Àwọn agbésùmọ̀mí kọlu ibùdó àwọn ológun nílùú Abuja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe awọn agbesumọmi Boko Haram ti kọlu ibudo awọn ologun kan niluu Abuja.
Ibudo naa ni eyii to wa lẹba oke nla Zuma Rock, to jẹ ala ilu Abuja si ipinlẹ Niger.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe okunkun lawọn agbesumọmi ọhun fi boju, ki wọn to si ṣina ibọn bo idubo awọn ọmọ ogun naa.
Awọn eeyan to wa lagbegbe naa ni lakọ-lakọ ni iro ibọn n dun, eyii to mu ki awọn sa asala fun ẹmi wọn.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn ologun atawọn agbesumọmi naa koju ija sira wọn, amọ a ko ti le sọ boya ẹnikẹni ba iṣẹlẹ naa lọ tabi ẹnikẹni farapa nibẹ.
Inu ọkọ ni a ti n gbọ iro ibọn ki a to ba ẹsẹ wa sọrọ
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun BBC pe inu ọkọ loun atawọn eeyan kan wa, asiko ti awọn si sunmọ oke nla Zuma Rock lawọn bẹrẹ si n gbọ iro ibọn leralera, eyii to mu ki wọn fi ọkọ wọn silẹ lati sa asala fun ẹmi wọn.
O ni lẹyin ti awọn salọ tan, awọn agbebọn naa ṣi tẹsiwaju lati maa yinbọn.
Gbogbo akitiyan BBC lati kan si ileeṣẹ ọmọ ogun lati sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun lo ja si pabo.
Aarin ọsẹ yii lawọn agbesummọmi kan kọlu awọn ẹṣọ to n ṣo ile Aarẹ, 7 guards brigade, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọmọ ogun ni awọn pa ọgbọn ninu awọn agbesumọmi ọhun.
Ẹ lọ fi ọkan yiin balẹ, abo to peye wa lori yin niluu Abuja
Ẹwẹ, ṣaaju ki ikọlu yii to waye ni ijọba Abuja ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati pese abo to peye niluu naa, ati pe ko si ewu kankan ninu ilu ọhun.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ijọba Abuja, Anthony Ogunleye, fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni awọn yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ipinlẹ miran to sun mọ Abuja fun eto abo to ye kooro.
Atẹjade ọhun ni Kọmiṣọna ọlọpaa ilu Abuja, Sunday Babaji ti fi da awọn eeyan ilu naa loju pe ko si nnkankan ti yoo ṣẹlẹ si wọn.
O ni “O fi da awọn olugbe ilu Abuja loju pe abo to peye wa niluu Abuja... ki awọn eeyan naa maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai si ifoya kankan.”
Ọjọ kan naa ti atẹjade yii jade ni awọn agbesumọmi kọlu agbegbe Zuma Rock.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
'ISWAP àti Boko Haram n gbèrò láti kọlu Eko, Abuja, Katsina àti àwọn ibòmíì'

Oríṣun àwòrán, AFP
Ajọ alaabo Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC), ti ke gbajare pe awọn agbesunmọmi n gbero lati kọlu ilu Abuja, ipinlẹ Katsina, Eko, Zamfara ati Kaduna.
Àwọn ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe aṣiri ikọlu naa tu ninu iwe akọsilẹ kan to lu jade lati ileeṣẹ alaabo NSCDC, lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2022.
Botilẹ jẹ pe ajọ naa ko tii sọ boya otitọ ni, iroyin sọ pe igbakeji oludari ajọ naa, DD Mungadi, lo fọwọ si atẹjade naa, lati fi ta awọn oṣiṣẹ rẹ ni olobo nipa àwọn ikọlu naa.
'Ẹgbẹ́ agbesunmọmi Islamic State for West Africa Province (ISWAP) ati Boko Haram, ti ko awọn ọmọ ogun rẹ jọ, to si ti ko nkan ijagun fun wọn lati ṣe ikọlu ni awọn ipinlẹ naa.'
] O ni eyi lo mu ki oludari ajọ NSCDC, pàṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ rẹ so eto aabo le daadaa ni awọn ibi pataki bi ile ẹ̀kọ́, ile ijọsin, ati awọn dukia ìlú, ti wọn le kọlu.
Iroyin yii jade lẹyin ti awọn agbébọn kọlu ikọ Presidential Guards Brigade ni ọjọ Aiku.
Ikọlu naa waye ni opopona Bwari si Kubwa, n'ilu Abuja. Ọmọ ogun mẹjọ ni iroyin sọ pe o ku níbi ikọlu naa.
Yatọ si ajọ NSCDC to n gbaradi, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Muyiwa Adejobi sọ fun iwe iroyin Punch pe, ọga agba ọlọpaa, Usman Baba, ti paṣẹ pe ki wọn o ko awọn ọlọpaa lọ si awọn ibi pataki n'ilu Abuja. Bakan naa lo tun ṣàlàyé pe awọn ọlọpaa ọtẹlemuyẹ naa yoo ṣe iwadii bi wọn ṣe le mu ki erongba awọn agbesunmọmi naa ja si òfo.








