Wo ọmọkùnrin ọdún mẹ́wàá yìí tó ní ojú ara takọ-tabo

“Ọpọ igba ni mo maa n sunkun pe ki lo de ti iṣẹda ọmọ mi fi ri bayii”.
Eyi lọrọ aro to jade lẹnu iya kan, ti ọmọ rẹ ọmọ ọdun mẹwaa jẹ abẹya takọ-tabo.
Wọn bi ọmọ rẹ ọkunrin, to si jẹ pe oun nikan ni ọkunrin ti wọn bi pẹlu nnkan ọmọkunrin ati nnkan ọmọbinrin papọ.
Ninu ọrọ ti wọn ba BBC sọ, awọn obi ọmọdekunrin naa ṣalaye ipenija ti wọn n dojukọ bayii ati eyi ti ọmọdekunrin naa nkoju lojoojumọ.
"O ni dokita lara lati sọ fun mi boya ọkunrin ni ọmọ mi tabi obinrin nigba ti mo bi i"
Bi o tilẹ jẹ wi pe ọmọdekunrin naa ti ṣe oniruuru iṣẹ abẹ lati ṣe atunṣe si eyi, sibẹ o ṣi nilo awọn iṣẹ abẹ miran ki o to lee yanju.
Ireti awọn obi rẹ ni pe bopẹ boya yoo ṣi lee gbe igbe aye rẹ bi o ti tọ ati bo ti yẹ.
“Nigba ti mo bi ọmọ naa, awọn dokita ko lee sọ fun mi boya ọmọ ọkunrin ni tabi obinrin.”
“Lọpọ igba ni mo maa n da omije loju nitori pe oun nikan ni ọmọ ọkunrin ti mo bi,” ni ọrọ ti iya rẹ sọ.
Nigba ti baba rẹ n ba BBC sọrọ, o ni nigba ti dokita sọ fun awọn ni ileewosan pe iyawo oun ti bimọ, inu oun dun gidigidi ni.
“Nigba ti mo jade dokita ki mi ku oriire, o ni iyawo mi ti bi ọmọ ọkunrin lantilanti. Inu mi dun.

O ni ki n tẹle oun lọ si ẹka ibi ti wọn gbe ọmọ naa si lati fi ipo ti ọmọ naa wa han mi.”
Nigba ti wọn ṣi ẹsẹ rẹ, ni mo wa rii. Mi o lee sọ boya ọkunrin ni tabi obinrin. O ru mi loju gidigidi.”
Baba ọmọdekunrin naa ni wọn dari awọn lọ si ileewosan nla fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ nilu Ile ifẹ, nibi ti wọn ti sọ fun wọn pe aisan to n da ọmọ naa laamu nii ṣe pẹlu ẹya ibalopọ rẹ.
Bawo ni ara ọmọdekunrin naa ṣe ri?
“Nnkan ọmọkunrin rẹ to yẹ ko wa ni apa oke, ko si nibẹ, dipo bẹẹ n ṣe lo wa ni isalẹ, to si da oju de ilẹ.
Koropọn rẹ to yẹ ko wa lapa isalẹ nnkan ọmọkunrin rẹ wa ni apa oke rẹ. Gbogbo rẹ kan doju kodo ni.
Eyi lọrọ ti baba rẹ sọ.
Lọwọ yii, ọmọdekunrin yii kii le bọ ṣokoto silẹ lati tọ nibi ti ọpọ ero ba wa.
O maa n bẹrẹ tọ bii obinrin ni ti itọ si maa n da si aṣọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iya rẹ tun ṣalaye siwaju sii fun BBC pe, isalẹ ni ibi to fi n tọ wa nitori nnkan ọmọkunrin rẹ to yẹ ko maa fi tọ ko la rara.
Bakan naa si ni oju ile igbọnsẹ rẹ kere pupọ tobẹẹ to fi jẹ pe kekeke ni igbọnsẹ rẹ maa n jade.
Nitori eyi, o ni akanṣe aga to maa n joko si nileewe, a si maa de idi fun un pẹlu.
O ni awọn ko kọkọ fẹ jẹ ko lọ si ile ẹkọ, ṣugbọn dokita lo sọ fun awọn pe ki awọn maṣe dii lọwọ ileẹkọ lilọ.
Ki ni aisan ìtúmọ̀ nini ẹya ara meji pọ lẹẹkan naa ti oyinbo n pe ni ‘Intersex’
- Eyi ni igba ti nnkan ọmọkunrin tabi ọmọbinrin ti eeyan kan ba ni ko jẹ ki a lee kaa kun akọ tabi abo.
- Awọn miran wa to jẹ wi pe igba ibi wọn ni wọn yoo ti ṣakiyesi eyi, awọn miran si wa to jẹ pe nigba ti wọn ba ti n balaga ni yoo to farahan.
- Kariaye, ida meji o din diẹ ninu ọgọrun lo ni eyi lara gẹgẹbi ọfiisi ajọ agbaye lori ẹtọ ọmọniyan ṣe sọ.
Ki ni awọn onimọ iṣegun oyinbo sọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọṣẹmọṣẹ imọ nipa itọju alaboyun, Dokita Adebayọ Bamisebi ṣalaye pe oniruuru aisan yii lo wa.
O ni fun awọn to ba ni iru iṣesi yii, ọkan lara awọn ẹya ara wọn ni yoo bori ikeji.
Nitori naa eyi to baa moke lara ẹya mejeeji to jẹyọ lara iru ẹni bẹẹ ni yoo sọ












