Aráàlú dáná sún afurasí méjì 'tó jí ọ̀kadà' ní Ibadan

Aworan bi wọn ṣe dana sun awọn afurasi naa

Awọn afurasi meji ti awọn eeyan fura ole si lagbegbe General gas ni ilu Ibadan ni wọn ti da ina sun lọjọru.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ, alupupu ọkada ni wọn ni awọn afurasi naa ji gbe.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe lati agbegbe Bodija ni ilu Ibadan kan naa lawọn afurasi naa ti ji ọkada naa ti awọn eeyan si ti n le wọn bọ.

Awọn ọlọkada ni agbegbe Bodija ni wọn ni wọn ti n le wọn bọ ti wọn si n pariwo ole! Ole!! tẹle wọn.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn tun sọ pe mẹta lawọn afurasi naa, ati pe orita agbegbe General gas ni ọna ti daru mọ wọn loju ti wọn fi dari ọkada ti wọn gbe gba abẹ afara ọkọ ni General gas naa nibiti ti ọwọ ti tẹ meji ninu wọn ti ẹni kẹta si sa asala.

Ọgbẹni Samuel to ba awọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe bi awọn afurasi naa ṣe n sare ni wọn n yinbọn lakọlakọ ti ibọn si ba eeyan meji to ti di ero ile iwosan bayii.

Aworan bi wọn ṣe dana sun awọn afurasi naa

“Ikanra yii ni awọn aradugbo fi mu awọn meji yii ti wọn si ba ọpọlọpọ ọ̀ta ibọn, ogun ati awọn ohun ija oriṣiriṣi.

Ikanra yii lawọn ọmọ agbegbe naa atawọn ọ̀lọkada ti wọn ji gbe fi lu wọn ti wọn si da ina sun wọn.”

Aworan bi wọn ṣe dana sun awọn afurasi naa

Awọn aladugbo naa ni gulegule awọn ole ajọkada gbe lagbegbe naa ti n di eyi to n mu awọn olugbe ibẹ lominu. Ọpọlọpọ sunkẹrẹ fa kẹrẹ ni iṣẹlẹ naa da silẹ lagbegbe General gas, akobọ ojurin.