Wo bí Ife ṣe pa ara rẹ̀ lẹ́yìn tó dáná sún Bolu ọkọ rẹ̀ torí pé ó ká 'chat' pé obìnrin míì lóyún fún ún

Àkọlé fídíò, Osogbo

Ọ́rọ́ Ifẹ́.......

BBC Yoruba ti wa ẹbi awon ololufẹ meji ti wọn ti jalaiasi kan ni ipinlẹ Osun. https://www.bbc.com/yoruba/articles/cere9mp22w7o

Saaju ni ọ̀rọ̀ IfeOluwa Akanji Bamidele àti ọkọ rẹ Boluwatifẹ Bamidele ti lu ayelujara pa.

Arabinrin Abike Bamidele to jé iya Boluwatife salaye fun BBC Yoruba ohun to ṣẹlẹ ni awọn ọjọ mérin ti Bolu lo kẹyin lori oke eepẹ.

Bakan naa lo sọ gbogbo igbesẹ ti wọn gbe gẹgẹ bi Obi lati pẹtu si aawọ tọktaya naa ti igbeyawo wọn koi tii pe ọdun kan.

O sọ bi wọn se gbeBolu lọs sile iwosan Central, LAUTACH titi de UCH lẹyin ti Ife dana sun ọkọ rẹ mọle lẹyin to tan 'generator'to si ran abure rẹ to n ba wọn gbe jade.

Tani BBC Yoruba tun ba sọrọ lori iṣẹlẹ yii

Tunde Bamidele to tun jẹ ẹgbọn oloogbe Boluwatife Bamidele ba BBC Yoruba sọrọ.

O ṣafihan ohun Ife ati ọrọ ti wọn jọ sọ kẹyin ki Ife to gbẹmi ara rẹ nigba to gbọ pe Boluwatife ọkọ oun ti ku.

O ni lẹyin naa ni awon Obi Ife pe wọn nigba ti wọn ri oku ọmọ wọn.

Lẹyin iku Bolu ni awon ọdọ kan lọ kọlu ile awọn Obi Ife ti wọn si ba a jẹ́ patapata.

Bẹ́ẹ̀, atẹjiṣẹ pe ẹnikan loyun fun Bolu ọkọ rẹ ti Ife ri lo bi iṣẹlẹ ibanujẹ to pada mu ẹmi awọn mejeeji lọ.

Opọ gba pe boya nitori pe oyun n bajẹ lara Ife lo jẹ ki igbonara rẹ pọ to bẹẹ.

Ninu fọnran ohun Ife ti Tunde gab silẹ ni Ife ti sọ pe oun ko mọọmọ jo Bolu mọle ati pe iṣẹ eṣu ni.

O ni oun mọ pe bolu ko fi ile ọmọ oun se oogun owo rara pe o kan maa n yan oun jẹ ni.