Táńkà epo kọlu dúrọ̀mù ní Mile 2 l’Ekoo, iná sọ

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Táńkà epo bẹntiróòlù kan gbíná nígbà tó kọlu dúrọ̀ọ̀mù ní agbègbè Mile 2, Wharf Otto ní ìrọ̀lẹ́ òní, ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Keje, ọdún 2022.
Àtẹ̀jáde tí akọ̀wé àgbà iléeṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu fi léde fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀.
Oke-Osanyintolu ní nígbà tí àwọn ma fi dé ibi tí ìjàmbá iná náà ti ń wáyé àwọn ri wí pé táńkà kan tó gbé epo ló kọlu dúrọ̀mù kan tó sì gbiná.

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Lásìkò tí a fi ń kó ìròyìn yìí jọ Oke-Osanyintolu ní àwọn ṣì wà níbi tí àwọn ti ń gbìyànjú láti pa iná náà.
Bákan náà ló ní àwọn àjọ panápaná ìjọba àpapọ̀, tí ìpínlẹ̀ Eko, LRT, àti LRU ni àwọn ti jọ ń ṣe akitiyan láti pa iná ọ̀hún.
Ó wá pàrọwà sí àwọn ọlọ́kọ̀ láti má gba ọ̀nà yìí fún ìgbà díẹ̀ ná.
Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti jìnà sí fífi iná ṣeré lásìkò yìí










