Ọdọbinrin Iyeyemi Adediran sọ iriri rẹ ni idi iṣẹ awakọ epo tirela ati bi o ṣe bẹrẹ.

Àkọlé fídíò, Ọdọbinrin Iyeyemi Adediran sọ iriri rẹ ni idi iṣẹ awakọ epo tirela ati bi o ṣe bẹrẹ.

Arabinrin Iyeyẹmi Adediran ni igbagbọ ohun ni pe ko si ohun ti ọkunrin le ṣe ti obinrin le ṣe.

Iyeyẹmi sọ eyi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iriri rẹ ni idi iṣẹ awakọ epo tirela ati bi o ṣe bẹrẹ.

O ni ọdun mẹrin niyii ti oun ti bẹrẹ iṣẹ awakọ ti oun si n gbiyanju lojojumọ lati ṣiṣẹ karakara.

Bakan naa lo ni oun ko yan iṣẹ naa laayo nitori pe ko si iṣẹ amọ nitori oun fẹran ọkọ wiwa ti oun si ti ri obinrin to ti wa ọkọ naa.