Agbẹjọ́rò AGF Ahmed n bèèrè fún béélì rẹ̀ ṣùgbọ́n EFCC fárígá ni Adájọ́ bá sọ ìdàhún rẹ̀ di òní

Mo sún ìgbẹ́jọ́ Ahmed Idris àti a akẹgbẹ́ rẹ̀ lọ sí ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù keje, kí ẹ sì dá wọn padà lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje-Adájọ́ àgbà A.O Adeyemi Ajayi

Igbejo AGF Ahmed IDris

Adájọ́ àgbà A.O Adeyemi Ajayi ti sún igbejọ Ahmed Idris, Godfrey Olusegun Akindele àti Mohammed Kudu Usman siwaju.

Ejo yii ni àjọ tó n mójútó ṣiṣẹ owo ilu kúmọ-kùmọ àti àwọn iwa ibaje mìràn EFCC fẹsun kan won.

Pe wọn ṣe owo to le ni ọgọrun un milionu naira ni kumọ-kumọ.

Adajo ni pe gbogbo re yoo tesiwaju loni ọjọ́ kejidinlọgbọn oṣù tí a wàyíi.

Kini Adajo naa tun sọ?

Bakan naa ni Adájọ́ àgbà naa sí tùn ní kí wọ́n dá wọn padà sí ogbà èwon Kuje.

Nígbà tí Agbẹjọ́rò Ahmed Idris bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, O sọ pe koko ìdí tí wọn ṣe péjọ lónìí ní fún ti béèlì ti won bẹ̀bẹ̀ fún, kí i ṣe fún iwa níná owó ìlú kúmọ-kùmọ.

Ó tèsíwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ báyìí pé àwọn ti mu ìwé béèlì rẹ̀ wá àwọn sì rawọ ẹbẹ sí adájọ́ àgbà latí bojú àánú wo Ahmed Idris kí wọ́n sì fún ni Béèlì.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kilode ti wọn fẹ́ gba beeli Ahmed?

O fi ìpín kejìlá ti ICPC nínú ìwé òfin ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn pé ọdún meje ni wọn le fi ṣe ẹ̀wọ̀n ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n, èyí tí ọ́ jásí pé, wọ́n silẹ fún Ahmed Idris ní béèlì. Ó tèsíwájú pé òfin tó rọ̀ mọ́ gbígba béèlì kò tako oníbàárà wọn, ìyẹn Ahmed Idris,

Wọn fi kun un pe ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ ní gbigba beeli, ti ẹni ti wọn fi ẹ̀sùn kàn bá ti ń wa fún ìgbẹ́jọ́ ní gbogbo ìgbà, èyí tí oníbàárà àwọn ti fihàn pé yóò ma wá nígbà kugbà tí wọ́n bá ránṣẹ́ pèé

Amọsa, agbẹjọ́rò àjọ tó n mójútó ṣiṣẹ owo ilu kúmọ kùmọ ati àwọn iwa ibaje mìràn tako gbígba béèlì Ahmed idris.

O sọ pé, ó yẹ kí wọ́n wo ẹ̀rí tó dájú tó wà nílẹ̀, kí wọ́n wo bí ẹ̀sun náà ṣe lágbára sí àti ìjìyà tí ó tọ́ fún ẹ̀sùn náà, kí wọ́n tó sọ̀rọ lóri gbígba béèlì.

EFCĆ wá rọ adájọ́ àgbà pé kí ó kọ̀ jálẹ̀ láti fún Ahmed idris ní béèlì.

Ó sọ síwájú pé ẹ̀sùn tó yẹ kí ìjìyà ẹ̀wọ̀n ọdún méje tọ́ sí ni, kì i ṣe ẹ̀sùn yẹpẹrẹ tí wọ́n kàn le fojúfò, ẹ̀sùn tó lágbára gan ni.

Ìgbẹ́jọ́ olùṣirò àgbà Naijiria tẹ́lẹ̀, Ahmed Idris ń tẹ̀síwájú lónìí lórí ẹ̀sùn lílu ₦80b ní pónpó

Ahmed Idris

Oríṣun àwòrán, Deji Owolabi

Lónìí ní igbẹ́jọ́ yoo tún tẹ̀síwájú nile ẹ̀jọ gíga tó wà nílùú Abùjá láàrin àjọ EFCC àti adarí ilé isẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó n mójútó ètò ìṣirò tẹ́lẹ̀rí, Ahmed Idris.

Eredi ẹjọ naa ko ṣẹyin ẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú kùmọ kùmọ àti àwọn ìwà ìbàjẹ́ míràn tí wọ́n fi kàn án.

Lọ́sẹ̀ to kọjá, ọjọ́ Kejìlélógún, oṣù Keje yìí ni adájọ́ àgbà, Adéyemí Ajayi, ni kí wọ́n kó àwọn afurasí ọ̀hún lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kuje niluu Abuja.

Ẹsun ti EFCC fi kan afurasi

High Court Abuja

Bó tilẹ jẹ pé àwọn agbẹjọ́rò Idris Ahmed já fitafita láti gba béeli rẹ̀ sùgbọ́n tó já sí pàbó.

Lara awọn ẹsun ti EFCC fi kan Idris ni pe o gba riba owo ti iye rẹ to biliọnu marundinlogun naira fun akanṣẹ iṣẹ kan.

Inu oṣu Karun un ọdun yii ni wọn fi panpẹ ofin mu afurasi naa niluu Kano, lẹyin to kọ lati yọju si ọọfisi EFCC lẹyin ti wọn fi iwe pe lori ẹsun lilu ₦80b ni ponpo.

Akọroyin BBC ti wa nile ẹjọ bayii lati maa mu gbogbo bi ẹjọ naa yoo ṣe maa lọ lonii.