari awọn oṣiṣẹ, Garba Bilai lo sọ fun awọn araalu pe Ọjọ kọkandinlọgbọn, Oṣu Kẹfa si Ọjọ Kini, Oṣu Keje ni wọn fun wọn.
Zamfara
Fun ijọba ipinlẹ Zamfara, ọsẹ kan ni wọn kede fun awọn eniyan gẹgẹ bi ọjọ isinmi fun awọn eniyan lati forukọ silẹ fun PVC wọn.
Niger
Ijọba Niger sọ pe oun gba awọn oṣiṣẹ ijọba lanfaani lati gba Ọjọ June 30 ati July 1 lati lọ fi lọ ṣe ifi orukọsilẹ ati lati gba PVC
Gomina Sani Bello sọ nibi ipade pẹlu ara ijọba rẹ.
Kaduna
Ijọba ipinlẹ Kaduna naa ko gbẹyin nibẹ.
Ọjọ 27 si 31 July ni wọn fun awọn oṣiṣẹ lati lọ gba PVC wọn.
Bauchi
Gomina Bala Mohammed ti kede Ọjọ Aje, June 27 gẹgẹ bi Ọjọ Isinmi fun awọn oludibo, ki gbedeke ti Ajọ INEC fi silẹ to de.
Borno
Gomina Babagana Zulum ti sọ pe July 21 ati 22 lati fi sọ ọjọ isinmi fun awọn eniyan.
Adamawa
Gomina ipinlẹ Adamawa, Ahmadu Fintriri kede Ọjọ Kejidinlọgbọn, Oṣu Keje si Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Oṣu Keje lati gba PVC wọn.












